YO/Prabhupada 0077 - E le fi won se kiko pelu ogbon ati oye



Ratha-yatra -- San Francisco, June 27, 1971

Olorun so wipe, awon ti won wa nigbagbogbo, wakati merin le logun fi nse ise Olorun... Gege bi awon omo eleko yi, awon omo egbe Isokan Krishna, e ma ri won ti won wa ninu ise Olorun wakati merin le logun. Iyen ni, mo lero lati wi pe, iyi isokan Olorun. Gbogbo igba ni won nni nkan se. Eto ayeye ti Ratha-yatra yi je kan ninu awon nkan na, bi o ti le kere, ojo kan, gbogbo yin le se wa po ninu ise isokan Olorun. Ifi se wa wu kan na ni yi, ti e ba si fi se wa wu fun gbogbo igbesi aye yin, ti o ba si di igba ati fi aye sile, ti e ba ni ore ofe lati se iranti Olorun, ile aye yin ti yori si rere. Ifi se wa wu na je dandan. yaṁ yaṁ vāpi smaran loke tyajaty ante kalevaram (BG 8.6). A ni lati fi ara yi sile, iyen ti daju. Sugbon ni igba tiku ba de, ti a ba se iranti Olorun, lesekese ni e ma yo si ibugbe Olorun. Ibi gbogbo ni Olorun wa, sugbon sibe na Olorun ni ibugbe pataki, ti won npe ni Goloka Vrndavana. O le ye yin wipe ara wa, ara tumo si awon ipa ara, ati olori awon ipa ara ni okan, ti o je nkan abami, ti o nse akoso awon ipa ara. ati eyi ti o ga ju okan lo ni oye, ati lori oye ni emi na wa. A ko ni irohin, sugbon ti a ba fi eto bhakti-yoga yi se wa wu, diedie ni a ma ni oye nkan ti emi je. Emi ki nse ara yi. Eyi, lakopô paapa awon ologbon nla, nla, ojogbon nla nla, awon onise sayensi, awon na wa ninu ero inu ti ara yi. Olukaluku nro wipe, "Ara yi ni mi," sugbo iyen je asise. A ki nse ara yi. Ma se alaye. Ara tumo si ipa ara, sugbon okan nse akoso awon ipa ara, oye na si ndari okan, emi na si ndari oye. Iyen je aimo fun yin. Ko si eto ipinle eko ni ikari aye ti won ko ni ni imo iwa l'aaye emi. ti o si je oye pataki ti o se alai mani fun omo eniyan. Omo eniyan ko wa lati paaye danu bi awon eranko. ki a kan ma jeun, maa sun, ma bara lo ati lati ma se dabobo. Igbesi aye eranko ni yen. Oye afikun ti awon omo eda nilati wa ni lilo fun bi a se le ni imo, "Emi... Tani mi? Mo je èmi-okan." Ti o ba ye wa wipe "Emi-okan ni mi," wipe ero inu ti ara yi, ti o ti da ijamba si ile aye yi... Nipa ero inu ara, emi nro wipe "Omo India ni mi," iwo nro wipe "Omo Amerika" oun na si nro nkan miran, nkan miran. Sugbon ikan na ni wa. A je emi-okan. Gbogbo wa laje iranse ayeraye fun Olorun, Jagannatha.

Bee na ojo oni dara gan, ojo rere. Ni ojo oni yi Oluwa Krishna, nigbati o fi wa lori ile aye, O fiyesi isin apejo ipade orun ati osupa ni Kurukshetra ati pe Krishna, Oun pelu egbon Re Balarama, ati Subhara, aburo won obirin, won jo lo si idan Kurukshetra. Ile Kurukshetra na si wa titi di ojo oni ni India. Ni ojo kan ti e ba lo si India e ma ri pe ile Kurukshetra si wa nbe. Bee na ipejo isin Ratha-yatra yi je ise ni iranti igba ti Krishna lo se ibojuwo Kurukshetra pelu egbon ati aburo Re obirin. Bee na Oluwa Jagannatha, ati Oluwa Chaitanya Mahaprabhu, O wa ninu ayo pupo. O wa ninu iwa inu ife ti Radharani, bee na Lo se nronu, "Krishna, jo pada wa si Vrndavan." Be Lo se njo niwaju Ratha-yatra, o si ma ye yin ti e ba ka awon kan ninu awon iwe ti e te si ta..., iwe ti egbe wa ta sita. Ikan ninu awon iwe na nje Awon Eko Oluwa Chaitanya. O je iwe ti o se pataki. Ti e ba fe mo ni pa egbe isokan Olorun yi, a ni opolopo awon iwe. E le fi won se kiko pelu ogbon ati oye. Sugbon ti e ko ba ni oyaya lati ko eko, ti e ba kan fi kike pe Hare Krishna yi ni sise, diedie gbogbo nkan a se fihan fun yin, e si ma ni oye ibatan yin pelu Olorun.

E se pupo fun ibapin yin ninu isin ipade yi. Nisinyi e je ka korin Hare Krishna pelu Jagannātha Swami. Hare Kṛṣṇa.