YO/Prabhupada 0123 - Fi ipa muni lati jowo - Iyen je ore-ofe pataki



Lecture-Day after Sri Gaura-Purnima -- Hawaii, March 5, 1969

Olufokansin: Ṣe a le beere lowo Olorun lati mu wa jowo fun Un ni lile, nitori bi a ti se faramu?

Prabhupāda: Beeni, ele beere lowo Re. O si le se ni dandan nigbamiran. O si fi ọ si iru ipo ti ko ni si ona miiran ju lati jowo fun Olorun. Beeni. Iyen je ore-ofe pataki. Iyen je ore-ofe pataki. Beeni. Oluko igbala mi fe ki n se waasu, ṣugbọn emi kò fẹ, osi se ni dandan. Beeni. Iyen ni iriri mi ilowo Emi ko tile ni ifẹ lati gba aṣẹ sannyāsa ati waasu, ṣugbọn oluko igbala mi nife si. Ko se mi ni iwuri pupo, sugbon o fi mu mi l'agbara. Eleyi na lesele. Iyen je ore-ofe pataki. Nígbà tí ó fi agbara mu mi, ni ìgba na, Mo ro pe "Kí ni èleyí? Kini ...? Se mo nse asise ni tabi ki leleyi? Idamu si mu mi. Sugbon lehin igba die, o ye mi wipe ore-ofe to gaju lose fun mi. Se e ri bayi? Nitorina nigbati Olorun ba fi ipa mu ni lati jowo, iyen jẹ nkan nla rere. Sugobn gbogbo igba ko ni O nṣe bẹ. Sugbon O se fun eniti o jẹ olododo gidigidi ninu iṣẹ Olorun. sugbon nigbakanna ti o si tun ni ifẹ diẹ fun emi igbadun. Nitori bẹ Oun a se, pe "Omùgọ eniyan yi ko mọ wipe awọn ohun elo nkan aye yi ko le fun láyọ ó sì nfi tọkàntọkàn wá ojurere Mi. Nítorí náà, o si jẹ òmùgọ. Nitorina ohunkohun bukàtà, bukàtà kekere ti o ba ni fun awọn elo emi igbadun, kà gé. Nigbana ko ni ona miiran ni yiyan ju lati jowo fun mi. " O ti wa ni sọ ninu awọn ti Bhagavad-Gita, ati, Śrīmad-Bhāgavatam. Yasyāham anughṛnāmi hariṣye tad-dhanaṁ sanaiḥ. Olorun so wipe "Bi Emi ba ṣe ẹnikan ni ojurere pataki, Maa si so di talaka. Emi o mu gbogbo àwọn ọna ti o fi nri igbadun kuro . " Ṣe o ye yin? O ti wa ni ako-le ninu Śrīmad-Bhāgavatam. Nitori nibi ninu aye asan yi gbogbo eniyan ni o gbiyanju láti ní ìdùnnú nipa pipa owo pupo, nipa owo, nipa iṣẹ, nipa ọna yi tabi ọna ôhun. Sugbon ni igba miran pataki Olorun a mu owo tabi iṣẹ rẹ làiyege. Se ẹ feran iru nkan bayi? (Erin) Ni ìgba na ko ni ona miiran ni yiyan ju lati jowo si Olorun. Ṣe o ye yin? Sugbon nigba kan, nigba ti a ba wa làiyege ninu igbiyanju iṣowo wa tabi igbiyanju owo pipa , a ma kábàámọ pe "Ah, Olorun se mi nìka to bẹẹ ti emi kò le ní ìgbẹkẹlé nínú eyi." Sugbon iyen jẹ ojurere Re, ojurere pataki. O yẹ ki o ye yin bayi.