YO/Prabhupada 0410 - Our Friends, They Have Already Begun Translating



Cornerstone Laying -- Bombay, January 23, 1975

dharma-kṣetra na ni Kurukṣetra je. Ninu awon Veda wan salaaye wipe, kurukṣetre dharmam ācaret: " Eyan gbodo losi Kuruksetra lati se awon ebo t'elesin." Nitorina lose je dharma-ksetra lati aye atijo. Kilode teyin fe ka se isotunmo pe " Itunmo Kurusetra yi ni ara wa, dharmaksetra, ara wa"? Kilode? Kilode tefe tan awon eyan je? E ma tan awoneyan je mo. Kurukṣetra si wa nibe. Ibi idaduro oko Kurukṣetra, gbogbo e si wa n'be. E gbiyanjulati ni oye nipa Bhagavad-gita, ki ile aye yi ba leni ilosiwaju, ke pin oro yi si gbogbo agbaye. Inu yin a dun, gbogbo agbaye ma ni idunnu na. Niotooro, arugbo nimi. Moti le odun agorin. Aye mi ti tan. Sugbon mofe ki awon olugbe India to daju pelu awon ilu imi... awon ilu wanyi tin ranwa lowo gan. Bibeko, kosi bi mosefe ni ilosiwaju ni asiko kekere yi, ninu odun meje si mejo, lati sewaasu egbe yi lori gbogbo agbaye. Beena mosi fe ki awon olugbe India, nipataki awon okurin, alakowe okurin kon ranwa lowo. E wa. E gbe pelu wa. E ka Bhagavad-gita. Aw o ni nkankan tafe daale. Kosi nkankan lati da sile. Kila wa fe daale? Koseni kankan ninu wa tio ni asise kankan. Ounkoun toje, e jeka keeko kai fi sinu aye wa, kasi pin kaakiri gbogbo agbaye. Ise apinfunni wa niyen. Beena ooni je ojo tose pataki gan. Pelu isoro to po awa ti ni ase nisin. Nisin e dakun e ranwa lowo, besele ranwa lowo si pelu prāṇair arthair dhiyā vācā, nkan merin: pelu aye yin, pelu oro enu, pelu owo... Prāṇair arthair dhiyā vācā śreya-ācaraṇaṁ sadā. Ise apinfunni ile aye eda leleyi. ounkoun teba ni.. konsepe "nitoripe talaka nimi mio le ran yin lowo." Rara. Eyin si l'emi. E fun egbe yi laaye yin, iyen na da gan. Teyin o ba le funwa laaye yin, e fun wa lowo. Sugbon teyin o ba le funwa lowo nitoripe eyin o ni, e funwa l'ogbon. teyin o ba logbon e funwa l'oro enu yin. Beena ele fun egbe yi ni iranlowo, lati fun awon eyan ni rianlowo, fun India ati n'ita India. Ibeere mi leleyi. E wa. ekādaśī l'oni je. Asin gbaawe, sugbon a ma pin prasadam die na. Beena kon sejo prasadam ejo ise pataki tanse nisin basele pin egbe imoye Olorun yi. Bibeko, kosi besefe ni idunnu. Imoye ile aye yi nikan, gṛha-kṣetra... Ato gṛha-kṣetra-sutāpta-vittair janasya moho 'yam ahaṁ mameti (SB 5.5.8). Ife imo ako ati abo nitunmo ile aye yi. Awon obirin sa tele awon okurin, awon okurin sa tele awon obirin. Puṁsaḥ striyā mithunī-bhavam etaṁ tayor mithaḥ. lesekese tonba wa papo, won ma ni lati gba gṛha, ile: gṛha-kṣetra, gṛha-kṣetra-suta, omode, ore, owo; ati moho, itanra eni, ahaṁ mameti (SB 5.5.8), "temi ni, emi ni moni." Awujo ile aye yi. Sugbon ile aye yi o wa fun iru nkan bayi. Nāyaṁ deho deha-bhājāṁ nṛloke kaṣṭān kāmān arhate viḍ-bhujāṁ ye (SB 5.5.1). Beena e keeko. Awa ni iwe to po. Kosi isoro kankan lati ka won iwe wanyi. Ati se isotunmo ni ede geesi. Gbogbo eyan lomo ede geesi. Lehin igba die asi ma ko awon iyoku ni ede Hindi, Gujurati ati awon ede imi. Awon ore wa tin se isotunmo, koni si ejo aini ninu eto imoye. E dakun e wa, e joko lojokan ninu ose ke ka awon iwe wanyi, e gbiyanju lati ni oye nipa imoye aye yi, kesi pin lori gbogbo agbaye. Ise apinfunni ti Bhāratavarṣa.

bhārata-bhūmite manuṣya-janma haila yāra
janma sārthaka kari' kara para-upakāra
(CC Adi 9.41)

Egbe paropakara leleyi, lati sise ore fun awon eyan ema se bi awon ologbo tabi aja, ke ma na owo lati gbadun. Ile aye eda ko niyen. Fun paropakara ni ile aye yi wa fun. Awon eyan wa ninu aimokan, lai ni imoye Olorun kankan, laimo idi fun aye yi. won sise bi ologbo at'aja at'elede. Won gbodo eeko. Ile aye eda yi wan fun eko kiko. beena ile-ajosin wa yi wa lati ko awon awujo eda lati d'eyan gidi kon bale ni ilosiwaju ninu aye won.

Ese pupo. Hare Krsna.