YO/Prabhupada 0025 - Taba se nkan to niyi, ema ri abajade re



Conversation with Yogi Amrit Desai of Kripalu Ashram (PA USA) -- January 2, 1977, Bombay

Yogi Amrit Desai: Mo ni ife yin pupo, mo si ni ki nwa ki yin.

Prabhupāda: O se.

Yogi Amrit Desai: Mo nso fun awon olujosin. Mo so wipe eyin ni...

Prabhupāda: O wa lodo Dr. Mishra?

Yogi Amrit Desai: Rara, mi o si nbe. Mo nso fuu gbogbo awon olujosin ibi. Mo so pe Sri Prabhupāda ni eni ti o ko ko gbe imo ti bhakti wa si ilu awon oyibo nibi ti o ti wa wu lo julo. Nitoripe oririsi ni o wa ninu ori won, won nse ju ki won ma ronu, ronu, ronu. Ona ti ife yi wa jinle pupo.

Prabhupāda: E ma wo be yen. Ti e ba fi nkan to dara gidi han

Yogi Amrit Desai: To dara gidi.

Prabhupāda: A di oran mimo.

Yogi Amrit Desai: Idi re niyi ti o fi nlosiwaju dara dara, nitoripe o je nkan gidi.

Prabhupāda: Eyi si je ojuse awon omo orile ede India lati fun won ni nkan gidi. Eyi ni a npe ni para-upakara. Ki emi to de, gbogbo awon swami ati won yogi won yi wa sibi lati le tan won je.

Yogi Amrit Desai: Rara, won nberu lati fun won ni otito nitori won nberu wi pe won o ni gbaa.

Prabhupāda: Won o mo nkanti o je otito. [erin] Won o beru. Nitori kini, ti e ba wa lori ododo, kilode ti e gbodo beru?

Yogi Amrit Desai: Ododo oro.

Prabhupāda: Won o mo nkanto o nje otito, beere lati ori Vivekananda.

Yogi Amrit Desai: Bi o ti le ko ri, bee ni. E wo, lati igba ti e ti de... Mo wa nbe lati odun 1960. Mo bere si ko eko yoga. Sugbon lati igba ti e ti de, mi o beru mo lati ko won ni pa bhakti ati ni pa atunwi ti mantras. Nisinyi a ni opolopo bhakti ni asrama, opolopo bhakti Mo si fi ogo yen fun yin nitori pe mo beru tele lati fun won nitori mo ro wipe, "Onigbagbo ti Kristi ni won. Bo ya won o ni feran eto esin pupo. Ko ni ye won." Sugbon e ti se nkan iyanu. Olorun, Krishna, se iyanu yi ni pa yin. O se iyanu gan, iyanu ti o ga julo lori aye. O se mi jigala jigala ni pa re.

Prabhupāda: O se pupo fun gbolohun oro yi. Ti a ba fi nkan gidi han, a si ma je.

Yogi Amrit Desai: Bee ni. Nkan ti emi na nse ni yi. Oni kalu ku... A ni bi ogorun ati ogota eniyan ti won ngbe ninu ashrama, gbogbo won ni won si nse ikonimora ni pa biba obinrin lo po. Oni kalu ku won nji laro kutu lagogo merin, won a si tun lo sun ni agogo mesan ale. Won o si nsunmo ara won. Won ma nsun ni yara oto oto Papa ni akoko ijosin, sat-sanga, won ma njoko ni aye oto oto. Gbogbo nkan ni o ni afoju to. Ko si pe a nlo ogun, ko si oti mimu, ko si tii mimu tabi tii dudu, ko si alubosa tabi galiki. Mimo.

Prabhupāda: O dara pupo. Bee ni. Awa na ngba ona kan na.

Yogi Amrit Desai: Bee ni

Prabhupāda: Sugbon se e ni Deiti?

Yogi Amrit Desai: Bee ni. Oluwa Krishna ati Radha awon ni won wa lori pepe wa. Guru mi ni Swami Kripalu-anandi. O wa ni... Ko ji na si Baroda ni bi ti o ni ashrama si. O se iparada fun ogbon din meta odun, leyin na ni o tun se odun mejila ni awe idakeke. Ni iwon ba odun to ku o nsoro lee kan tabi lee meji lodun, nitori pe awon eniyan da le kun.

Prabhupāda: Ko nse atunwi?

Yogi Amrit Desai: O nse atunwi. Ni igba to ba dake, igba yen o le se atunwi. Nitori ni igba ti o so wipe... Ni igba ti a ba pe oruko Olorun, a o ka yen kun gege bi a nda idake duro. Bee ni o nse atunwi.

Prabhupāda: Idakeke, tumo si wipe ki a ma so isokuso. A ma se ipe Hare Krishna. Iyen ni idakeke. Eyi ti a ba fi pa aye mole, soro ni pa awon nkan asan, e je ki a se ipe Hare Krishna. Eyi dara. Sugbon ka kan dake iyen o dara. E dawo duro nkan aini tumo; e so oro to logbon.

Yogi Amrit Desai: Bee ni! Bi e ti wi na lori.

Prabhupāda: Param drstva nivartate (BG 2.59). Param drstva nivartate. Ti a ba fi nkan ailogbon si le, ni igba na param, eyi ti o Ga julo... Param drstva nivartate. Ti e ba ni nkan ti o jo ju, kia kia ni e ma fi eyi ti o to nkan sile. Nitorina gbogbo nkan asan, asan ni. Karma, jnana, yoga, gbogbo won asan ni won je. Karma, jnana, yoga. Paapa titi de awon ise ti bo ti wu ka pe yoga, gbogbo won asan ni.