YO/Prabhupada 0553 - You Don't Require to go to Himalaya. You Just Remain in Los Angeles City



Lecture on BG 2.62-72 -- Los Angeles, December 19, 1968

Prabhupāda: Beena awon yogi ati awon ona iyoku, wonfe ni idarilori iye ara pel'agidi. " Mofe losi Himalaya. Mio ni ri obirin kankan to lewa nibe. Ma paa'ju mi de" Iwa agidi leleyi. Eyin o le ni idaari lori iye ara yin. Apeere to po gan wa. Kowulo lati losi Himalaya. Ejoko si ilu Los Angeles kesi lo oju yin lati ri Krsna, eyin ju awon eyan ton ti losi Himalaya lo. Eyin ma gbagbe gbogbo nkan to ku. Ilana wa niyen. Kowulo pe eyin fe ise yin sile. E fi eti yin fi gbo Bhagavad-gita boseje, eyin ma gbagbe gbogbo iranu wanyi. Eyin ma lo'ju lati ri bi Krsna se lewa to. Elo ahon yin lati fi je ounje Krsna Prasadama Efi ese yin fi rin wa si ile ajosin. Efi owo yin fi sise fun Krsna. Efi imu yin fi gboorun awon idodo ton ti fun Krsna.. Lehin na nibo ni iye ara yin ma lo? Won ti mu lati'bikibi. O daju pe oma ni ilosiwaju. Ema f'agidi fi ni idari lori ara yin, ma woo, ma see baayi. Rara. Egbodo paaro nkan teyin se. Nkan to ma ranyin lowo niyen. Tesiwaju.

Tamala Krsna: Iye. " Ati salaaye tele wipe eyan le f'agidi fi ni idari lori iye ara yi, sugbon afi teyin ba lo iye ara yin ninu ise Oluwa, o daju pe eyin ma wolule. Botilejepe eni to wa ninu imoye Krsna yi le wa lori ipo iye ara, looto nitoripe oni imoye Krsna, koni ifarasi tabi itara lati awon ise iye ara. Eyan to wa ninu imoye Krsna ni'telorun pelu Krsna nika o tan, kosi nkankan imi. Nitorina eyan bay ti koja gbogbo awon idimu ati itara aye yi. Ti Krsna bafe, olufokansi na le se ounkoun tojepe kole se teletele, ti Krsna o ba fe koni se nkan toma se teletele fun igbadun ara re. Nitorina o le sise tabi ko ma sise nitoripe gbogbo e wa labe ase Krsna. Ore-ofe Oluwa ni imoye bayi je ti awon olufokansi le ni botilejee won wa lori ipo aye yi." 65: Fun awon eyan ton wa pipe, awon isoro meta aye yi o le fun won ni damu mo. Ninu ipo idunnu bayi, ogbon eni na ma daju." 66: " Eni tio ba ni imoye to gaju kole ni ifokan bale tabi ogbon to daju, beena kole si alafia kankan, bawo ni idunnu sefe wa tio ba ni alaafia?" 67...

Prabhupada: Gbogbo eyan ninu ile aye yi sin sa tele alaafia, sugbon won o fe ni idari lori iye ara won. Kolese se. Gege bi teyin bani aisan lara, ti dokita sowipe " E mu ogun yi, e je ounje bayi," sugbon teyin o ba le se ten je nkan tefe, ten se awon nkan t'ologun so kema se. bawo lara yin se fe ya? Beena, afe ni iwosan ninu idamu ile aye yi, afe lowo at'alafia, , sugbon awa o fe ni idari lori iye ara wa. Awa o mo lati ni idari lori iye ara wa. Awa o mo ona yoga to daju lati ni idari lori iye ara wa. Beena kosi basele ni alafia kankan. Kutaḥ śāntir ayuktasya. Oro dédé na wa ninu Bhagavad-gita. Teyin o ba nise ninu imoye Krsna, kosi besef ni alafia. Ele gbiyanju, sugbon kolese se.