YO/Prabhupada 0603 - This Mrdanga will go Home to Home



Lecture on SB 1.16.8 -- Los Angeles, January 5, 1974

Lati ri bi awon eda aye yi sen huwa elese, ise Yamarāja niyen, beena asi funwa ni ara eda toye. Karmaṇā daiva-netreṇa (SB 3.31.1). Gbogbo wa leyin igba taba ku, wan ma dajo fun wa. Looto teyin ba mu ona imoye Krsna yi nipataki, lehin na lesekese l'ona yi ma je fun yin. Lesekese lema pada si ile, si odo metalokan. Koni si ibeere pe wan dajo fun yin. Fun awon omo-odaran ni idajo yi wan fun, awon asiwere tio ni imoye Krsna. Sugbon teyin be ni imoye Krsna, teyin o batie le paari ise yi ninu aye tewa yi, teyin ba tie subu sile, beena eyin ma r'aye imi lati pada ninu ara eda eyan yi, lati bere nibi teyin ti paari, ati tun bere latibi teti subu.

Nitorina svalpam apy asya dharmasya trāyate mahato bhayāt. Teyin ba mu imoye Krsna yi dada, te gbiyanju lati mu ise na ni pataki, itumo re niwipe ke tele awon ofin na, ke korin Hare Krsna. Otan. Awon nkan marun. aini imo ako ati abo laise igbeyawo, aimase eto tete, aima jeran... Awa o sowipe kema ni imo ak ati abo, sugbon imo ako ati abo pelu eni tio kin se iyawo tabi oko yi iwa ese niyen. Ese to gaju. Sugbon awon asiwere wanyi, won se lateni kan si keji, alateni kan sikeji... Itanraeni maya niyen. Sugbon teyin ba paraapo pelu Krsna... Mām eva ye prapadyante māyām etāṁ taranti te (BG 7.14). Teyin ba mu ese Krsna dani dada, lehin na eyin oo ni subu. Sugbon teyin ban se igberaga brahmacari eke, grhastha eke, tabi sannyasi eke, daju pe eyin a wolule. Awa ti jerisi. Lehin na eyin ma wolule. Krsna o le fi aaye gba awon olufokansin eke. Māyā lagbara gan. Lesekese dimu: " Kilode tose wa sibi? Kilode teyin se wa sinu egbe yi." Ise Yamaraja leleyi. Sugbon teyin ba duro sinuu imoye Krsna, Yamaraja o le fowokan yin. Iku yin ti tan lati ibi teyin ti bere imoye Krsna yin. Iku re ti tan. Koseni tofe ku. Oto oro niyen. Eyin le sowipe, mole sowipe, " Rara, mio beru iku." Iwa were imi niyen. Gbogbo eyan lon beru iku, koseni tofe ku. Oto oro niyen. Sugbon teyin ba mu eto yi ni pataki pe " Mio fe fi ipaari si eto iku yi," lehin na imoye Krsna niyen.

Nitorina wonti funwa ni itosona, aho nṛ-loke pīyeta hari-līlāmṛtaṁ vacaḥ. " O ile aye eda, eyin tini ara eda yi, E tesiwaju ke ma mu adun krsna-katha yi." Wanti salaaye nibi. Aho nṛ-loke. Nipataki wanti salaaye ninu nṛ-loke, awujo eda. Fun awon aja-loke tabi ologbo-loke ko lowa fun. Kosi bonsele se. Won o ni agbara na. Nitorina lonsen pe ni: nṛ-loke. Nāyaṁ deho deha-bhājāṁ nṛ-loke. Ese iwe imi niyen ninu Apa karun: nāyaṁ deho deha-bhājāṁ nṛ-loke, kaṣṭān kāmān arhate viḍ-bhujāṁ ye (SB 5.5.1). Awon Bhagavata niyen. Kosi ifarawe. Kosi iwe mimo ninu gbogbo agbaye yi bi Śrīmad-Bhāgavatam. kosi ifarawe kankan. Kosi idije kankan. Gbogbo oro towa ninu re da fun awujo eda. Gbogbo oro, gbogbo oro kan soso. Nitorina loye ka ti iwe pinpin yi siwaju. Bakana tabi keji, teyan ba gba iwe kan, asi jeere na. Osi riwipe, " Oh, won ti sonwo to po. Eje kin wo nkan to wa ninu re." Toba ka śloka kan, ile aye re mani aseyori. śloka kan, oro kan. Ikan to da leleyi je. Nitorina lasen tenumo gan, " Edakun e pin awon iwe wanyi, e pin awon iwe yi." mṛdaṅga tosi lagbara ju. Awa sin korin, tan lulu mṛdaṅga. Won le gbo ohun na ninu yara yi tabi keji. Sugbon mṛdaṅga yo ma lo lati ile sile, latilu sile, lati awujo kan sikeji, mṛdaṅga yi.

Beena wanti funwa ni itosona pe nr-loke. Ara -eda yi nitumo Nr-loke, ninu awujo eda-eyan. Awa o le ti segbe kan pe " Awujo olugbe America leleyi" tabi " Awujo olugbe Europu leleyi," " Awujo olugbe India leleyi..." Rara, awon eda-eyan. Gbogbo awon eda eyan. Kosi isasoto kankan lori eto ibi toti wa. Gbogbo aawon eda eyan. kama wa soro nipa awon okuron ton laju, anārya. Wanti juwe won ninu Bhagavatam. Kirāta-hūṇāndhra-pulinda-pulkaśā ābhīra-śumbhā yavanāḥ khasādayaḥ (SB 2.4.18). Awon oruko yi wa n'be. Kirāta, Awon dudu nitumo Kirāta, awon eyan lati Africa. Won pe won ni Kirāta. Kirāta-hūṇa āndhra. Hūṇa, orile ede to wa lori ipo àríwá, lori Russia, Germany niyen, awon lonpe ni Hūṇa. Awon t'awa o tie mo gan wa. Khasādayaḥ, awon olugbe mongolia. Awon eyan tio ni irugbon to po, itumo Khasādayaḥ niyen, egbe Mongolia niyen. Kirāta-hūṇāndhra-pulinda-pulkaśā ābhīra-śumbhā yavanāḥ khasādayaḥ. Yavana, awon mleccha, yavana, awon tonje Muhammadan ati awon iyoku. Beena gbogbo won wa ninu Nr-loke yi, Nitoripe nr-loke loje. Gbogbo eda eyan. Loju wa , awa le rowipe orile ede yi da ju ikeji lo, otooro niyen. Awon Aryan ati awon tio kin se Aryan. Isasoto yi wa: Awon ton laju, awon tio laju, awon ton keeko, awon aikawe; dudu, funfun; eleyi anti iyen. Sugbon iyato laari ara eda leleyi.