YO/Prabhupada 0056 - Awon alase mejila ni won daruko ni won daruko ninu awon iwe mimo



Lecture on SB 7.6.1 -- Madras, January 2, 1976

Prabhupāda:

śrī-prahrāda uvāca
kaumāra ācaret prājño
dharmān bhāgavatān iha
durlabhaṁ mānuṣaṁ janma
tad apy adhruvam arthadam
(SB 7.6.1)

Eyi ni Prahlāda Mahārāja. O je ikan ninu awon alase lori ifokansin Olorun. Awon alase mejila ni won daruko ninu awon iwe mimo, shastras:

svayambhūr nāradaḥ śambhuḥ
kumāraḥ kapilo manuḥ
prahlādo janako bhīṣmo
balir vaiyāsakir vayam
(SB 6.3.20)

Alaaye Yamaraja ni yi nipa awon ti won je alase lori dharma. Dharma tumo si, bhāgavata-dharma. Mo ro wipe mo se ni alaye lale ana, itumo dharma ni bhagavata. Dharmaṁ tu sākṣād bhagavat-praṇītaṁ (SB 6.3.19). Gege bi Alagba Olori Adajo wa se ndajo ninu ofin bee na ni eniti o se pataki tabi onisowo kan ko le da ofin sile, rara o. Ijoba ni kan lo le da ofin sile, ni pa akoso ilu. Eni Kankan ko le se. Iyen ko ni... Kani ninu ile idajo, ti enikan ba so wipe, " Alagba, mo ni ofin temi," Alagba Onidajo ko ni gba ebe na. Bee na ni bakanna, e ko le da dharma sile. Boya o je enikan pataki... Olori Oludajo paapa, ko le da ofin sile. Ijoba ni o nse ofin. Bakanna, dharma tumo si bhāgavata-dharma ati awon eyi keyi dharmas, won ki se dharmas. Won o le gba won, Gangan ni ona kanna, ti won o ni gba ofin ti e da sile ninu ile yin. Nitorina dharmaṁ tu sākṣād bhagavat-praṇītaṁ (SB 6.3.19).

Ati kini bhagavat-praṇītaṁ dharma? Won sapejuwe eyi ninu Bhagavad Gita, a mo, onikaluku. O wa. Olorun wa. Ise pataki Re je dharma-saṁsthāpanārthāya, lati wa se idasile awon ofin esin, tabi se atunse. Dharmasya glānir bhavati bhārata. Yadā yadā hi dharmasya glānir bhavati bhārata (BG 4.7). Bee na nigba miran glaani ma wa, nigbati aiba-dogba ba wa ninu eto esin, dharma. Nigba na ni Olorun soka le wa. Paritrāṇāya sādhūnāṁ vināśāya ca duṣkṛtām (BG 4.8). Yuge yuge sambhavāmi. Nitorina dharma yi, Olorun ko wa lati se atunse irukiru dharmas: Dharma ti awon Hindu, dharma ti awon Musulumi, dharma ti awon omo eleyin Kristi, dharma ti Buddha. Rara. Gege bi Śrīmad-Bhāgavatam ti wi, dharmaḥ projjhita-kaitavo (SB 1.1.2). Dharma na ti o je iru eto atannije, iru dharma yen je projjhita. Prakṛṣṭa-rūpeṇa ujjhita, tumosi ohun ti a nso sita, tabi fi so nu. Bee ni dharma to daju ni bhagavat-dharma, dharma otito. Nitori idi eyi ni Prahlāda Mahārāja se so wipe, kaumāra ācaret prājño dharmān bhāgavatān iha (SB 7.6.1). Ni otito, dharma tumo si Olorun, ibatan wa pelu Olorun, ati fi fi se iwa wu gege bi ibatan wa na, ki awa le se aseyori ninu aye wa. Iyen ni dharma.