YO/Prabhupada 0187 - E duro s'abe ina nigbogbo igba



Lecture on SB 2.8.7 -- Los Angeles, February 10, 1975

Aimokan yi sin lo lasiko wa yi. Nitorina fun ojo iwaju, Parīkṣit Mahārāja ti se'beere, pe " Bawo ni awon eda se wonu ara yi? Boya nkan to lofa tosele, tabi kosi nkan to fa?" Ama salaaye.. Ti oun to fa ba wan'be... gege bi eyan to ko aisan sara, lesekese loma ki aisan na. Lesekese loma wa. Sugbon nkan to fa niwipe, eti ko aisan yi s'ara. Gege na teba se jeje te gbiyanju lati ma ko awon aisan yi s'ara, ele jade kuro ninu ibimo sinu awon ara eda kekere tabi ijiya wanyi. Nitorina lase da awujo yi sile. Itumo awujo niwipe ema ri idi lati fi ni idagbasoke ninu eto emi. Gege bi orisirisi awon awujo ton wa. " Awon eye pelu iye kanna lon fo po." Gege na awujo wa leleyi. Talo ma wa sibi? Nitoripe awujo wa yi wa lati fun awon eyan ni ominiran... Awon eyan jiya gan nitori ile aye yi. Koseni to ni idunnu. Oto oro niyen. Sugbon nitoripe wani aimokan, gbogbo wan ro pe idunnu ni ibanuje tonni. Nkan ton pe ni maya niyen. Maya leleyi.

Yan maithunādi-gṛhamedhi-sukhaṁ hi tuccham (SB 7.9.45). Maya yi wa ninu iwa imo ako ati abo. wan rope imo ako ati abo yi da gan, sugbon lehin na orisirisi ibannuje lo wa n'be. Kosi iyato ti ibanuje yi ba je eyi toye wa tabi eyi ti o yewa. Nkankanna ni gbogbo awon ibanuje wanyi. gbogbo wa lamo. Nitorina, agbudo lo idunadura yi tio da basele lo to. Ati ni ara lati'le aye yi. Idi to fa wa n'be. Idi to wa niwipe gbogbo wa fe gbadun, awa o fe sise fun Krsna. Idi to wa niyen. Kṛṣṇa-bahirmukha hañā bhoga vāñchā kare. Awan sise fun Krsna. Ipo wa niyen, lati sise fun Krsna, sugbon nigbami agbudo ale rowipe: " kilode ti mase sise fun Krsna? Kilode ti ma sise fun Oluko mi? Mofe gbadun. Mofe gbadun." Sugbon igbadun yi wa ninu ise si Krsna, sugbon o fe gbadun laisi Krsna. Idi fun iwo lule re niyen. Pelu Krsna a le gbadun dada. Eti ri awon iworan na, bi Krsna sen jo pelu awon gopi, awon oluso maalu okurin ton sere, gbogbo wan gbadun. Igbadun gidi teni wa pelu Krsna. Sugbon laisi Krsna, teba fe gbadun. maya niyen.

Gege na maya wan'be ni gbogbo igba... Nitoripe afi t'okunkun ba wa kosi besele mo iwulo ina; nitorina ni Krsna se da okunkun yi sile, maya na, lati je ki gbogbo mo iwulo ina. Awon nkan meji lani. Laisi'na, awa o le mo iwulo okunkun, ... lais'okunkun, awa o le mo iwulp ina. Awon nkan meji yi wa legbegbe ara wan. Gege bi ina orun, ati ojiji, egbegbe ara wan lonwa. ele joko sinu iboji tabi ke bosinu orun. Bose wunyin niyen. Taba joko sinu okunkun, ibanuje ma wa ninu aye wa, taba bosinu ina,... Nitorina ni iwe mimo Veda se sofun wa, tamasi mā: " Ema joko sinu okunkun." Jyotir gama: " Ewa sinu ina." Egbe imoye Krsna yi gbiyanju lati mu awon eyan wa sinu ina lat'okunkun. Ema lo anfaani yi nilokulo. Bakana tabi keji eti wa sinu egbe wa yi. E lo dada. Ema pada sinu okunkun. E duro s'abe ina nigbogbo igba.

Ese pupo.