YO/Prabhupada 0374 - The Purport to Bhajahu Re Mana part one



Purport to Bhajahu Re Mana -- San Francisco, March 16, 1967

Bhajahū re mana śrī-nanda-nandana-abhaya-caraṇāravinda re. Bhaja, esin nitumo bhaja; hu, bawo ni; mana, okan. Akewi Govinda dasa, alakowe ati elesin Olorun, tin gbadura. On bere lowo okan re, nitoripe ore ati ota gbogbo wa l'okan wa je. Teyan bale fun okan re leeko nipa imoye Krsna, ile aye re ma ni ilosiwaju. Tiko bale fun okan re leeko, ipadanu ni ileaye re je. Nitorina Govinda dasa, elesin giga ti Olorun Krsna... Oruko re gan sofun wa, Govinda dasa. Govinda, Kṛṣṇa, ati dāsa itumo re je iranse. Iwa awon elesin leleyi. oruko wan ni oro dasa yi pelu, itumo re ni iranse. Govinda dasa tin gbadura, " Okan mi, daakun, gbiyanju lati sadura si omo Nanda, toje abhaya-carana, ti idaabo re daju. Kosejo iberu." Abhaya. Itumo Abhaya niwipe kosi'beru, ati carana, itumo carana ni ese re bi ododo. O sin fun okan re ni imoran, okan mi, daakun, bere sini s'adura si Olorun tio kin beru, omo Nanda." Bhajahū re mana śrī-nanda-nandana. Itunmo Nanda-nandana ni omo Nanda Mahārāja, Kṛṣṇa. Ese re toda bi ododo, kosi iberu kankan nibe. Govinda dasa sin bere lowo okan re, "Daa kun mofe ko sise fun Krsna." Awon nkan iyoku...

o sowipe durlabha manava-janama. Nkan to won lati ri nitumo Durlabha Manava-janma nitumo ile aye eda yi. Lehin iyika to po gan loma wa. Wan si ti funwa laaye lati ni imoye Krsna k'abaale jade kuro ninu iyika ibimo ati ku yi. Nitorina oti fun wa ni imoran wipe, ile aye eda yi, se pataki gan, durlabha. Pelu isoro nla nitumo Duh, nkan tale ri lo nitumo labha. awon eyan tio logbon o mo bi ile aye eda yi se wa pataki. Wan lo asiko wan nilokulo bi awon eranko. Nkan tose pataki gan leleyi pe on fun okan re leeko pe " Ogbudo saadura si Olorun Krsna." Durlabha mānava-janama sat-saṅge. laarin awon eyan to daa lale ni ikeko yi, sat-sanga. itumo sat-sanga niwipe, a wa ninu ise olorun, pelu gbogbo okan. sat lon pe wan. Satāṁ prasaṅgāt. Laisi asepo pelu awon elesin, kosi basele fun okan wa leeko. awon eto yoga wanyi o le ranwa lowo tabi ke ma sasaro. Eyan gbudo ni asepo pelu awon elesin bibeko kolese se. Nitorina lase da egbe imoye Krsna yi, ki awon eyan bale gba egbe yi laaye. Govinda dasa, akewi at'elesin yi sin fun wa ni imoran, durlabha mānava-janama sat-saṅge: " Eyin ti ni ara eda yi to da gan. Nisin eni asepo pelu awon elesinke si gbokan le Olorun Krsna tio n'iberu kankan." On beere lowo okan re. Lehin na on salaaye nipa awon ibanuje aye yi. Kini yen? Śīta ātapa bāta bariṣaṇa e dina jāminī jāgi re. Igba otutu nitumo Śīta. Igba oru nitumo Ātapa, tio orun ban ran gan. Śīta ātapa bāta, otutu, bariṣaṇa, ojo to po. Awon isoro wanyi si wa. Nigbami otutu to po gan ma wa. Nigbami oru loma wa. Nigbami ojo loma ro. Nigbami nkan bayi, tabi keji. gege na o sowipe, śīta ātapa bāta bariṣaṇa e dina jāminī jāgi re. Lat'aro d'aale awon eyan sise lai ronu, nipa otutum oru, omi ojo, tabi asiko aale, wan losi ile gbigbe, wan lo s'abe omi - gbogbo ibi lon wa ton sise. Śīta ātapa bāta bariṣaṇa e dina jāminī jāgi re. Ise ale wa, ati orisirisi nkan na. Gege na o sowipe,

śīta ātapa bāta bariṣaṇa
e dina jāminī jāgi re
biphale sevinu kṛpaṇa durajana
capala sukha-laba lāgi' re

" Ise tole nigbogbo eleyi je, kini mo ti se? Moti sise fun awon eyan tio le ranmilowo ninu imoye Krsna mi. Kilode timon sise fun wan?" Capala sukha-laba lāgi' re: Capala, idunnu tio daju. Mon rowipe ti omo mi ba rerin inu mi a dun. Mon rowipe, ti inu iyawo mi ba dun, inu mi na a dun. Sugbon gbogbo idunnu yi tabi erin wanyi, fun igba die lonwa." Eyan gbudo mobe. Awon akewi to po gan ti korin nipa eto yi..., okan wa dabi ile-gbigbe, sugbon on rin kakiri lehin omi odo. Ninu ile-gbigbi, teba mu omi odo wa, lehin na lele f'omi kun be. Ijeere wo lole watebafi omi die sibe? gege bayi, ni okan wa, rin kakiri lati wa idunnu. ninu idunnu igba die yi pelu ebi, awujo wa, gbogbo e dabi omi kekere. awon ton je alakowe, awon ton ti waadi gbogbo nkan ton sele yi, wan le ni mowipe " Idunnu kekere o le funmi ni idunnu to da." Lehin na o sowipe, kamala-dala-jala, jīvana talamala.

Ododo nitumo Kamala-dala-jala. Se ti ri awon ododo lori adagun. nigbogbo igba lon wa ninu omi. Omi sile kun nu adagun yi nigba gbogbo. Gege na aye yi kun fun alebu, alebu to po. O le paari l'eyikeyi asiko. Awon peere to po gan wa. awon eyan ma wo sugbon wan o kin riran. Nkan toje iyanu gan. Lojo jumo wan riwipe alebu po l'aye yi, wan sin ri awon elomi na ton wa ninu alebu yi. Sugbon o ronu wipe " Kosi nkankan to ma sele." Bose ri iyen.