YO/Prabhupada 0083 - Ekorin Hare Krishna lehin na gbogbo nkan ma wa



Lecture on SB 7.9.11-13 -- Hawaii, March 24, 1969

Bee ni Prahlada Maharaja so wipe - a ti se ijiro lori eleyi tele pe ko gba ijeri iwa kan kan. Lati tu ninu, lati se ife, lati se itelorun, e ko ni ilo ijeri iwa tele: oh, e gbodo se ase yege idanwo ni ile eko univasiti, tabi pe e gbodo di olowo bi Rockefeller, tabi Ford, tabi e ma di eyi tabi t'ohun... Ko si ipo kan kan. Ahaituky apratihatā. Ti e ba fe ni ife Olorun, ko si idaduro. Ko si idaduro. Ona ti si sile. E kan ni lati je olododo. Ko ju yen lo. Olorun a si pa ona mo. Ati pe ti ko ba si ododo, nigbana ojiji Olorun lo wa mbe. Ni gbogbo igba lo ma, o ma fi ikose s'ona "Ki se eleyi, eyi ko, ki se eyi" Bee ni Prahlada Maharaja ba se ipinnu wipe " Bo ti le je wipe omode ni mi, Emi o ni eko ile iwe, mi o ni eko iwe mimo ti awon Veda, ti mo si je omo bibi inu baba ailanigbagbo, eniti a bi sinu ese, pelu gbogbo ijeri buburu... Bee na, awon ojogbon ti won ni iwa rere ni won nsin Olorun, ti won nko orin Vediki, ati awon oniwasu, ti won ni imo ijinle ninu asa ibile. Emi o si ni iru ijire iwa won yi. Sugbon sibe na, gbogbo awon orisa ti won ni ipo nla nla,, won ti bi mi lee re. Iyen je wipe emi na le tu Olorun ninu. Bibeko bawo ni won se le bi mi lee re? Nitorina ipo ki po ti mo ba ni, oye k'oye ti mo ba ni, ki nle fi sore fun Olorun Nitorina egbe wa, bi egbe isokan Olorun wa se ri niyi, wipe ipo ki poti ti e ba ni, iyen ti to. E beere pelu ipo na E gbiyanju lati se ise fun Olorun pelu ipo yin. s Nitoripe nkan to je ipo gidi - imo yin fun ise. Iyen gan ni ijeri ipo. Bee na e je ki imo na dagba si, ki se ipo ode, ewa, ola, eko, eyi t'ôhun, rara. Awon nkan won yi o ni iwulo. Won a ni iwulo ti won ba fi won se ise Olorun. Ti o ba je Olowo oloro, ti o ba fi ola re si ise Olorun... Iyen se dede. Sugbon ki se dandan lati je olowo oloro. Nigbana e le se ise Olorun.

Bee ni Prahlada so wipe, nīco ajayā guṇa-visargam anupraviṣṭaḥ pūyeta yena pumān anuvarṇitena. Ni bayi, a le bere wipe Prahlada je omo baba onibawon. Eyi ni ijiyan. Prahlada ki nse alaimo, sugbon fun iyan-jija, je bibi eni yepere, tabi ni idile talika, tabi enikan, ti a leri nkan pupo pupo lati so nipa re. Sugbon Prahlada so wipe, "Ti mo ba bere, lati ma fi iyin fun Olorun nikan, nigba na emi o si di eni mimo" Ti mo ba se adura iyasi mimo... Adura Hare Krishna yi je ona ti a fi ndi mimo. Ki se pe mo gbodo gba ona miran lati di mimo ki nto le gba adura Hare Krishna. Rara. E beere si ke pe. Nigba na ni o di mimo. E ma di mimo. E beere si ma se ikepe Oluwa. Ni ipo ki po ti e le wa, ko se nkan kan. Ni ododo mo bere, egbe isokan Olorun yi - ki se pe awon eniyan wa lati ipo mimo. Gbogbo wa, oni kaluku yin, le mo wipe, awon ti won wa si odo mi, gege bi eko ti won ba ti ni lati igba omode won... Gege bi ajohun ile India, won o ti le mo ipile imo toto. Kini iwulo lati beere iwemimo? So ye yin. Ni ile India lati kekere ni eko na ti nbere, won ko omode lati we, lati fo eyin la ra-ro. Beni Mo si ranti, nigba ti omo mi keji je omo odun merin, bee na ni mo se ma nbi leere, ko to jeun aaro, "Fi eyin re han mi" Bee na lo si ma fi han..., "O da be, o ti fo eyin re. Bo se dara ni yen. Nigba na lo l'aaye ati jeun aaro." Bee ni eko yi se wa. Sugbon nibi, ni orile ede yi, eko... Daju daju, won wa nbe, sugbon won o se ni lile. Iyen ki se nkan kan. E ke pe Hare Krishna. Bere Hare Krishna. Nigba na ni gbogbo nkan yi o si wa. Gbogbo nkan yi o si wa.