YO/Prabhupada 0599 - Krsna Consciousness is not Easy. You cannot have it Unless You Surrender Yourself



Lecture on BG 2.23 -- Hyderabad, November 27, 1972

beena nibo wansi salaye ninu Brahma-saṁhitā: vedeṣu durlabham adurlabham ātma-bhaktau (BS 5.33). Vedeṣu. Teyin ba ka awon Veda, botilejepe opin to gaju lati ka awon Veda ni lati mo Krsna, sugbon teyin ba ka awon Veda pel'ogbon ara yin, lehin na O ma jina si yin. Vedeṣu durlabham adurlabham ātma-bhaktau (Bs. 5.33). Sugbon tryin ba sumo olufokansi Oluwa, o le salaye fun yin. O le salaye funyin. Mahīyasāṁ pāda-rajo-'bhiṣekaṁ niṣkiñcanānāṁ na vṛṇīta yāvat, naiṣāṁ matis tāvad urukramāṅghrim (SB 5.7.32). Prahlāda Mahārāja sowipe " Eyin o le ni imoye Krsna yi..." Naiṣāṁ matis tāvad urukramāṅghrim. Imoye Kṛṣṇa o fibe rorun. Kosi besele rigba teyin o ba teriba. Niṣkiñcanānām, mahīyasāṁ pāda-rajo-'bhiṣekaṁ niṣkiñcanānāṁ na vṛṇīta yāvat. Teyin o ba gba eruku ton jade lati ese awon olufokansin, niṣkiñcanānām, tio ni nkankan se pelu ile aye yi - to kan gbokan re lori ise Oluwa - afi teyin ba parapo pelu iru eyan bayi, kosi besele ni imoye Krsna. Awon oro sastra niyen.

Beena Krsna ni otito to gaju, eyan loje. Sugbon kosi basele ni oye nipa re afi t'awa ba lo ba kṛṣṇa-bhakta. Nitorina lati ni oye nipa Kṛṣṇa, Kṛṣṇa ti sokale wa bi bhakta, Oluwa Caitanya Mahāprabhu. Śrī-kṛṣṇa-caitanya prabhu nityānanda śrī-advaita gadādhara śrīvāsādi-gaura-bhakta-vṛnda. Beena agbodo ni oye nipa Krsna lati Oluwa Caitanya. Nitoripe Krsna ti wa fun ara re... kṛṣṇāya kṛṣṇa-caitanya-nāmne. Nigbati Rūpa Gosvāmī pade Caitanya Mahāprabhu leleekeji. Nigbato pade re laalakoko, alakoso ofin ninu ijoba Nawab Hussein Shah loje. Lehin na, lehin ipade yi, Caitanya Mahāprabhu si fe kon sise fun ise apinfunni to muwa. Beena won si fiposile ninu ise ijoba ton se, won parapo pelu Caitanya Mahaprabhu lati pin egbe imoye Krsna yi. Nitorina nigbati Rupa Gosvami pade Caitanya Mahaprabhu ni Allahabad, Prayaga, ese iwe talakoko to sajo ninu eto yi, o sowipe, namo mahā-vadānyāya kṛṣṇa-prema-pradāya te: (CC Madhya 19,53) " Oluwa mi, eyin l'eda to l'aanu ju ni aye yi." Kilode? " Nitoripe Eyin sin pin kṛṣṇa-prema. Awon eyan o le ni oye nipa Krsna, kama wa soro nipa kṛṣṇa-prema. Sugbon eyin pin kṛṣṇa-prema, fun gbogbo awon eyan." Namo mahā-vadān... "Nitorina eyin l'eda to laanu ju." Namo mahā-vadānyāya. Eni ton sise ore ofe, ton se sara funa won eyan nitumo Vadānya.