YO/Prabhupada 0610 - Unless one accept the Institution of Varna and Asrama, He's not Human



Lecture on BG 7.1 -- Calcutta, January 27, 1973

Teyin bafe mo nipa Krsna tabi Oluwa pelu irori lasan, fun odun kan nikan ko, odun meji...Panthās tu koṭi-śata-vatsara-sampragamyo vāyor athāpi. Pelu irori nikan ko, sugbon pelu oko afefe ton fo pelu iyara vayu, tabi afefe tabi okan, iyara okan eda, beena leyin aimoye odun, eyin o le de bee. avincintya loje, kole yewa. sugbon teyin ba gba ilana krsna-yoga, tabi bhakti-yoga, lehin na eyin ma mo nipa Krsna laipe. Bhaktyā mām abhijānāti yāvān yaś cāsmi tattvataḥ (BG 18.55). Lati mo nipa Krsna pelu oye tio jinle, kole to. Iyen na da sugbon egbodo ni tattvatah, nkan ti Krsna je gangan. Asi le mo nipa oye yi - bhaktya, lati Krsna-yoga yi. Bibeko,

manuṣyāṇāṁ sahasreṣu
kaścid yatati siddhaye
yatatām api siddhānāṁ
kaścin māṁ vetti tattvataḥ
(BG 7.3)

Aimoye awon eda to wa laye yi. Bi eranko ni opolopo ninu won je - ko s'asa kankan laye won. Nitoripe, gege bi asa Veda wa, afi teyan ba wole sinu ile-eko varna ati asrama, onitoun o kin seyan eda. won o le gba. Beena Krsna ti sowipe manuṣyāṇāṁ sahasreṣu. Ta lon gba varnasrama yi? Rara. ipo alebu. Beena ninu ipo alebu yi eyin o le mo eni t'Olorun je, eni ti Krsna je Nitorina Kṛṣṇa sowipe manuṣyāṇāṁ sahasreṣu. Ninu aimoye awon eda, boya ikan ninu won ma gba ile-eko sayensi ti varṇāśrama-dharma. Awon ton tele Veda daju daju. Ninu awon eyan ton tele awon ofin Veda yi daju, opolopo ninu won lon feran karma-kanda, awon ayeye ebo. Beena ninu opolopo awoneyan tonse awon ebo ayeye wanyi, ikan ninu won lee ni illosiwaju ninu imoye na. Won pe won ni jñānī, tabi awon alakowe elejo iranu. Awon eyan wanyi o kin se katmi sugbon jnani. Beena ninu aimoye awon jnani wanyi, boya ikan ninu won le di mukta, awon ton ti gba ominiran. Brahma-bhūtaḥ prasannātmā na śocati na kāṅkṣati (BG 18.54). Ipo igbala leleyi. Eni to ba je emi toti mo nipa Brahma, kosi nkankan tofe sukun fun tabi tole fun ni ibanuje. Nitoripe ninu ipo kari aisan meji lowa: ife okan to lagbara ati ibanuje. Ounkoun teyin ba ni, toba sonu, lehin na ma bere sini sukun. "OH, moni nkan bayi bayi nisin o ti sonu." ounkoun t'awa o ba ni, a ma bere sini sa tele. lati le ni nkan na, asi bere sini sise gan. toba de ti sonu, asii bere sini suun. Ipo karmi leleyi. Beena brahma-bhūtaḥ stage... Itumo Ipo Jñāna niwipe eyan na o ni ibanuje kankan mo. Prasannātmā. "Oh, ahaṁ brahmāsmi nimi. Kini mo ni lati se pel'ara yi? Ise mi ni lati keeko mimo, brahma-jnana." Beena lori ipo yi, brahma-bhūtaḥ prasannātmā na śocati na kāṅkṣati samaḥ sarveṣu bhūteṣu (BG 18.54). Idanwo to wa niyen. koni ibanuje kankan. koni ife okan kankan. egbe loje si gbogbo eyan. Paṇḍitāḥ sama-darśinaḥ.

vidyā-vinaya-sampanne
brāhmaṇe gavi hastini
śuni caiva śva-pāke ca
paṇḍitāḥ sama-darśinaḥ
(BG 5.18)

Kosi isasoto kankan laye re. Beena bayi, teyan ba wa lori ipo yi, lehin na mad-bhaktiṁ labhate parām (BG 18.54), lehin na asi wa sori ipo ise ifarasi Olorun. toba si wa sori ipo ise ifaras'Olorun yi, bhaktyā mām abhijānāti yāvān yaś cāsmi tattvataḥ (BG 18.55), lehin na lole se.