YO/Prabhupada 0608 - The Devotional Service, We have to Execute it with Patience, with Enthusiasm



The Nectar of Devotion -- Vrndavana, October 20, 1972

Narottama dāsa Ṭhākura, acarya pataki, ti ko wa, "Ema gbiyanju lati mo nipa yugala-piriti, awon eto ife laarin Rahda ati Krsna, pelu irori ara yin. " Rara. E gbiyanju lati sise fun awon Gosvami mefa na, rūpa-raghunātha-pade haibe ākuti, bo won sen juwe. Gege bi Bhakti-rasāmṛta-sindhu. Lati ibere ko ni Śrīla Rūpa Gosvāmī ti bere lati ko awon eyan nipa eto ife laarin Radha-Krsna. Rara. O si kowon leeko, ni alakoko, eni ton ka iwe na gbodo gbiyanju lati di olufokansi mimo.

anyābhilāṣitā-śūnyaṁ
jñāna-karmādy-anāvṛtam
ānukūlyena kṛṣṇānu-
śīlanaṁ bhaktir uttamā
(Brs. 1.1.11)

Ni alakoko, ofe gbiyanju lati mu olufokansi na wa sori ipo ise ifarasi Oluwa. Vidhi-mārga. Die die toba tio baramu, lehin na raga-marga ma fihan si. Nkan eke ko ni Raga-marga. svayam eva sphuraty adhaḥ. Sevonmukhe hi jihvādau... (Brs. 1.2.234). Asepo pelu Krsna, eyin o le fi se nkan eke. Gbogbo wa lani ibasepo pelu Krsna ninu ipo talakoko wa. Awa ma fihan siyin teyin ba ni ilosiwaju ninu ise ifarasi Oluwa ninu awon ofin akosile bi sastra ati oluko mimo se juwe re. teyin ba ti keeko dada, eyin ma wa sori ipo raga-marga, lehin na ibasepo teni... Nkan tonn pe ni svarūpa-siddhi niyen. Svarūpa-siddhi. Beena oni asiko toma wa teyin ma de ipo svarūpa-siddhi. Gege bi svarūpa-siddhi.... Ife okan fun imo ako ati abo wa ninu gbogbo awon eda eyan, sugbon t'omo okunrin at'obirin ba ti dagba to, ife okan yi ma jade, konse nkan ton ko. Beena, rāga-mārga, svarūpa-siddhi, yi ma fara re han. Śravaṇādi-śuddha-citte karaye udaya. Udaya. udaya ni oro ton lo. gege bi orun. Eyin ma foju ri orun lesekese tobati jade. Eyin o le sofun orun pe ko jade laale. Kolese se. Orun ma ran. Eyin duro die. Nigbati asiko ba dee, laaro, ago mefa, eyin ma ri orun na. Beena, ise ifarasi Oluwa yi, egbodo sise yi pelu isuru to po, pelu igbiyanju. Utsāhāt dhairyāt niścayāt tat-tat-karma-pravartanāt. Oye ka gbiyanju... "Masi sise dada ninu egbe imoye Krsna yi." Amuye talakoko, igbiyanju. Onilora yi kole ranyinlowo. Eyin gbodo gbiyanju gan. Guru Maharaja mi man sowipe, prāṇa ache yara sei hetu pracāra. Oniwaasu, eyan le di oniwaasu toba gba aye yi. Oku o le di oniwaasu. Beena egbodo gbiyanju gan pe " mofe sewaasu ogo Oluwa mi bi mose lese si." Konsepe eyan gbodo di alakowe giga lati le sewaasu. Igbiyanju nikan loye koni, " Oluwa mi lagbara gan, osi lewa gan, osi lagbara gan. Beena mogbodo so nkan nipa Oluwa mi." Amuye to wa niyen, igbiyanju. konse dandan pe eyin gbodo mo nipa Krsna dada. Kolese se pe eyin ma mo nipa Krsna dada. Alailopin ni Krsna. Awa o le mo nipa Krsna ni pipe. Kolese se. Sugbon Krsna ma farahan beyin sele ni oye re si. Beena teyin ba di iranse olooto ti Krsna, utsāhān, t'aba si sise fun pelu isuru, lehin na Krsna ma farahan siwa. wan ti fun wa l'apeere lori eto yi. Gege bi omo-obirin toti se igbeyawo. Nigbogbo'gba awon omo-obirin mafe omo. Sugbon tobafe omo lesekese leyin toba se ibeyawo re tan, kolese se. O gbodo duro. Ogbodo sise fun oko re dada. Utsāhān dhairyāt tat-tat-karma-pravartanāt. Gege bi iyawo oloooto. Asiko ma wa toma l'oyun asi bimo na. Beena itumo niscayat niwipe... Gegi iyawo se mowipe nitoripe oti fe oko, oda ju pe oma ni omo. Otooro niyen. O le pe die. Beena, nigbateyin ba wole sinu ise ifarasi, bhakti-yoga, bhakti-marga, ilosiwaju yin daju, sugbon eyin godo gbiyanju ke ni'suru. Konsepe " Lesekese mofe ni omode," "lesekese mofer ni imoye Krsna nii pipe." Rara. Awonn ihamo po gan. Nitoripe awa ninu ibi tio wa ni pipe. Sugbon t'aba ni'suru, teyin sin sise ise ifarasi Oluwa yi bonse salaye ninu sastra. bi oluko mimo wa se jeerisi, lehin na o daju pe ilosiwaju yin ti ni idaniuloju. Ona to wa niyen. Utsāhān dhairyāt tat-tat-karma-pravartanāt. Eyin gbodo se awon ise wanyi. Gege bi awon akeko wa ton korin iye meridinlogun Nkan kekere ni orin merindinlogun. Ni Vrndavana awon olufokansi po ton ko iye 120 orin na. Beena, merindinlogun lo kere ju tele se. Nitoripe mo mope ni ilu geesi oma lee gan fun awon eyan lati pari merinlelaagota tabi 120, merindinlogun lo kere ju telese. E gbodo paari e, Tat-tat-karma-pravartanāt. Ilana to wa niyen. Ke tele awon ofin wanyi. Bayi, oye ka tele awon ofin oluko mimo ati sastra. Lehin iyoku ma tele. Idaniloju wa fun aseyori tema ni.