YO/Prabhupada 0606 - We are Preaching Bhagavad-gita as it is, That is the Difference



Room Conversation -- January 8, 1977, Bombay

Olugbe okurin India (1): Elo leyin pa nibi lojojumo? Wonfe mo iye teyin pa nibi, fun iwe aro aje.

Prabhupada: Oh, iye iwe t'awa ta? Lakh marun si mefa.

Olugbe Okurin India(1): O daa.

Prabhupada: Ele ri fun ara yin iye t'awa n'ta.

Olugbe okurin India(1): Ati aduru awon eyan ton gba awon iwe wanyi. Iwe iroyin yi ko to dollar kan. Ninu America rupee kan niyen. (Ede Hindi) ... iwe iroyin fun won.

Prabhupada: Beena itan to wa niyen. Ati awon olugbe Europe...,ode ati didirin ko niwon pe wan ma ra iwe esin, tio kin se Bibeli won. Se ri? Beena oni agbara gan. Beena ninu asiko tawayi, Agbodo paarapo lati ri wipe won tisi waju dada. Mon sise yi fun ara mi pelu iranlowo awon... sugbon awon olugbe Inidia kankan o wa . Isoro to wa niyen.

Ashok Chugani: Mo rowipe awon olugbe India wonyi fe sise ninu abule ton ti wa.

Prabhupada: Koseni ton lo sibe.

Ashok Chugani: Beena, toba jepe eyin ti losi Bharatpur laipe, awon abusun 5,200 lon lo fun awon eyan ton wa fun netra-yajna, iwosan oju awon eyan.

Prabhupada: Mo mobe. Mo mo. Sugbon mon soro nipa asa yi.

Ashok Chugani: Asa, beeni.

Olugbe okurin India (1): Iralowo gidi lon fun awon olugbe India.

Olugbe okurin India (2): (kose gbo)... nkan karma, enikan toju won.

Olugbe okurin India (1): Eyan o le.....

Ashok Chugani: Ninu bhakti ati ninu..

Prabhupada: Sugbon nkan to wa niwipe awa n'se iwaasu nipa Bhagavad-gita gege boseje. Ninu Bhagavad-gita kosibi ton ko wipe ke toju oju awon eyan Kosi iru oro bayi nibe. Eyin la da eleyi sile. Sugbon awa sin sewaasu Bhagavad-gita gege boseje. Iyato to wa niyen. Iwaasu wa niwipe dipo teyin ma fun oju awon eyan ni irorun, e fun ni nkan tojepe koni pada wa sinu aye yi lati gba ara eda imi. Eyin o le wa ona abayo fun isoro wanyi. Enikan toju oju re, enikan toju ekana, enikan toju irun, elomi n'toju nkan imi, oko tabi obo, ati bayi bayi lo. Kosi bosefe yanju isoro to wa. Isoro to wa niwipe, wanti salaaye ninu Bhagavad..., janma-mṛtyu-jarā-vyādhi-duḥkha-doṣānudarśanam (BG 13.9). Ogbin ori niyen. Lesekese teyin ba ni ibimo, eyin ma l'oju, eyin ma ni aisan oju, vyadhi. Janma-mṛtyu-jarā-vyādhi. Teyin ba gbajanma-mṛtyu, lehin na laarin janma-mṛtyu, vyādhi ati jarā wa nibe. Eyin gbodo gbabee. Ele ni itura die, sugbon eyin godo gba bee. Beena ona abayo ko niyen. Ona abayo ni lati fi ipaari si janma-mṛtyu-jarā-vyādhi. Ona abayo to wa niyen. Ona abayo to daju niyen. Beena nkan t'awa sin fun awon eyan niyen - Kolesi isoro oju riro mo. Aisan to wa... Kasowipe okurin kan wa to l'aisan, beena nigbamoi o le ni ori fifo, nigbami oju riro, nigbami ekana le ma dun, teyin ba fun logun fun ori-fifo. Ona abayo koniyen. Ona abayo towa niwipe okurin bayi bayi l'aisan bayi l'ara. Bawo lasele fun ni'wosan? Beena nkan ti Bhagavad-gita wa fun niyen. Tyaktvā dehaṁ punar janma naiti (BG 4.9). lesekese teyin ba gba ara eda yi - kleśada. Na sādhu manye yato ātmano 'yam asann api kleśada āsa dehaḥ (SB 5.5.4). Asann api. Fun igba die l'ara eda yi ma wa fun. Beena nitoripe ara eda yi kole wa tayeraye, fun igba die na l'aisan na ma wa. Beena itosona Krsna niwipe tāṁs titikṣasva bhārata. Mātrā-sparśās tu kaunteya śītoṣṇa-sukha-duḥkha-dāḥ (BG 2.14). E gba ona abayo yi - ona abayo to daju, lati fi ipaari si janma-mrtyu. Sugbon won o mo, pe won le fi ipaari si. Wan kan sise lori awon isoro toni to wa fun igbadie. Won sin rowipe nkan pataki niyen. Kilo se pataki na? Kasowipe eyin l'ewo lara. Teyin ba fi abere fi gun ( ohun nkan ton fon) se ewo na ma tan? Won gbodo lo ise abe fi yo kuro. Beena nkan ti egbe wa yi wa fun niyen. Kon wa fun janma-mrtyu, nkan ti mo feso niwipe, fun igba die jarā-vyādhi. O da bee, sugbon Krsna sowipe - T'aba gba itosona , Bhagavad-gita - isoro ko niyen je. Ti isoro die ba wa, tāṁs titikṣasva bhārata. Isoro gidi to wa ni janma-mṛtyu-jarā-vyādhi (BG 13.9), e gbiynaju lati fi ipaari si. Ogbon gidi niyen. Tyaktvā dehaṁ punar janma naiti mām eti kaunteya (BG 4.9). Asa wa niyen; ikeeko niyen - ema foju si oun to ma wa fun igba die. Ogbon gidi ko niyen. E funwon l'asa yi, imoye Krsna. Beena awa ti ni ara eda yi. Ele yanju oju riro na, sugbon boti jepe eyin ni ara eda yi, isoro tuntun ma jade. Kosi idaniloju kankan pe leyin igba toba toju oju re tan, koni si aisan kankan mo. janma-mṛtyu..., er, mātrā-sparśās tu kaunteya (BG 2.14). Beena e sewaadi lati fi ipaari si gbogbo e.. Awujo veda niyen, pe eyin o gbodo di baba, tabi iya, teyin o ba le yo awon omo yin kuro ninu iyika iku ati ibimo. Pitā na sa syāj jananī na sā syāt na mocayed yaḥ samupeta-mṛtyum (SB 5.5.18). Isoro to wa niyen. Asa gidi to wa niwipe " Omode yi ti wa s'odo wa, agbodo ko leeko toma ranlowo lati ma pada sinu aye yi." Nitoripe lesekese tawa ba gba ara eda.... o rorun gan lati ni oye ninu eto na, sugbon Bhagavad-gītā ti ko wa pe, yadā yadā hi dharmasya glānir bhavati (BG 4.7). Ti sawon eyan ba gbagbe isoro wanyi, janma- mrtyu-jara-vyadhi, Krsna man wa fun ara re lati ko won pe " Isoro teni leleyi."