YO/Prabhupada 0607 - In our Society, You are all Godbrothers, Godsisters



Lecture on SB 1.3.13 -- Los Angeles, September 18, 1972

Ṛṣabhadeva, O si ronu pe " Eyin omo okurin mi, ile aye eda yi, koye ka lo nilokulo bi awon elede at'aja." Igbadun iye ara wa laarin awon elede na - niwonba to da. Kosi ihamo kankan. Kosi ihamo kankan. Ninu awujo awon eda eyan awon ihamo to po wa. Mātrā svasrā duhitrā. Gbogbo awon śāstra sowipe, " Kosi... Sugbon awon awujo wanyi wa - awa o fe soro nipa won - awon eyan tonse imo ako ati abo pelu iya won, aburo obirin won at'omo-obrirn. Sugbon teletele bayi ko lose ri. Kosen bayi, oo to po gan nisin. Sugbon śāstra sowipe, mātrā svasrā duhitrā vā nāviviktāsano bhavet (SB 9.19.17). " Eyin o gbodo joko sibi ti awon eyan o si pelu iya yin, pelu omo-obirin aburo yin, pelu omode - obirin yin." Beena eyan le sowipe, " Eni to ba le ni imo ako ati abo pelu iya re, pelu aburo-obirin re, pe didinrin tabi elese ni onitoun. Rara. Śāstra sowipe balavān indriya-grāmo vidvāṁsam api karṣati. " awon iye ara wanyi si lagbara toje pe, eyan le logbon gan, sugbon asi bosinu iwa wanyi." Asi bere sini ni awon ifekufe okan niwaju iya, aburo obirin ati omo obirin re.

Beena awon iye ara wanyi si lagbara gan. Balavān indriya-grāmaḥ. Ihamo loje. Kama wa soro nipa won iyoku. Nitorina, ikeeko to daju lo titi ati awujo Veda ni lati gba awon obirin bi iya afi iyawo eni. Mātṛvat para-dāreṣu. Para-dāreṣu. Gbogbo awon eyan loye kon se igbe yawo. Iyawo nitumo Dara. Para-dāreṣu, iyawo elomi. Kosejo boya o kere juyin lo tabi o dagba ju yin lo, sugbon egbodo huwa si bi iya. Nitorina ninu asa Veda, lesekese teyan ba ri obirin Eyin ma pe ni "Iya" Mātājī Lesekese, "Iya". Eyin ti ni asepo iya s'omo niyen. Obirin asi huwa b'iya s'Okurin tio mo, okurin na asi huwa s'obirin tio mo b'iya. Awujo Veda leleyi. Beena agbodo mu jeje. Ninu awujo wa, aburo-okurin at'obirin leje si ara yin. Tabi awon ton ti bimo won dabi iya. Beena agbodo se jeje. Lehin na eyin ma di dhira, eni tori re pe. Iwa awon brahmana leleyi, asa brahmana. Konsepe " Nitoripe moti l'aye lati sere pelu awon obirin ton lewa, beena mo gbodo lo won nilokulo. " Tabi ki awon obirin na ma huwa bayi.. Rara. Nitorina lase f'ihamo yi: ema ni imo ako ati abo laise igbeyawo.

Eyan gbodo di dhira. Lehin na ele sewaadi nipa imoye Oluwa. Kosibi awon Eranko sefe ni imoye Oluwa. Nitorina lonse sowipe dhīrāṇām. Vartma. Ona tofi han, fun awon dhira niyen, konse fun adhira. Dhīrāṇām. osi da tojepe sarvāśrama-namaskṛtam. Gbogbo awon āśrama ma teriba fun., itumo gbogbo āśrama ni brahmacārī, gṛhastha, vānaprastha, ati sannyāsa Beena teyin ban sise pelu awon obirin... Ati fun awon okurin ni itosona boseye kan huwa. Gbogbo awon iwe mimo Veda wanyi fun awon Okurin lon wa fun. Obirin gbodo tele oko re. Otan. Oko ma fun iyawa ni'tosona. Kosi nkankan biwipe ki awon obirin losi ile iwe tabi brahmacārī-āśrama, tabi kon loba oluko mimoo lati gba itosona. Ilana Veda ko niyen. Ilana Veda niwipe awon okurin gbodo keeko dada, awon obirin gbodo fe awon okurin wanyi. Ti awon okurin gan ba tie ni iyawo to po, ikobirinjo, beena oye ki gbogbo awon obirin f'oko. asi gba itosona lati oko re. Ilana Veda niyen. Koye ki awon obirin losi ile iwem ile eko giga tabi oluko mimo. Sugbon oko ati iyawo won lejo gba itebomi. Ilana Veda niyen.

Beena dhīrāṇāṁ vartma. Nitoripe awon eyan gbodo se jeje. Lehin na wan le soro nipa Krsna ati imoye Oluwa. Toba j'eranko, bawo lose fe ye? Ilana Veda niyen. Dhīrāṇām. Tose jeje nitumo Dhira. Ogbodo pe gbogbo obirin ni "iya." Mātṛvat para-dāreṣu para-dravyeṣu loṣṭravat. Ikeeko to wa nkyen, pe eyan gbodo pe iyawo elomi ni iya, owo elomi bi idoti loju tit. Koseni tofe wo. Beena, awa o gbodo fowokan owo elomi. Toba ti jepe enikan gbagbe apo owo re, apo owo loju titi, koseni toma fowokan. Ejeki eni toni pada wa mu nkan re. Awujo gidi leleyi. Para-dravyeṣu loṣṭravat, ātmavat sarva-bhūteṣu. kosi huwa jeje si awon eda base huwa s'ara re na. Teyin ba yinmi leekana, oma dun mi. Kilode ti mase yin elomi leekana? Teyan ba ge orun mi, inira to po loma je funmi. Kilode toye kin ge ofun awon eranko? Awujo gidi leleyi. Awujo Veda leleyi. Konsepe ka fiku pa awon eranko, ka sa tele awon obirin tio woso, ka fi pa owo. Awujo toda ko leleyi. Awujo awon eda eyan koleleyi.