YO/Prabhupada 0438 - Cow Dung Dried and Burned into Ashes is used as Toothpowder



Lecture on BG 2.8-12 -- Los Angeles, November 27, 1968

Ninu Ayur-veda, tonba ti fi igbe maalu yi s'orun tan wansi fis'ina, lehin na eruko re lon lo fi fo eyin. Eruko na sin pa kokoro. Beena, awon nkan to po wa ninu Veda to dabi nkan idamu, sugbon idamu ko loje. Nkan ton ti jerisi ni gbogbo won. Gege bi baba ton sofun omo re, pe " Omo mi, gba ounje yi.O da gan." ti omo na ba gba, to ni igbagbo ninu babare, oludari. Baba na sowipe.. O daju pe " baba mi o ni funmi l'oró . Nitorina o le gba lai yeewo, lai sawaadi ninu ounje na, boya o mo tabi ko mo. Agbodo ni iru igbagbo bayi. Eyin ma losi ile-isinmi nitoripe ijoba ti se iyanda fun. Egbodo nigbagbo pe ounje teyin je nibe daju osi wa ni mimo, kode si kokoro ninu re,.. Sugbon bawo lese mo? Oludari. Nitoripe ijoba ti jerisi ile-isinmi na, nitorina le se nigbagbo. Beena itumo śabda-pramāṇa niwipe lesekese ti ijerisi ba wa, ninu awon iwe Veda, " Bayi bayi lose je, oye ke gba bee. Otan. Lehin na imoye yi ma wa ni pipe, ntoripe eti gba awon nkna wanyi lat'orisun. Beena Krsna, Krsna ni Olorun agbaye. Ounkoun toba so, o da bee. gba bee. Arjuna sowipe, sarvam etad ṛtaṁ manye (BG 10.14). " Krsna mi, ounkoun teba so mo gba bee." Ofin wa niyen. kilode toye ka sewaadi, ti awon ijerisi ti wan'be lati awon oludari? lati din isoro wa ku, agbodo gba oun ti awon oludari ba so. Ilana Veda leleyi. Nitorina Veda ti salaaye wipe, tad vijñānārthaṁ sa gurum evābhigacchet (MU 1.2.12).