YO/Prabhupada 0421 - Ten Offenses to Avoid while Chanting the Maha-mantra - 1 to 5



Lecture & Initiation -- Seattle, October 20, 1968

Madhudviṣa: Śrīla Prabhupāda? Se kin ka awon aimase mewa?

Prabhupāda: Beeni.

Madhudviṣa: O wa nibi.

Prabhupada: Se ti ri. Tesiwaju pelu kika iwe na. Beeni, kaa fun wa.

Madhudviṣa: "Awon aimase mewa toye ka paati ninu eto kiko maha-mantra.

Ikini: So isokuso nipa awon olufokansi Olorun.."

Prabhupada: Nisin je ko ye e. Awa o gbodo so isokuso nipa awon olufokansi. Kesejo nipa orile-ede toti wa. Gege Oluwa Jesu Kristi, olufokansi pataki loje. pelu Muhammad gan, olufokansi na loje. Kon sepe ka me rowipe, olufokansin nimi awon kan o je be. Ema ronu bayi. Enikeni ton sewaasu nipa awon ogo Olorun, olufokansi loje. Awa o gbodo so isokuso nipa won. E se jeje. Lehin na?

Madhudviṣa: "Ikeji: Ka ma rowipe Olorun ati awon orisa wa lori ipo kanna, tabi pe Olorun kan soso ko lowa."

Prabhupada: Beeni. Gege bi gbogbo iranu to wa nisin, won sowipe awon orisa... Ni otooro, eyin o ni nkankan se pelu awon orisa. Ninu esin Veda aimoye awon orisa to wa. Nisin awon eyan ma sowipe teba s'aadura si Krsna tabi Siva tabi Kali pe nkankan loje. Iranu niyen. Eyin o gbodo fi awon orisa pelu Olorun lori ipo kanna. Koseni to gaju Olorun lo. Koseni to j'egbe si Olorun. Beena eto pe won je egbe agbodo paati. Lehin na?

Madhudviṣa: " Iketa: Ka ma tele awon ofin oluko waa ninu eto emi."

Prabhupada: Beeni. Agbodo mu awon ase Oluko wa gege bi aye at'emi wa. Lehin na gbogbo nkan ma daju. Lehin na?

Madhudviṣa: " Ikerin: Ka ma mu oro awon iwe mimo Veda mi ere."

Prabhupada: Beeni. Eyin o gbodo mu awon oro iwe mimo wanyi bi ere. Asise niyen je. Lehin na?

Madhudvisa: Ikaarun: Ka ma fun isotunmo tioye si oruko Olorun."

Prabhupada: Beeni. Nisin gege bi awa sen korin Hare Krsna, bi ojo to koja nigbati omo okurin kan sowipe: "Ami." Kon sen ami. Krsna Awa n'korin "Krsna," aan daruko Krsna. Agbara Krsna nitumo Hare, asin gbadura pe, " E dakun e fimi sinu ise yi." Hare Krsna leleyi. Kosi isotunmo imi ju bayi lo. Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare, Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare. Adura kan soso to wa niwipe, " O agbara Olorun, O Olorun Krsna, Olorun Rama, E fimi sinu ise yi." Otan. Kosi isotunmo imi.