YO/Prabhupada 0035 - Ninu ara yi awon emi meji ni o ngbe be



Lecture on BG 2.1-11 -- Johannesburg, October 17, 1975

Ni bayi Olorun gba ipo guru, olukoni, O si bere si da ni moran. Tam uvāca hṛṣīkeśaḥ. Hṛṣīkeśa..., Oruko miran fun Olorun ni Hṛṣīkeśa. Hṛṣīkeśa. tumo si hṛṣīka īśa. Itumo Hṛṣīka ni awon oju ati imu, īśa si ni oga. Nitorina Olorun ni oga awon oju ati imu, oju-imu oni kalu ku wa. A o ri alaaye yi ninu ori iwe Iketala, wipe kṣetra-jñaṁ cāpi māṁ viddhi sarva-kṣetreṣu bhārata (BG 13.3). Ninu ara yi awon emi meji ni o ngbe be Ikan ni emi fun rara mi, okan emi, ātmā; ikeji ni Olorun, Paramātmā. Emi Mimo. Īśvaraḥ sarva-bhūtānāṁ hṛd-deśe arjuna tiṣṭhati (BG 18.61). Nitorina alakoso gan gan ni Emi Mimo, Paramātmā. Won gba mi l'aaye ati lo, nitorina oju-imu mi, nkan ti mo npe ni oju-imu mi won o je ti ara mi. Emi ko ni mo da owo mi. Olorun ni o oluda owo, ni pa ti idanida aye, won si fun mi ni owo na lati lo fun ise mi, fun ati jeun, ati lati ma gba awon nkan. Sugbon ni ododo ki ise owo mi. Bi beko, ti owo ko ba se gbe mo, mo si nso wipe "owo mi" - Mi o le lo mo nitori wipe eni ti o nii ti gba agbara re pada. Gege bi ti a ba wa ni ile, ile ti a ya, e ngbe be. Ti eniti o ni ile, onile, ba so eru yin si ita, e ko le gbe be mo. E ko le loo mo. Bakanna, a le lo ara yi titi di igba ti alakoso ti ara yi, Hṛṣīkeśa, gba wa l'ase lati duro sibe. Nitori eyi oruko Olorun ni Hṛṣīkeśa. . Ati wipe Egbe Isokan Olorun yi tumo si wipe a ti gba oju-imu la ti odo Olorun. A gbodo lo won fun Olorun. Eyi ti a ba fi lo fun Krishna, a nloo fun igbadun ara. Eyi ni ipo ibanuje aye wa. Gege bi igba ti e ba ngbe ni ibi ti e gbodo san owo ile, sugbon ti e ko ba le san owo ile - e ro wipe nkan ini yin ni - e o si ri wahala. Bakanna, itumo Hṛṣīkeśa ni Olorun alakoso otito. Won ti fun mi ni ini yi. Bhagavad Gita ti so eleyi.

īśvaraḥ sarva-bhūtānāṁ
hṛd-deśe 'rjuna tiṣṭhati
bhrāmayan sarva-bhūtāni
yantrārūḍhāni māyayā
(BG 18.61)

Yantra: Eroo ni. Olorun ti fun mi ni eroo yi ntirori wipe mo ni ero wipe "Ti mo ba ni eroo bi ara omo eniyan, mo le je igbadun bayi." Olorun si fi ase si: " Ko ri be" Ti mo ba si ro wipe, "Ti mo ba ni eroo ti o ma je ki nle mu eje awon eranko miran" "A f'ase si" Bee ni Olorun wi, "Gba eroo ara ti ekun fun li lo" Bi o ti se nlo ni yi. Nitorina oruko Re ni Hṛṣīkeśa. Ti o ba si ye wa daju wipe " Emi ki nse alakoso ara yi. Olorun ni alakoso ara. Mo fe ni iru ara ti mo le fi gbadun. O ti fun mi sugbon ko dun mo mi ninu. Nitorina mo gbodo ko bi a se nlo eroo yi fun alakoso re," eyi ni a npe ni bhakti. Hṛṣīkeṇa hṛṣīkeśa-sevanaṁ bhaktir ucyate (CC Madhya 19.170). Ni igba ti awon oju-imu won yi - nitoripe Olorun ni alakoso oju ati imu - Oun ni alakoso ara yi - nitori idi eyi ni igba ti a ba lo ara yi fun ise Olorun, iyen ni yi o je ase pe ati igbala aye wa.