YO/Prabhupada 0079 - Ki se nipa ola mi



Lecture on SB 1.7.6 -- Hyderabad, August 18, 1976

Nisinyi, awon ajoji yi, won ki nse boya Hindu, tabi Indian tabi brahmanas. Bawo ni won se ngba? Won ki se awon omugo ati jaguda. Won wa lati idile to gbajumo, alakowe. Bee na ni a ni ile-ijosin wa ni Iran. Ni Tehran, ibe ni mo ti nbo bayi. A ni opolopo awon omo leyin ti won je Musulumi, ti awon na ti gba ona yi. Ni Afrika won ti gba ona na. Ni Australia won ti gba ona na. Ni ikari aye. Bee ni iyen ni ise Chaitanya Mahaprabhu.

pṛthivīte āche yata nagarādi grāma
sarvatra pracāra haibe mora nāma
(CB Antya-khaṇḍa 4.126)

Eyi ni isotele Oluwa Chaitanya Mahaprabhu. Bi opolopo awon ilu ati abule ti won wa ni ori ile aye egbe isokan Olorun yi a tan ka. Nitorina ki se ni pa ola mi, sugbon nipa igbiyanju kinkinni, iyanju nirele. Bee na ti enikan soso ba le se, ka ni, iseyori, kilode ti gbogbo wa o le se? Chaitanya Mahaprabhu ti fi agbara fun gbogbo awon omo orile ede India ni ofin lati je asoju. Bhārata-bhūmite haila manuṣya-janma yāra (CC Adi 9.41). O nba awon manusya soro, ki se awon ologbo ati awon aja. Nitorina manuṣya-janma yāra janma sārthaka kari'. Ni akoko julo, gbiyanju lati ni oye idi aye yi. Iyen ni won npe ni janma sārthaka. Janma sārthaka kari' kara para-upakāra. Ma lo. Ibi gbogbo ni won ti nse ibeere gidi gan lori isokan Olorun.