YO/Prabhupada 0021 - Kilode ti ifaya sile se nsele pupo ni orile ede yi



Lecture on SB 6.1.26 -- Honolulu, May 26, 1976

Bayi ni asa to gbajumo nisinyi Oni kaluku ti fi ara re fun awon ise aye asan yi, ati pe ipile ise ti aye asan ni grhastha, idile abiyamo. Idile abiyamo, gege bi asa Vediki, tabi nibi ki bi, se ni lati toju iyawo ati awon omo, Oni kaluku nfi'sé sè. Won ro wipe eyi ni kan ni ojuse won. "Lati toju ara ile, eyii ni ojuse mi" Bo ti le se ni itelorun si. Iyen ni ojuse mi" Ko si eniti o nro wipe awon eranko paapa nse iru ojuse yi. Awon naa ni awon omo won, won si nbo won. Kini iyato? Nitorina oro ti a fi juwe re nibi ni mūḍha. Mūḍha tumo si ketekete. Eniti o fi ara re fun iru ise won yi bhuñjānaḥ prapiban khādan. Prapiban. Pariban tumo si mimu, ati bhuñjānaḥ tumo si jije. Bi o se nje, bi o se nmu, khādan, bi o se nrun nkan lenu, carva casya raja preya (?). Orisi merin ohun jije lo wa. Nigba miran a run kan lenu, igba miran a nla nkan, to ba tun ya a ngbe nkan mi ati ni igba miran a nmu. Ni bayi orisi merin oun jije lo wa. Nitori eyi a nko lorin, catuḥ vidhā śrī-bhagavat-prasādāt. Catuh vidha tumo si orisi merin. Nitorina a nfi orisirisi ounje se `oré ninu awon idi merin yi Nkan ti a nrun lenu, nkan ti a nla lenu, nkan ti a ngbe mi. Bi o se ri ni yi.

Bee na bhuñjānaḥ prapiban khādan bālakaṁ sneha-yantritaḥ. Baba ati iya se itoju awon omo won, bawo ni won se ma fun won ni ounje. A ti ri Yeye Yashoda nf'ounje fun Krishna. Bakanna. Eyi ni iyato. Awa nfounje fun omo l'asan, ti awon ologbo ati awon aja na nse sugbon Yeye Yashoda nf'ounje fun Krishna. Ni ona kanna. Ko si iyato ni ona ti a ngba fi se, sugbon ikan fi Olorun siwaju ati ikeji fi eyi to wu siwaju. Iyen ni iyato to wa nbe. Ni igba ti a ba fi Olorun siwaju, ni igba na o je ti emi, ati ni igba ti a ba fi iwu kiwuu siwaju, ni igba na asan lo je. Ko si iyato ninu nkan aye... Eyi lo fi yato. O wa... Gege bi ife agbeere ati ifé, ifé mimo Kini iyato laarin ifé agbere ati ife mimo? Ni ibi bayi a nfarapo, okunrin ati obinrin, nfarapo ninu ero agbeere, ati Krishna na si nfarapo pelu awon odobinrin, gopis. Looju lasan won daa bi bakanna. Sugbon kini iyato ti o wa nbe? Bee na ni Olukowe, Caitanya-caritāmṛta, ti se alaaye iyato yi wipe kini iyato ti o wa ni aarin ifé agbere ati ifé? A ti se alaaye eyi sile. O ti so wipe, ātmendriya-prīti-vāñchā-tāre bali 'kāma' (CC Adi 4.165), Ni igba ti mo ba fe te ara mi lorun, eyii ni agbeere, kāma." Sugbon kṛṣṇendriya-prīti-icchā dhare 'prema' nāma, Ati ni igba ti a ba fe se itelorun ipa ara Olorun, iyen ni ifé, prema' Eyi ni iyato to wa nbe. Ni ile aye assan yi, ko si ifé nitoripe okunrin ati obinrin, won ko ni ironu wipe, "Mo nfarapo pelu okunrin yi, okunrin ti o se itelorun awon ero okan mi" Rara. "Ma se itelorun ara mi" Eyi ni ipile pataki na.. Okunrin naa nro wipe, " Ti mo ba farapo pelu obinrin yi, emi o se itelorun ero okan mi", Obirin naa si nrowipe "Ti mo ba farapo pelu okunrin yi, emi o se itelorun ero okan mi" Nitori idi eyi, o je nkan ti o gbajumo ni ilu awon oyibo, dee de ti isoro nkan ba ti fara han ninu igbadun ara, kiakia ni a ma se ikosilé. Eyi ni idi oro, kilode ti ifaya sile se nsélé pupo ni orile ede yi. Idi pataki naa ni wipe "Dee de igba ti emi o ba ri itelorun mo, nigba na emi o fe mo." Śrīmad-Bhāgavatam fi enu ba eyi : dāṁ-patyaṁ ratim eva hi. Ni aye ti awa yi, oko ati aya tumo si igbadun ibaralo, tara mi nikan Ko si ibeere wipe" Kaa joo gbe poo,; A ma se itelorun Olorun ni ipa kiko a ti se ife re. Eyi ni egbe isokan Oluwa.