YO/Prabhupada 0027 - Awon eyan o mo wipe aye atunwa daju



Lecture on CC Adi-lila 7.1 -- Atlanta, March 1, 1975

Bee na (nka iwe:) "Eni ti o wa ninu idande aye wa ni agbegbe alaini ireti. Sugbon emi idande, ti o wa ni owo agbara ti esu tabi agbara ti aye. o ro wipe oun ni idabobo ati ife to pe julo lowo orile ede, agbegbe, awon ore re laimo wipe ti iku ba de ohun kan kan ninu awon nkan won yi ko le gba sile Iyen ni a npe ni maya. Sugbon ko gbagbo Ninu iboji maya, ko tun ni igbagbo ninu igbala. Igbala. Igbala tumo si wipe a gbodo gba ara wa la ninu ayika ti iku ati aaye. Iyen ni igbala gidi. Sugbon won o mo eleyi (nka iwe:) "Awon ofin ti iséda aye ni agbara gan to be gee ti ofi je wipe ko si nkan ninu gbogbo awon ini wa to le gba wa si le lowo ibaje iku." Eni ko kan wa mo eleyi. Ati wipe eyi gan ni isoro wa. Tani o beru iku? Gbogbo eniyan ni o beru iku. Kini idi eyi? Nitori pe eda ki eda elemi, ko ni ipin lati ku. O je ailopin; nitorina ibi, iku, arugbo ara ati aisan awon nkan wonyi je idaamu fun. Nitoripe oun wa lailai, ko ni ibi si nu aye, na jāyate, ati pe eni ti a o bi, ni bakanna ko si iku fun, na mriyate kadācit. Eyi ni ipo wa gan gan. Nitori eyi a nberu iku. Eyi ni isewa wu wa ti idanida.

Nitorina lati gba wa lowo iku... Iyen ni ise wa akoko gege bi omo eda adari hurun. A nko eko isokan Olorun yi fun idi kan soso yi. Eleyi gbodo je ero oni kalu ku wa. Imoran iwe mimo ni yen. Awon ti won je oluso... Oni joba, Baba, Oluko, awon ni oluso awon omode. Won gbodo mo, bi a se ndabobo fun araye... Na mocayed yaḥ samupeta mṛtyum. Nibo ni a ti ma ri iru imo yi, ni gbogbo aye? Ko si iru imo na. Eyi nikan ni, egbe isokan Olorun, ti o ngbe iru imo yi so de. ki ise bo ti wu wa sugbon lati inu iwe mimo ti won se lase, iwe Vediki, alase. Bee na ni eyi je èbè wa. A nsi awon ile ipade ni ikari gbogbo aye fun ibukun akojo omo eniyan. wipe won o mo nkan ti a wa ye fun, won o mo wipe leyin iku a tun di ala-aye. Won o mo awon nkan wonyi. Aye atunwa je ohun to daju, a si le pa ara mole fun aye ojo ola ninu aye yi. E le lo si awon aye to ga miran fun irorun to jo ju, irorun ara. E le duro nbi ninu abobo ipo yin." Abobo tumo si aye ti ara yi. Gege bi won ti wi:

yānti deva-vratā devān
pitṟn yānti pitṛ-vratāḥ
bhūtāni yānti bhūtejyā
mad-yājino 'pi yānti mām
(BG 9.25)

Bee na e le se ipale mo ara yin fun aye rere ninu awon orun to ga. tabi ni agbegbe to jo ju ni aye yi. tabi ki e lo si awon aye miran ni ibi ti awon abara emi ati awon emi jatijati nse akoso. Tabi ki e lo si aye miran ni ibi ti Krishna ti se iferi re. Gbogbo nkan ni o wa ni ojuto yin. Yānti bhūtejyā bhūtāni mad-yājino 'pi yānti mām. E kan ni lati se ipale mo ara yin. Gege bi igba ti a wa ni odo a nko eko - enikan ma di injinia, elo miran ma di oniwosan, elomiran si ma di agbejoro, ati orisirisi awon osise miran won si nse ipale mo pelu eko, bakanna, e le se ipale mo fun ile aye yin miran. Eleyi ko nse nkan ti o soro lati ye wa. Sugbon won o ni igbagbo ninu aye miran, bi o tile je wipe o je nkan imo yepere. O wa daju pe ile aye miran wa nitoripe Krishna so be ati pe pelu ogbon kekere lori o le ye wa wipe ile aye miran wa. Nitorina imoran wa ni wipe "Ti e ba ma se ipale mo ara yin fun ile aye miran, kilode ti e ko ni se iyonu lati se ipale mo lati pada si ile, pada si odo Baba loke? Imoran wa ni yen.