YO/Prabhupada 0071 - Omo Olorun alaibikita oninakuna

From Vanipedia
Jump to: navigation, search
Go-previous.png Previous Page - Video 0070
Next Page - Video 0072 Go-next.png

Recklessly Wasteful Sons of God - Prabhupāda 0071


Room Conversation With French Commander -- August 3, 1976, New Mayapur (French farm)

Gbogbo wa la je alaibikita oninakuna omo Olorun. Omo Olorun ni wa, ko si iyemeji, sugbon nisinyi, alaibikita oninakuna. A nse nibaje igbesi aye oniyebiye wa pelu, a je alaibikita pupo. Bee ni egbe isokan Olorun ni lati mu opin si iwa aibikita won. ati lati mu wa sinu imo gbigba ojuse won, lati pada si ile, si odo Baba loke. Iyen ni isokan Olorun. Sugbon awon eniyan ti di alaibikita pupo, sibe ge, were ti e ba so nkan kan nipa Olorun, won a ti bere si ma rerin lowo kanna, "Ah, kini nkan ainilari, Olorun." Iyen ni alaibikita to ga ju lo. Nigba kan ana India gba oro Olorun mori gidi gan. Sibe sibe, India si se ni pataki. Nisinyi, awon oselu ojo oni, won nro wipe awon ara India ti di baje, won o ni ise miran ju ki won se ronu Olorun - won ki nse bi awon ara Amerika tabi awon ara Yurop ti won nfi gbogbo igba nronu si idagbasoke oro ati ekun.

Bee na eyi ni ipo na, o si je isoro pupo, sugbon a si le se nkan fun omo araye yi, nipa si se iwasu ti egbe isokan ti Olorun. Awon ti won si ni ori rere, won a wa, won a si mu ni pataki. Awon alaibikita oninakuna omo, a ni opolopo apeere. Fun apeere kan, gege bi ti epo petrolu ba wa ni ipamo won si gbo wipe won le mu oko si se pelu petrolu lai lo esin. Bee na, won si bere si se awon aimoye oko lati ba gbogbo epo na je. Eyi ni iwa alaibikita. Ti o ba si tan, nigba na won wa ma ke. O si ma tan. Nkan bayi nsele. Iwa slaibikita. Gege bi omo oninakuna, baba fi awon nkan ini sile, o kan nlo nilo. Gbere ti won ri, gbere lo ti tan. O pari. Iyen ni alaibikita. Ti ara ba l'okun die, ti o ba si ti to adun ife ara wo, "Ahh, lo o, loo," lo gbogbo agbara na. Opolo a yo lagbari. Bere lati odun kejila, igba ti o ba fi de ogbon odun, gbogbo e a titan. Igbana l'o di okofo. Ni igba omode wa - igba omode wa, tumo si, kani, ogoji odun seyin, tabi kani ogorun odun seyin - ko si oko ni gba na. Sugbon nisinyi, ibikibi ti o ba lo, ni eyikeyi orile ede, e ma ri egbe gberun oko. Eyi ni alaibikita. Ogorun odun seyin won le se lai lo oko, sugbon nisinyi won o le se lai lo oko. Ni pa ona yi, won nso awon nkan ilo won di pupo si, lainidi. Eyi ni alaibikita. Ati pe awon olori na, ti won ma gba won niyanju ni ona alaibikita yi, oun ni olori to dara. A ni tani o ma so fun wipe, "E fi iwakuwa yi sile, e wa sinu isokan Olorun," ko si eni ti o ni aniyan. Andhā yathāndhair upanīyamānās te 'pīśa-tantryām uru-dāmni baddhāḥ (SB 7.5.31). Eyi la npe ni omugo nmu omugo rin. Won o mo wipe awon mejeji wa labe awon ofin lile ti idanida. (idake) ...

Bi awon ofin idanida se nse se. Won je alailoye patapata. Won o mo. Eyi ni ilaju ode oni. Awon ofin idanida gbodo sise l'ona ti re. Bi e ba se l'amojuto tabi ti e o ba si se, iponju yin ni yen. sugbon awon ofin idanida ko ni se lai sise. Prakṛteḥ kriyamāṇāni guṇaiḥ karmāṇi sarvaśaḥ (BG 3.27). Sugbon awon alailofin won yi, won o mo bi awon ofin idanida se nse se. Won ngbiyanju pelu ogbon arekereke, lainiye ninu, lati bori awon ofin idanida. Sayensi ni eyi, sayensi awon alailofin, ti ko le se se, sugbon won ngbiyanju. Iyen ni won pe ni ijoba alailofin. Baba were. Abi awon oni sayensi won o so be? " A ngbiyanju lati bori." Jaguda, e o le ri yen se lailai. Sugbon ijoba alailofin yi nba selo. Won si npatewo, "Ah, o dara gan, odara gan, o dara gan." "Ah e nlo si ori osupa." Sugbon l'eyin gbogbo igbiyanju won, owo o to pepe. "Ko wu lo" Ko ju bayen lo. Se e mo itan na? Itan amotesin? O nse laa laa lati ja osan oyinbo, o nfo soke, nfo soke. Nigbati ko je aseyori, o ni, "Ah, ko wu lo. O kan, ko wulo" Bee na won nse bayi. Awon amotesin nfo soke, ko ju yen lo. A si leri bi awon alailofin won yi se nfo soke lainilari; (Erin) Nitori e ni a se nse ikilo fun awon eniyan ki won ma tele awon omugo amotesin. E se ologbon ki e wa ni isokan Olorun. Iyen a mu ile aye yin yori si rere.