YO/Prabhupada 0059 - Mase gbagbe ise re gidi



Lecture on BG 2.14 -- Mexico, February 14, 1975

Nigbana a si beere wipe, "Ti mo ba je alaiku, kilode ti opolopo ipo ibanuje aye iya se wa? Ati kilode ti iku fi je dandan?" Bee ni eyi si je ibeere ologbon, wipe "Ti mo ba je alaiku, kilode nigbana ti a ma fi wa ninu ara ti o nje iya iku, ibi, arugbo ati aarun?" Nitorina ni Krishna se ko wa nimoran wipe ara ile aye yi ni idi ipo ibanuje aye. Awon ti won je karmis, eyi tumosi awon ti won ti fi aye won fun ife ti ara... Awon ni won npe ni karmis. Awon karmi won o bikita fun ijowaju.; won kan nfe nkan irorun aye ni bayi. Gege bi omo ti o ba ni itoju awon obi re, a sere titi ojo ko si ni se bikita fun ijowaju re, ko ni gba eko. Sugbon gege bi omo eniyan, ti a ba je ologbon daju daju, a o se iyanju pupo bi a se le ni aye na tabi ara ti ko ni si iku, ibi arugbo ati aarun mo.

Nitorina egbe ifokansin ti Krishna yi wa lati ko eniyan sona fun eleyi. Nisinyi, enikan le so wipe "Ti mo ba kan fi okan mi sin ninu Krishna, nigbana bawo ni emi ose gbe bukata awon nkan ini fun igbesi aye mi. Bee ni esi na si wa ninu Bhagavad-Gita, wipe enikeni ti o ba fi ara re s'ise Olorun, fun nkan ini igbesi aye re, Olorun yi o se akoso. Olorun ni O nse akoso gbogbo eda. Eko yo bahūnāṁ vidadhāti kāmān: "Olorun Oba kan soso ni o nse akoso gbogbo eda elemi. Bee na fun eniti o fi okan re sin lati pada sodo Baba-loke, ko le r'ogun aini. Fi okan re bale. Olorun so ninu Bhagavad-Gita, teṣāṁ satata-yuktānāṁ yoga-kṣemaṁ vahāmy aham: (BG 10.10) "Olufokansin ti o nfi gbogbo igba se ise fun Mi, Mo nse akoso bi awon nkan ini fun igbesi aye re yi o se je dede. Apeere kan ti o wulo ni pe ninu egbe ifokansin Krishna yi ni ogorun ile ipade, ati pe ni ikokan awon ile esin won yi, awon olufokansin lati bi marun le logun titi di bi ogorun meji ati adota ni won ngbe nbe. Bee na a ko si ni ere tabi owo osu ti o nwole dede, ati bee ni a si nna egberun ogota dollars ni gbogbo ikari awon ile isin wa lo-so-su. Sugbon nipa ti ore ofe Olorun ko si ogun aini lodo wa; gbogbo nkan ni o wa ni amojuto. O ma nse awon eniyan niyanu nigba miran wipe "Awon eniyan yi o ni se lowo, won o gba sé kan ni sise, won kan nke pe Hare Krishna. Bawo ni won se ngbe?" Sugbon iyen kii se ibeere. Ti awon ologbo ati awon aja ba ngbe ni pa ti aanu Olorun, awon olufokansi le gbe ile aye ti o rorun ni pa ti aanu Oluwa.

Ibeere bayi ko nse pataki, sugbon ti enikan ba nro wipe " Nisinyi ti mo ti di omo egbe ifokansin Olorun, sugbon mo nse roju opolopo nkan," fun awon eniyan bee, tabi fun gbogbo wa imoran na ni wipe mātrā-sparśās tu kaunteya śītoṣṇa-sukha-duḥkha-dāḥ: (BG 2.14) "Awon iroju ati idunnu won yin dabi igba otutu ati igba erun" Nigba otutu omi nseni ni ilara, bee na nigba erun omi ndun mo wa. Nitorina ewo ni ipo omi? O ndun mo ara tabi o nro ni lara? Kii se nkan ilara, be ni kii nse didun, sugbon gege bi igba ti o nse, ti o ba kan ni lara o dabi pe ohun ni eni lara tabi ohun dun mo ni. Won se alaye iru inira ati idunnu won yi ni bi: "Won nwa won si nlo. Won o wa lailai" Āgama apāyinaḥ anityāḥ tumo si wipe " Won nwa won si tun nlo; nitorina won o wa lailai." Olorun wa se ni imoran, tāṁs titikṣasva bhārata: "Saa fara daa" Sugbon ma se gbagbe ise re gidi gan, ifokansin Olorun. Ma se fo kan si inira ati idunnu yepere ti aye yi.