YO/Prabhupada 0051 - Eniti opolo re o pe ko le ni iye nkan tio koja ara yi



Interview with Newsweek -- July 14, 1976, New York

Onirohin: Se e ro pe l'ojo kan esin Hare Krishna maa tan kari aye fun gbogbo eniyan.

Prabhupada: Iyen ko le se se. O je nkan ti o wa fun awon egbe omo eniyan ti won loye julo. Nitorina, egbe yi, wa fun awon eniyan ti won loye julo.

Onirohin: Sugbon lara awon ti won loye julo.

Prabhupada: Afi ti eeyan ba loye, to je egbe awon..., ko le ni oye. Bee na, a o lero wipe onikaluku lo ma loye lori. Kṛṣṇa ye bhaja se baḍa catura. Ayafi ti eniyan ba je eni ti o l'ogbon lori gidi gan, ko le di eniti nfokansin Olorun, eyi je ori oro miran. Awon eniyan fi gbogbo okan won sinu ero ara ti aye yi. Sugbon o ju bayen lo. Nitorina eniti opolo re o pe ko le ni iye nkan ti o koja ara yi. Bee ni e ko le lero wipe olu kaluku ma ni iye ifokansin Olorun. Iyen ko le se se.

Onirohin: Won ti nsoro pupo nipa ise pipe orisun-iran omo eniyan, tabi, ka so wipe, igbiyanju lati se iran eniyan ni pipe.

Prabhupada: Kini orisun iran? Onirohin: Ni dada... Kini ise pipe ti orisun iran?

Bali-mardana: L'ana a nsoro nipa sayensi ti nse ni pipe orisun iran omo eniyan. Won se yanju lati mo awon ami, bi ara ati okan se da sile, ni igba na ni won o se yanju lati tunse.

Prabhupada: A ti koko so nipa iyen... Ibo ni iwe yen wa?

Ramesvara: Iwe savarupa damadara. Prabhupada: Beni. Mu wa.

Ramesvara: Kini ibeere yin?

Onirohin: Ibeere mi ni .... E nso tele nipa bi won se ma nlo awon irin ise ode oni, si ti agbegbe na ba wa nii bi ti awon nkan wa....

Prabhupada: Iwe na o si nbi ni? Rara?

Onirohin: E je ki mbi yin leere. Ti o ba ri wipe nipa eto irin ise omo eniyan se ilosiwaju, ni oro miran, ti awon eniyan peere ba di ologbon pupo, kini o je iwon yin fun eniti o logbon...

Prabhupada: Ologbon.... Ti e ba ti le ni iye pe e ki nse ara yi, e yin ni e wa ninu ara. Gege bi e se ni aso kan. Iwo kii se aso na. O le ye eni keni. Iwo wa ninu aso. Bakanna eni ti o ba loye pe oun ki ise ara yi - oun wa ninu ara na... Enikeni lo le ye nitori ni igba ti ara yi ba ku, kini iyato? Nitoripe emi olokun ti o ngbe ninu ara ti lo, nitori idi eyi a so wipe ara na ti ku.

Onirohin: A ri awon eniyan ti won je ologbon gidi, sugbon ti won ko mo kan nipa emi, tabi gan awon eniyan ti won mo wipe won ki nse ti ara yi, tabi wipe ara yi ko je nkankan, ti ara ba ku pe nkan miran si wa. Kilode ti awon eniyan won yi o mo nkankan ni pa emi?

Prabhupada: Ti eniyan ko ba ni imo nkan kekere yi, pe oun ki nse ara yi, ko wulo ju eranko lo nigba na. Iyen ni ti oye akoko ni ipepe ti emi. Ti o ba ro wipê ara l'oun je, ko yato si awon eranko nigba na.

Rāmeśvara: Ibere re ni wipe... Ka gba wipe enikan ni'gbagbo ninu aye miran, ati pe o le je eni t'oloye ni ipa iwon aye. Kilode ti ko le fun ra re....?

Prabhupada: Rara, iwon aye kii se ogbon. Iwon ti aye ni wipe "Emi ni ara yi. Omo Amerika ni mi, omo India ni mi. Atemona ni mi. Aja ni mi. Eniyan ni mi." Iyen ni oye ti aye yi. Oye ti emi ju yen lo, wipe "Emi ko ni ara yi." Ti o ba si gbiyanju lati ni oye idamo ti emi, nigba na ni o je oloye. Bi beko ko nse oloye.

Onrohin: Se o wa je wipe...

Prabhupada: Won ti se apejuwe won gege bi muudha. Itumo Muudha ni ketekete. Nitorina eyi ni oye akoko, ki a ma se idamora wa gege bi ara yi.

Onirohin: Kini oye ti o tele...?

Prabhupada: Bi aja. Aja ni oye wipe oun je ara hun. Ti eniyan na ba ni iru oye yi - oun ni ara - ko dara ju aja lo nigba na.

Onirohin: Oye wo ni wa leyin eleyi?

Bali-mardana: Leyin ti e ba ti mo wipe eyin ki nse ara yi, kini a tun ma kan leyin yen?

Prabhupada: Ha! Ibeere ologbon ni yen. Nigba na a gbodo se iwadi wipe "Ero ti emi nfi sise ko ju ti ara yi lo. Nitorina kini ileri mi? Iyen ni ibeere ti Sanatana Goswami, wipe "E ti gba mi sile ninu ileri aye. Nisinyi e je ki nmo iseju mi." Fun idi eyi e ni lati too oluko ti emi lo, lati ni imo, lati ni oye nkan ti o nse ojuse re nisinyi. "Ti emi o ba nse ara yi, kini ise mi nigba na? Nitoripe mo nfi t'osan t'oru laapon fun ara yi. Mo njeun, mo nsun, mo nndarapo, mo si ndabobo - awon nkan ini ara ni won yi. Ti emi ko ba nse ara yi, nigba na kini ise mi? Ogbon ni yen.

Ramesvara: O ti so bayi wipe, "Kini ese ti o tele imo wipe emi ki nse ara yi"? Prabhpada so wipe, ese ti o tele ni lati se iwadi ojuse re. ati lati ni imo na, o gbodo gba imoran l'odo eniti o ti mo emi ni oran, tabi oluko ti emi.

Onirohin: Oluko emi ni pa ti awon iwe re.

Bali-mardana: Fun ra re, tabi...

Pusta-Krishna: Prabhupada nse alaaye wipe nisinyi ti ani ero ara a ni opolopo awon ojuse. A nsise, a nse idarapo, a njeun, a nsun, a nse abobo ara wa - nkan pupo. Gbogbo awon nkan won yi nse nipa ti ife ara. Sugbon ti emi o ba nse ara yi, kini ojuse mi nigba na? Kini ise dede oju mi? Nitorina ese ti o tele wipe bi a ba ti ni oye yi, nigba na a gbodo gba imoran lodo ojise Olorun. se ilosiwaju ati ni oye nkan ti o je ise otito. Iyen se pataki.

Prabhupada: Fun jije, sisun, idarapo ati idabobo a ni lati ni eko lowo oluko kan. Ka so nipa jije, a ngba imo lowo eniti o mo nkan daju, iru nkan wo ni a le je, iru eronja, iru... Nitorina iyen na nilo eko. Sisun na nilo eko. Bee na fun ero ti ara a ni lati gba eko lowo awon miran. Bee na ni ti o ba koja ero ara aye yi - o loye wipe "Emi kii se ara yi; Emi okan ni emi nse" - ni bakanna o gbodo gba eko ati imoran lowo eniti o mo nkan daju.