YO/Prabhupada 0738 - Krishna & Balarama have again descended as Caitanya & Nityananda



Lecture on CC Adi-lila 1.2 -- Mayapur, March 26, 1975

Kṛṣṇa Caitanya ati Nityānanda leleyi, idanimo wan ni Oluwa Krsna ati Balarama. Nisin, nigbati Krsna wa, awon aburo meejeji wan yi je oluso maalu ore awon gopi ati omo si Mama Yasoda ati Nanda Maharaja. Aye wan ni Vrndavana niyen. Krsna ati Balarama, awon omo-okurin oluso maalu. Itan t'alakoko ti Krsna-Balarama niyen. Ise imiton se niwipe wan losi Mathura, wan pa Kamsa ati awon jagun jagun, lehin na won losi Dvaraka, won si ba awon esu t o gan ja. Sugbon titi de odun merin dinlogun wan wa ni Vrndavana, ile aye to rorun, to si kun fun idunnu. paritrāṇāya sādhūnām niyen (BG 4.8). Sadhu, awon olufokansi, nigbogbo igba lon gbiyanj lati ri Krsna, Balarama ati awon alabasepo re. Ibanuje wan man po ton ba tife fi Krsna sile. Lati funwa l'emi, Krsna-Balarama lo gbogbo asiko omode won ni Vrndavana. Lati Vrndavana, si Mathura, de Dvaraka ati orisirisi ibi ton lo, ise to wa ni vināśāya ca duṣkṛtām: pipa awon esu. Ise meji lon ni: Lati fun awon olufokansi ni alafiaa, ati lati pa awon esu. Otito to gaju ni Krsna ati Balarama. Kosi iyato laarin pipa ati ife. Awon ton pa wansi bo lowo idimu aye yi.

Nisin awon aburo mejji wanyi ti wa bi Śrī Kṛṣṇa Caitanya-Nityānanda. Sahoditau: beena wan jo farahan. Konsepe ikan wa ikejo o wa. rara. Awon mejeji. sahoditau. wansi fi won we orun ati osupa. ise orun ati osupa ni lati yo gbogbo okunokun to wa. Orun ma ran l'ojo, osupa ma ran laale. sugbon orun ati osupa yi lagbara, citrau, wan jo farahan leekona. Sugbon ise wan nkankan loje, tamo-nudau. lati tana s'okunkun ni ise wan, nitoripe awa wa ninu okunkun yi. gbogbo awon eyan ninu aye yi wa ninu okunkun. Aimokan nitumo okunkun yi. Awon eranko nipataki. "kilode ton se j'eranko, awon eyan ton mura dada ton lo si ile iwe giga? Kilode ton se wa ninu okunkun?" Beeni, nitoripe won wa ninu okunkun. "Kini ijerisi to wa?" Iferisi to wa niwipe won o ni imoye Krsna. Ijerisi to wa niyen. Okunkun wa niyen. E bere lowo enikeni pe... Kile mo nipa Krsna. Koseni to mo,okunkun. Ijerisi to wa niyen. Bawo leleyi se je ijerisi? Nisin, Krsna sowipe. Bawol lose so? Na māṁ duṣkṛtino mūḍhāḥ prapadyante narādhamāḥ, māyayāpahṛta-jñānā (BG 7.15). Itumo Apahṛta-jñānā l'okunkun. Wan ni awon digiri lati awon ile eko giga, wan ni ilosiwaju ninu eto aye yi, sugbon māyayāpahṛta-jñānā. digiri wan.. nitoripe wan o mo Krsna dada, wan o si fe teriba fun Krsna, nkan ti Krsna sin so fun ara re: sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ vraja... (BG 18.66). On salaaye fun ara re. Nitoripe awon asiwere at'ode wanyi, wan wa ninu okunkun - wan o mo nkan ti ipinnu aye yi je - Krsna si dara to jepe oun lon bere fun ara re: sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ vraja. Imoye to wa niyen. Awon eyan o si fe gba. Kilode? Narādhamāḥ. nitoripe awon eyan wanyi lon woole ju, naradhama. Bawo lonse di naradhama? duskritina, ese ton se. kini aye ese yi? Imo ako ako ati abo, eran jije, oti mimu ati ere tete. nitoripe wan feran awon nkan wanyi lon se je duskrtina ati naradhama, awon eyan ton woo le ju. Ounkoun toba ni bi imoye imoye eke loje, imoye eke. Māyayāpahṛta-jñānā. Ipo wa niyen.