YO/Prabhupada 0426 - One Who is Learned, He Does Not Lament Either for the Living or for the Dead Body



Lecture on BG 2.11 -- Edinburgh, July 16, 1972

Prabhupāda: Isotunmo.

Pradyumna: Isotunmo: "Olorun to dara sowipe: On soro bi alakowe sugbon, on sukun fun nkan tio ye ko sukun fun Awon ton gbon o kin sukun fun awon ton ti ku tabi awon ton wa laaye (BG 2.11)

Prabhupada: "Olorun to dara sowipe: On soro bi alakowe sugbon, on sukun fun nkan tio ye ko sukun fun. Awon ton gbon o kin sukun fun awon ton ti ku tabi awon ton wa laaye." Imoye Krsna yi, egbe imoye Krsna, wa lati ko awon eyan lati ni oye nipa ipo eda. Nibi wan sowipe eni to keeko, Ko kin sukun fun eni to wa laaye tabi eni toti ku. (segbe:) E yo wan kuro niwaju. E yo wan kuro, e mu lo seyin. Awujo aye isin o mo ju ara eda lo: " Ara mi nimi." " Omo-ilu India nimi," " Omo ilu America nimi" "Hindu nimi," " Musluman nimi", "Mo dudu," " Mo funfun," ati bayi bayi lo lori eto ara bayi ni gbogbo awujo wanyi sise. Botilejepe wanti ko awon ile-eko giga sugbon kosi ibi ton ko awon eyan lati mo " Tani mi." Dipo wan fun won leeko to ma yi won sodi pe " Ilu yi lon bi e si. E gbodo niifarasi ilu yi, egbodo sise fun ilu yi." tabi kon awon eyan nipa orile-ede won. sugbon koseni ton ko won nipa eniton je.

Ipo kankan loje pelu Arjuna, Arjuna lori ile-ogun Kuruksetra. Ogun kan si wa. Itan akole ti orile-ede India, Mahabharata. Wan pe ni Mahabharata. Lati Mahabharata ni Bhagavad-gita ti wa. India to gaju nitum Mahabhrata. Beena ninu itan akole India, o ni ija kan tosele laarin awon omoebi kanna, awon Pandavas ati Kurus. Awon Pandavas atii Kuru wan ninu ebu kanna, ton pe ni Ijoba Kuru, NIgbana bi odun 5,000 seyin ijoba Kuru yi lo ni idari lori gbogbo agbaye. Nisin nkan t'awa pe ni Bharata-varsa, iwonba die loje. Teletele gbogbo agbaye yi lon pe ni Bharata-varsa. K'eleyi tosele aimoye odun seyin, Ilāvṛta-varṣa ni oruko agbaye yi. Sugbon o ni oba kan to lagbara gan ton pe ni Bharata. pelu oruko re lon se so agbaye yi ni Bharata-varsa. Sugbon die die, awon eyan bere sini pin si we we. gege bi awa sen jerisi ni India, odun 20, tabi odun 25 seyin kosi Pakistan. sugbon nisin, Pakistan ti jade. tele tele kosi iyato kankan lori agbaye yi. Ikan soso ni agbaye yi je, Oba kan soso lon ni, asa kan lon ni. Asa Veda loje, oba kan loni. Bi mo se so tele awon ijoba Kuru loni ijiba lori gbogbo agbaye. Ijoba oba loje. Beena o ni ogun tosele laarin awon ara ebi kanna, ogun yi ni koko oro ninu Bhagavad-gita. Lori ile-ogun lon so iwe Bhagavad-gita. Lori ile ogun, asiko die lani. Nigbati awon apa mejeji ton fe ja pade lon soro Bhagavad-gita lehin igbati Arjuna ri apa keji, gbogbo won je ara ebi re nitoripe ogun laarin awon ara ebi kanna, beena ibanuje si mu lokan. Pel'aanu o sofun Krsna, "Krsna mi, mio fe ja. Jeki awon aburo mi gba ijoba kon gbadun, mio le pa won ninu ogun yi." Koko oro Bhagavad-gita leleyi. Sugbon Krsna si sofun pe " Ksatriya loje. Lati jagun ni ise re. Kilode to fe fi ise re sile?"