YO/Prabhupada 0653 - If God Is Not A Person, Then How His Sons Become Persons?



Lecture on BG 6.6-12 -- Los Angeles, February 15, 1969

Olufokansi: wanti salaye ninu Padma Purana, " Koseni tole ni oye nipa oruko mimo, irisi mimo ,awon amuye ati akoko idaraya mimo ti Sri Krsna pelu iye ara lasan. Afi toba wa sori ipo ton sise mimo fun Oluwa, lehin na lole ni oye nipa oruko mimo, irisi mimo, amuye ati akoko idaraya mimo t'Oluwa."

Prabhupāda: Beeni, Eleyi se pataki gan. Nisin, Krsna, awa ti gba pe Krsna l'Oluwa. Nisin, bawo lase gba pe Oluwa ni Krsna? Nitoripe awon iwe Veda toi salaaye , gege bi Brahma-samhita, īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ sac-cid-ānanda-vigrahaḥ (BS 5.1). Oju inu... Awon eyan ton wa lori ipo ifekufe okan ati aimokan, wan foju inu fi ni imo nipa Oluwa. Tonba de ti ni idamu, wan ma sowipe, "Oh eyan ko l'Olorun. Ofurufu loje." Ibanuje niyen. Sugbon looto, Kilode t'Olorun o se ni l'ara/ Vedanta ti sowipe, janmādy asya yataḥ (SB 1.1.1): Latii otito to gaju ni gbogbo awon irisi aye yi ti jade. Nisin awa ti ni irisi wa. Beena awa na sini, Awa ni kan ko, awon irisi orisiri eda lowa laye yi. Nibo lonti wa? Nibo ni irisi yi ti jade? Ibeere ogbon ori leleyi. T'Olorun o ba kin seyan, lehin na bawo ni awon ome re se j'eyan? Ti baba re o ba kin seyan, bawo lose d'eyan? Ibere ogbon ori lelyi. Ti baba mi o ba l'ara kankan, nibo ni moti ri ara temi gba? Sugbon awon eyan sin foju inu fi rori, nitoripe ibanuje ti mu won, nigbaton ba riwipe isoro to po gan wa peli irisi yi, nitorina Olorun o le ni irisi kankan. odi keji eto yi leleyi. Sugon Brahma-samhita sowipe rara. Olorun ni irisi re, sugbon sac-cid-ānanda-vigrahaḥ loje. Īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ sac-cid-ānanda-vigrahaḥ (BS 5.1). Sat, cit, ānanda. tayeraye nitumo Sat. Tayeraye nitumo Sat, imoye nitumo cit ati igbadun nitumo ananda. Beena Olorun si ni irisi re, sugbon irisi re kun fun igbadun, imoye asi wa tayeraye. Nisin e wo ara teyin. Ara yin o le wa tayeraye beena ko kun fun igbadun tabi imoye. Nitorina Oluwa ni irisi re, sugbon irisi re yato. Sugbon lesekese t'awa ban soro nipa irisi, awon ma bere sini ronu nipa ara tojo t'awa. Nitorina odikeji loje, ko l'ara. Kos'ogbon kankan. Imoye gidi ko niyen. Nitorina ninu Padma Purana wan sowipe eyin o le ni oye, nipa irisi, oruko, amuye, ohun elo t'Olorun pelu awon iye ara aye yi. Ataḥ śrī-kṛṣṇa-nāmādi na bhaved grāhyam indriyaiḥ (CC Madhya 17.136). Pelu irori teyin ni, nitoripe ogbon ori yin o daju, bawo leyin sefe so isokuso lori eda to gaju? Kolese se. bawo lasele se? Sevonmukhe hi jihvādau. Teyin ba ko iye ara yin, egbodo ya iye ara yin si mimo, iye ara to wa ni mimo yi ma je keyin ri Olorun.

gege bi teyin ba ni aisan, aisan oju, iyen o wipe eyin o le riran mo. Nitoripe oju yin ni aisan ojum iyen o wipe eyin o le riran mo. Iyen o wipe kosi nkankan lati ri. Eyin o le riran. Beena, eyin o le mo nipa iru ara t'Oluwa ni nisin, sugbon ton ba yo aisan oju yin kuro, e le ri. Nkan tafe niyen. Premāñjana-cchurita-bhakti-vilocanena santaḥ sadaiva hṛdayeṣu vilokayanti (BS 5.38). Brahma-saṁhitā sowipe awon olufokansi t'oju won kun fun ife Oluwa, iru awon eyan bayi, Oluwa n'be ninu okan re nigbogbo'gba, fun wakati merinlelogun. Beena eyin gbodo ya iye ara yi si mimo. Lehin na ele ni oye nipa irisi Oluwa, nkant'oruko Oluwa je, amuye Oluwa, iru oun elo t'Oluwa. Oluwa lo ni gbogbo nkan. Wan ti salaye awon nkan wanyi ninu iwe Veda. gege bi apāni-pādo javana-gṛhīta. Wan sowipe Olorun o l'apa tab'ese. Sugobn ole gba ounkoun teyin ba fun. Olorun o l'oju at'eti, sugbon ole ri gbogbo nkan, o le gbo gbogbo nkan. Beena awon oro tako leleyi. Itumo re niwipe nigbat'awa ban soro nipa riri, awa man rowipe eyan na gbodo loju bi tawa. Irori okan wa niyen. Oluwa loju, Ole riran ninu okunkun. Eyin o le rian ninu okunkun. Beena osi ni oju toyato. Olorun le gbo. Olorun ninu ijoba re to jina gan siwa, sugbon teyin ba so nkan, oro abosi, o le gbo. Nitoripe O joko ninu ara yin. Beena kosi besele sa kuro latibi tole ri yin,tabi k'Oluwa ma gbo tabi k'Oluwa ma fowokan yin.