YO/Prabhupada 0029 - Buddha Oluwa,tan awon èlèsu jé



Sri Isopanisad, Mantra 1 -- Los Angeles, May 3, 1970

Bee na ni Buddha Oluwa, se tan awon èlèsu jé. Kilode ti o fi tan won jé. Sadaya-hṛdaya darśita-paśu-ghātam. O jé alaanu pupô. Olorun je abanidaro nigbogbo igba fun gbogbo awon nkan elemi nitoripe gbogbo nkan ni nse omo Re. Awon alainilari won yi nse iku pa awon eranko laini iwonsi, won kan nfi eran se ni pipa... Ti e ba si bi won leere, "Ah, kilode ti e npa awon eranko?" Won a so ni kia kia wipe, "Ah, o wa ninu awon iwe mimo ti Vedas: paśavo vadhāya sṛṣṭa." Pipa eranko wa ninu awon iwe Vedas, sugbon fun anfani wo? Iyen ni lati se idanwo awijo, mantra Vediki. Won a fi eranko sinu ina, ati pelu awijo, mantra Vediki, won a si tun ji pa da s'aye. Iyen ni irubo, irubo eranko. Kii se fun jije. Nitori idi eyi ni akoko ti Kali yi, Chaitanya Mahaprabhu ti fi odi si irubo eyikeyi. nitoripe ko si, a ni wipe, alufa ti o daju ti o le se ipe awon awijo, mantras lati fi se afiwon awijo, mantra Vediki wipe, e wo " Oun lo njade yi" Iyen ni wipe... Ki won to bere si se irubo, bi awijo, mantra na se lagbara si, won ma se idanwo re nipa fifi eranko rubo ati lati ji pada s'aaye. Nigba na ni won ma fi gba wipe awon alufa ti won se ipe awijo, mantra, won je ododo. Iyen ni se idanwo. Kii se fun pipa eranko. Sugbo awon alainilari, fun jije eran won si'we, "E wo, eranko pipa wa nbe." Gege bi o se ri ni Kalakuta... Se e ti de Kalakuta ri? Opopo kan wa, opopo koleji. Won ti so l'oruko miran nisinyi. Boya Vidhan Raya ni won tun so (?) Gege bi... Lonakona, beni awon ile iperan kan se wa. Nitorina ile iperan tumo si wipe awon Hindu, won o ni ra eran lowo awon musulumi. Iyen je nkan alaimo. Bakanna: igbe nibi igbe lo hun. Won nje eran, sugbon ile oja awon Hindu je mimo, ti awon musuluman ni o je alaimo. Awon ero kiro ni won yi. Bi esin se nlo ni yen. Nitori idi eyi... Ni idi eyi ni won se nja: " Emi nse Hindu," Emi je Musulumi," Emi nse elesin Kristi." Ko s'eni to mo esin. S'eri ba yen? Won ti fi esin sile, awon alailogbon. Ko si esin. Esin to daju ni yi, ifokansin Olorun, to nko yan ni bi a se nni'fe Olorun. O pari. Iyen ni esin. Esin k'esin, ko da bi o ti leje esin Hindu, esin Musulumi tabi esin Kristi, si e ba ndagba ninu ife Olorun, e ti di pipe ninu esin yin nigba na.