YO/Prabhupada 0586 - Actually this Acceptance of Body Does Not Mean I Die



Lecture on BG 2.20 -- Hyderabad, November 25, 1972

Nitorina taba s'eto ninu aye yi, ara eda yi, ara eda yi ma paari, oma ku, sugbon eto timo ni yi ma wa ninu okan mi. nitoripe osi wa ninu okan mi, lati le paari ife okan yi mo gbodo gba ara eda imi. Ofin ipaaro ara fun emi leleyi. Emi yi as gba ara eda imi pelu eto yi lokan. pelu emi yi, emi to gaju, Eledumare wa pelu e. Sarvasya cāhaṁ hṛdi sanniviṣṭo mattaḥ smṛtir jñānam apohanaṁ ca (BG 15.15). Beena, emi to gaju yi, Eledumara, lon fun logbon. " Nisin ofe s'eto yi. Nisin o ti ni ara lati fise. Beena ale riwipe enikan je oni sayensi giga tabi atokose to da. itumo re niwipe laye re to kehin atokose loje, osin seto bayi, ninu aye yi na, ife okan re yi ti tan. Asi sewaadi kan, lehin na adi olokiki, eyan pataki. Nitoripe awon karmi, nkan meta lonfe: lābha-pūjā-pratiṣṭhā. Wanfe ijeere aye yi, ati ki awon eyan teriba fun won, lābha-pūjā-pratiṣṭhā ati aye to dogba. Ile aye yi. Beena leyokan sikeji, awa sin gbiyanju lati ni ijeere aye yi die, awon igberaga, ati oruko rere. nitorina lasen gba ara eda orisiris. Nkan ton sele niyen. Looto pe mo gba ara eda yi konsepe moti ku. Mo wa nibe. Ninu ara teyin o le foju ri. Mowa nibe. Na jāyate na mriyate. Nitorina kosejo pe eyin ni ibimo tabi iku. Iyika ara eda yi leleyi. Vāsāṁsi jīrṇāni yathā vihāya (BG 2.22), base ma salaye ninu ese-iwe to kan:

vāsāṁsi jīrṇāni yathā vihāya
navāni gṛhṇāti naro 'parāṇi
tathā śarīrāṇi vihāya jīrṇāny
anyāni saṁyāti navāni dehī
(BG 2.22)

Dehī, eda yi, o kan paaro aso re. bi aso ni ara eda yi se ri. gege base soro tele,awon eyan sowipe emi wa o le ni irisi. Bawo niyen se je? Ti ara eda yi ba dabi aso funmi, bawo lose jewipe emi o ni irisi kankan? bawo laso na se ni irisi? Aso tabi ewu mi ni irisi yi nitoripe ara mi ni irisi na. Moni owo meji. Nitorina aso mi, ewu mi na sini owo meji. Aso mi ni apa meji. Beena ti aso na, ara eda yi bonse juwe re ninu Bhagavad-gita - vāsāṁsi jīrṇāni yathā vihāya (BG 2.22) - beena toba je aso, mogbodo ni irisi temi. Bibeeko bawo lonse se aso na? Ipaari oro to daju leleyi asi rorun lati ni oye re. Afi temi ba ni ara eda mi bawo ni aso me seni irisi re? Kini idaaun na? Seni kan fe daaun? Bi eda talakoko o se lese at'owo? Gege bi eyin sen losi odo aronso. Asi won owo yin, ese yin, aya yin. Lehin won ma se aso ati ewu yin. Beena, teyin ba ni aso teba fe, oye ke mo wipe moni ara, ara mimo. Koseni tole jiyan. lehin gbogbo ijiyan wa, oyeka gba oro Krsna. Nitoripe oun l'Olori.