YO/Prabhupada 0568 - We are Simply Depending on Donation. If You Like, You Can Pay



Press Interview -- December 30, 1968, Los Angeles

Prabhupāda: Beena pelu gbogbo awon irori yi nimo wa sibi, mode rowipe mole ni aaseyori, beeni.

Akoroyin: Ko dabi eyan to po fun asiko teti wa. Awon akeeko melo lo wa... (sin) e dakun.

Prabhupada: kosi wahala.

Akoroyin: Awonn akeeko melo lowa..se ogorun nikan?

Prabhupada: won ju ogorun die.

Hayagriva: awon tonti gba itebomi leleyi ton tele awon ofin daju djau. Looto awon ton wa si ile ajosin wa po ju bayi lo, awon eyan sin paarapo pelu wa. Akoroyin Ile ajosin melo leni?

Prabhupada: Ile ajosin metala. Metala.

Akoroyin: Metala?

Prabhupada: Ikan ni Los Angeles, ikan ni San Francisco, ikan ni New York, ikan Santa fe, ikan Buffalo, ikan Boston, Ikan Montreal, ikan Vancouver, ati Seattle, Colunbus ati London, Hamburg, bayi.. Hawaii.

Akoroyin: Oda ju pe awon eyan to wa ninu ile ajosin metala yi ju ogorun lo.

Prabhupada: Beeni> Beeni, o koja Ogorun.

Hayagriva: Mio mo.

Prabhupada: Beeni, moni won ju ogorun lo.

Hayagriva: beeni, nitoripe iyen ma je eyan mewa ninu ile ajosin kan.

Prabhupada: Beeni. Nibi awa ni ju eyan ogun ninu ile ajosin yi.

Akoroyin: bi ogun nibi. Nibo leyin tin r'owo lati se itejade iwe iroyin teni?

Prabhupada: Oluwa, Oluwa lon fi ranse. ( Erin)

Akoroyin: Beeni, o daju bee, sugbon Oluwa ole fowo ranse siyin. Mo kan bere. Mo gbodo sowipe..

Prabhupada: Oluwa asi sofun yi at'eyin ma sowo. Otan.

Akoroyin: Mo gbodo sowipe idaaun yi si ibeere yi ko daju.

Prabhupada: (erin) Beeni. Mo wa sibi .. o ma yeyi lenu. Mowa sibi pelu dollar meje pere, sugbon gbogbo owo tan na ninu egbe yi ko keere ju, dollar ẹgbẹ́ẹdọ́gbọ̀n l'osu. O kere ju niyen.

Akoroyin: Iyen bosi ọkẹ́ kán lona meta l'odun kan. Se won fun yin lofe?

Prabhupada: ẹgbẹ́ẹdọ́gbọ̀n keere gan. Morope o ju bayi lo.

Hayagriva: mio tie mo.

Prabhupada: Beeni. Nitoripe awa n'sonwo ni ile ajosin yin, a'san dollar ogorun merin l'osu fun owo ile. Beena nigbogbo ibi tawa eye tan san niyen.

Akoroyin: Se awon eyan tio kin se akeeko tabi olufokansi le wa si aajo yin.

Prabhupada: beeni. Rara, awa fe ki gbogbo awon eyan wa, " Ewa, e korin. E jeun Prasadam." Aw ati saadura si prasadam yi. E korin, e jo, e gbo oro Bhagavad-gita ke je prasadaa, lehin na e pada sile.

Akoroyin: Niooro imi, tonba fe fun yin nikan, wonle fun yin.

Prabhupada: Beeni. Asin bere fun iranlowo pe " Lori awon ebun yi lawan gbe. teba fe ele funwa." Awon eyan man funwa. Beeni.

Akoroyin: Beeni. Se biwe iroyin yi sen jade niyen?

Prabhupada: Iwe iroyin na, awa man mulo soja lati ta. Awon eyan man ra. Beena kosi owo gidi kankan ton wole.

Akoroyin: Oh, kosi.

Prabhupada: Rara. Awa kon gbokanle Krsna. Sugbon pelu ore ofe Krsna, egbe wa sin posi. Kole dinku.

Akoroyin: O da bee. Mo kan fe mo nitoripe iwe iroyin to da gan leleyi.

Prabhupada: Beena ele ranwa lowo.

Akoroyin: E dakun?

Prabhupada: e gbiyanju lati funwa ni iranlowo. America yin, awon olowo po gan. Ti awon bayi ba wa ranwa lowo, ikan tabi meji, ale ni ilosiwaju to da gan. Awa o lowo kankan. Asin tiraka gan. Seti ri bayi? Omo-okurin yin, alamodaju loje ninu ile iwe eko giga Ohio. Beena ounkoun toban gba osin na funwa. Beena, gbogbo awon omo okurin teyin ri yi, ounkoun ton ba gba won na. Sugbon ko to, set ri bayi? Agbogo polowo. Awa o le te awon iwe yi jade. Afe te iwe tokoja ẹgbàárùn lona marun losun kan, sugbon ko s'owo kankan. Awa sin te bi ẹgbẹ́ẹdọ́gbọ̀n losu

Akoroyin: talon fon fere nibe? ( won fon conchshell)