YO/Prabhupada 0055 - E nfi ara kan Olorun nipa ti igboran



Lecture on BG 2.18 -- Hyderabad, November 23, 1972

Asotele Chaitanya Mahaprabhu: "Bi awon oye ilu ati awon abule ti won wa lori ile aye, ni gbogbo ibi ni won ti ma se iranti mantra Hare Krishna, tabi oruko Oluwa Chaitanya, okiki re a kan." Iyen nsele. Ainiwon pàpà lo wa lati mu esin Hare Krishna jade kari aye. Iyen wulo. O se wa laanu, biotilejepe Chaitanya Mahaprabhu fi oro yi le gbogbo awon Indian lowo... Kii se fun awon Bengalis, nitoripe oje omo Bengal. Ko fi gba kan so wi pe fun awon Bengalis. O so wipe, bhārata-bhūmite manuṣya-janma haila yāra (CC Adi 9.41). Ni ori ile mimo ti Bharatavarsa, enikeni ti o ba ti gba yanbi gege bi omo eniyan, gbodo se aye re ni pipe." Janma sārthaka kari'. E kole je oniwasu lai koko se ile aye yin ni pipe. Ti mo ba duro bi alaipe, emi ko le wasu. O gbodo wa pe. Eleyi o soro rara. A ti ni itosona awon ojogbon nla ti won je eni mimo ati lodo Olorun, Krishna, Fun ra re.

Nitorina lati mu aye wa pe ko soro rara. A kan se aibikita. Eyi ni ailoriire wa. Mandāḥ sumanda-matayo manda-bhāgyāḥ (SB 1.1.10). Nitoripe a je manda, manda-matah, at gba awon ogbon etan kan, etan ti "ism", ti a si tan ra wa je. A gbodo gba ona to daju l'odo shastra, iwe mimo. Igba yen ni a ma di ologbon. Su-medhasaḥ. Yajñaiḥ saṅkīrtana-prāyair yajanti hi su-medhasaḥ (SB 11.5.32). Ilana ona-kukuru. Egbe awon ojogbon eniyan ni won ma gba esin sankirtana fun idagbasoke emi. Otito ni, o se fii dani loju, won si se laase. E ma se ni igbagbe. E gba ikepe Hare Krishna yi tokan tokan, ati nibi kibi... Niyamitaḥ smaraṇe na kālaḥ. Ko si awon ofin tabi awon ilana, wipe "O gbodo se ni akoko yi tabi akoko kan, ni ipo yi tabi ni ipo miran." Rara. Nitoripe won se ni pataki ni paapa fun awon emi ti won wa ni idande, ko si ofin kole-kole kankan. Nāmnām akāri bahudhā nija-sarva-śaktis tatrārpitā niyamitaḥ smaraṇe na kālaḥ. Oruko na, oruko mimo ti Olorun, ni agbara gege bi Olorun. Ko si iyato laarin Krishna ati oruko Re. Olorun je Atobi julo. Nitori idi eyi ko si iyato larin oruko Olorun, aworan Olorun, Iwa Olorun, elegbe Olorun, ise dede Olorun ati Olorun. Gbogbo nkan lo je Olorun. Ti e ba ngbo nipa Olorun, e si mo nigbana wipe e nfi ara kan Olorun nipa ti igboran. Ti e ba ri aworan Krishna, iyen je wipe e nri Olorun fun ra Re. Nitori Olorun je Atobiju. O le gba esin yin, bakanna. Nitoripe O je gbogbo nkan. Īśāvāsyam idaṁ sarvam (ISO 1). Agbara Re. Parasya brahmaṇaḥ śaktis tathedam akhilaṁ jagat. Gbogbo ohu ni se agbara Re. Bee na ti a ba wa ni ifowoba pelu agbara Olorun, pelu imo kekere, a o si fowoba Olorun taara. Eto na ni yi. Bi e ba se wa ni isumo Olorun leralera, iyen ni ifokansin Olorun. Igba na eyin o si di mimo. Di mimo. Bi igbati e ba fi irin sinu ina, a gbona, a gbona si, gbona si, titi ti a fi di ina eje. Nigbati o ba di ina eje, o di ina. Kii se irin mo. Bakanna, ti e ba nfi gbogbo igba fokansin Olorun, e o di eni Olorun. Eto na ni yi. Nigba na ni gbogbo nkan ma di mimo; nigba na ile aye ti emi yin o si farahan. Ile aye yin yi o si je aseyori.