YO/Prabhupada 0072 - Ojuse Iranse ni ko jowo ara re

Revision as of 18:51, 14 October 2018 by Vanibot (talk | contribs) (Vanibot #0023: VideoLocalizer - changed YouTube player to show hard-coded subtitles version)
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


Lecture on CC Madhya-lila 20.108-109 -- New York, July 15, 1976

Bee na kosi eni ti o le je oga. Iyen ko se se. E ma ri imoran yi, ekale īśvara kṛṣṇa āra saba bhṛtya (CC Adi 5.142). Olorun nikan ni oga, onikaluku ni iranse. Eyi ni ipo wa gangan. Sugbon ni ona eke a ngbiyanju lati di oga. Iyen ni ijakadi fun igbesi aye. A nse laala fun nkan ti a ki nse. Gbogbo wa la mo itumo oro yi, "laa laa aye" "Eni l'agbara lo nye" " Eyi ni laa laa na. A ki nse oga, sibe sibe, a ngbiyanu lati di oga. Imo Mayavada, awon na nse awon awe ati idani nijahun ti won le gan sugbon fun kini. Ero won ni wipe " Ma di ikan pelu Olorun." Asise kan na. Asise kan na. Ki se Olorun, sugbon o nse yanju lati di Olorun. Bi o ti le je wipe o ti se opolopo aawe, vairagya, fi nkan aye sile, gbogbo nkan... Nigba miran won a fi gbogbo igbadun aye yi sile, won a wo igbo lo, ni ibi ti won a ti mase awon aawe lile orisirisi. Kini ero na? "Nisinyi ma di ikan pelu Olorun." Asise kan na.

Bee na maya lagbara pupo. Ti o je wipe iru asise wonyi nsele paapa fun awon ti won ti a le f'enu pe gegebi eni ti o ti dagba ninu emi. Rara. Nitorina Chaitanya Mahaprabhu ko oro na niko kia kia ninu awon imoran Re. Iyen ni imo Chaitanya Mahaprabhu. Nibi ti Olorun ti so ipari oro, sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ vraja.. (BG 18.66). O nso oro ni pa ipo na; Oun ni Olorun, Eni to ga julo, Olorun awon oba. Oun beere, O fi agbara beere, "Eyin alailofin, e jawo ninu gbogbo nkan. Ki e si jowo emi yin fun Mi. Igba na ni e o ni alafia. Eyi ni imoran ikeyin ninu Bhagavad Gita. Chaitanya Mahaprabhu, ti o je Olorun fun Ra Re sugbon ti O nfi wawu gege bi ojise Olorun; nitorina Oun so nkan kan na. Olorun so wipe, "Jowo emi re," Chaitanya Mahaprabhu na so wipe " Gbogbo awon eda elemi ni won nse iranse Olorun." Iyen tumo si wipe o gbodo jowo emi re. Ojuse iranse ni ko jowo ara re, ki se ko ma jiyan pelu oga tabi ko so wipe "Egba ni a je." Awon ti won ti gba esin sodi ni won yi, ero were.

piśācī pāile yena mati-cchanna haya
māyā-grasta jīvera se dāsa upajaya

Iranse ko le di Oga. Iyen o le se se. Sugbon gbere ti... Titi di igba ti a ba nmu ero aye ,ti ko ja moran yi wipe "Emi ki se oga, iranse ni mi," tabi "emi ki se iranse, oga ni mi," igba na yi o si jiya. Maya na a fun ni ijiya. Daivī hy eṣā. Gegebi awon, elewon, awon jaguda ati awon ole, won s'afojudi si ofin ijoba. "E mi o saniyan fun ijoba." Sugbon iyen tumo si wipe o fi tinu tinu gba iya. O gbodo se itoju ofin ijoba. Ti ko ba si nse bi won se nse, o di alailofin, won a si fi sinu ewon. ati pelu agidi, ni lilu, ni ijeniya, o gbodo gba. "Beni beni, mo gba."

Nitorina eyi ni ise maya. Daivī hy eṣā guṇamayi mama māyā duratyayā (BG 7.14). A wa ni abe ijoba maya. Prakṛteḥ kriyamāṇāni guṇaiḥ karmāṇi sarvaśaḥ (BG 3.27). Nitori kini? Nitori wipe a npe ara wa l'oga. Omo odo npe ra re l'oga; nitorina ijiya. Ati gbere ti a ba gba wipe " Emi ki nse oga, omo odo ni mi" igba yen ko ni si ijiya. Imo to rorun pupo. Iyen ni mukti. Mukti tumo si, lati wa si ipo to dara. Iyen ni mukti. Bi Mukti se tumo si ninu Srimad-Bhagavatam, muktir hitvā anyathā rūpaṁ svarūpeṇa vyavasthitiḥ (SB 2.10.6). Mukti tumo si wipe a gbodo fi iponju ti ko nilari yi sile, anyathā. O je omo odo, sugbon o npe ra re l'oga. iyen ni anyatha, nkan idakeji. Bee ni igba to ba fi ero odi aye yi sile pe oun je oga, nigba na ni o di mukti; o ni igbala lojukanna. Mukti o gba gbogbo asiko lati lo ma se awon aawe to le lati lo sinu igbo ati ka ma lo sori oke Himalaya lati lo gbiro, fowo d'imu ati awon orisirisi nkan. Ko gba nkan pupo. Bo se rorun to ni pe e kan loye nkan moju. wipe " Iranse Oluwa, ni mi" - e di mukta lojukanna. Iyen ni itumo mukti bi won se fun ni ninu Srimad-Bhagavatam. Muktir hitvā anyathā rūpaṁ svarūpeṇa avasthitiḥ. Gege bi jaguda ti o wa ninu ewon. ti o ba ni iforibale wipe "Lati igbayi lo emi o ma tele awon ofin. Emi o si tele gbogbo awon ofin ijoba pelu iteriba." o si ma sele nigba miran wipe won a da sile, kojo re to pe nipa ofin. Bee na a le di eni igbala lojukanna ninu ile ewon ti aye yi. ti a ba gba imoran Chaitanta Mahaprabhu, jīvera svarūpa haya nitya kṛṣṇera dāsa (CC Madhya 20.108-109).