YO/Prabhupada 0116 - Ema fi iyé aye yin sofo



Lecture with Allen Ginsberg at Ohio State University -- Columbus, May 12, 1969

Emi wa n'be, lati inu emi ni ara wa ti ni idagbasoke, emi-ọkàn na si nse iṣipo pada lati ara kan si miiran. Nkan ti a npe ni idagbasoke. ilana itiranyan yi si nboju lọ, awon eda aye 8,400,000, awon aromiyo, awon eye, awon eranko, awon ohun ọgbin, ati orisirisi eda aye yi. A ti ni bayi okan ti o ti dagbasoke, aye ti omo adari-hunrun. O ye ki a lo daradara. Ebge isokan Olorun wa niyen. A kan n'se l'eko fun awon eniyan niwipe "Ema fi iyé aye yin sofo, igbesi-aye omo eda. Ti e ba ti padanu anfani yi, e nfi iku pa ara yin niyen" Ikede wa niyen. Ma se ara re. Gba fun isokan Olorun yi.

Ilana naa wa ni irorun gidi gan.. Kosi idi lati gba ilana yoga to le gan, tabi ke bo sinu ẹkọ ọgbọn. Iyen ko le ṣee ṣe ni asiko yi. le aye. Ìyẹn ni pé... Emi ko nsoro lati iriri ara mi, sugbon mo n mu iriri ti awọn ācāryas ńlá ati awon ojogbon nla. Won so wipe "kalau nāsty eva nāsty eva nāsty eva gatir anyathā. Ti o ba fẹ lati mọ ara rẹ, ti o ba fẹ lati mọ ohun ti atunwa re ma je, ti o ba fẹ lati mọ nipa Ọlọrun, ti o ba fẹ lati mọ ohun ti ibasepo rẹ pelu Olorun se ri, gbogbo nkan wọnyi yoo wa ni hàn fun nyin - eyi ni imo to daju - ti e ba korin mantra yi, Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare/ Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare. O je iwulo. A o si bere ohunkohun. A ki nse igboya pe "Ma fun e ni ohun kan, asiri mantra, yi o si na e ni idiyele aadọta dọla." Rara. O jẹ ìmọ fun gbogbo eniyan. Jọwọ gba o. Iyen nikan Ia beere. A nbe yin, "Ki e ma ba ile aye yin je. E jo e gba mantra yi. Ki e ko lorin ni gbogbo ibi ti e ba fe". Ko ni ofin imole ti eni lati tele. Nigbakugba ti o ba fẹ, nibikibi ti o ba fẹ, eyikeyi majemu ti aye. Gege bi a se korin ni saaju idaji wakati seyin. Ni ipo eyikeyi, e si ni idunnu wo inu emi. Bakan na e si tesiwaju. Ekorin Hare Kṛṣṇa mantra yi. O jẹ fi fun yin l'ọfẹ. Sugbon ti o ba fẹ lati mọ ohun ti Hare Krishna mantra yi je nipasẹ imoye, nipa ìmọ, nipa irogun, a ni opo awon iwe... E ma se rowipe a kan njo ijo didinrin. Rara, a l'ọwọ lẹhin. Nítorína e gbiyanju lati ni oye egba ifokansin Olorun yi. Mo ti wá si orilẹ-ede yin paapa lati fun yin ni ihin rere yi. nitori ti o ba ti gba eyi, ti o ba le ni oye yi Imọ ti isokan Olorun, awọn apà aye miiran yio tun tẹle, oju aye yi o si ni iyipada. Otito oro niyen.