YO/Prabhupada 1058 - Asafọ ti iwe mimọ Bhagavad Gita ni Oluwa Śrī Kṛṣṇa



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Asafọ ti iwe mimọ Bhagavad Gita ni Oluwa Śrī Kṛṣṇa. O wa ni imẹnuba lori gbogbo oju iwe mimọ Bhagavad Gita, bi Ẹní Isaju Eledumare, Bhagavan. Lootọ Bhagavan jẹ ọrọ ti o ma ntọkasi si ẹnikẹni to jẹ alagbara eniyan tabi eyikeyi orisa alagbara, ati laisianiyan Bhagavan nibi sapejuwe Oluwa Śrī Kṛṣṇa bi eniyan nla, sugbọn l’oju kanna o yẹ ki a mọ pe Oluwa Śrī Kṛṣṇa ni Ẹní Isaju Eledumare, gẹgẹ bi awọn ācāryas... mo lero lati wipe, bi Śaṅkarācārya, Rāmānujācārya, Madhvācārya, Nimbārka Svāmī, Śrī Caitanya Mahāprabhu ati ọpọlọpọ miran ti jẹrisi. Ọpọlọpọ awọn omowe alasẹ ni wọn wa ni orilẹ ede India. mo lero lati wipe, ninu imọ Vediki. Gbogbo wọn, ati Sankaracarya, ni wọn gba pe Sri Krsna ni Ẹní Isaju Eledumare. Oluwa funrarẹ na tun fi ararẹ mulẹ bi Ẹní Isaju Eledumare ninu iwe mimọ Bhagavad Gita. O si tun jẹ bẹ ninu Brahma-samhita ati gbogbo awọn Purāṇas, paapa ninu Bhāgavata Purāṇa: kṛṣṇas tu bhagavān svayam (SB 1.3.28). Nitorina a gbọdọ gba Bhagavad Gita bi o se wa ni itọsọna nipa Ẹní Eledumare funra Rẹ. Ni ori iwe Kẹrin ti Gita Oluwa wipe:

imaṁ vivasvate yogaṁ
proktavān aham avyayam
vivasvān manave prāha
manur ikṣvākave 'bravīt
(BG 4.1)
evaṁ paramparā-prāptam
imaṁ rājarṣayo viduḥ
sa kāleneha mahatā
yogo naṣṭaḥ parantapa
(BG 4.2)
sa evāyaṁ mayā te 'dya
yogaḥ proktaḥ purātanaḥ
bhakto 'si me sakhā ceti
rahasyaṁ hy etad uttamam
(BG 4.3)

Oluwa sọ fun Arjuna nibi wipe Oluwa sọ fun Arjuna nibi wipe ona sîsê ti yoga yi ọlọrun-oorun ni o kọkọ gba ni imọran, ọlọrun-oorun si salaye rẹ fun Manu, Manu na salaye rẹ fun Ikṣvāku, ati nipa ọna yi, nipa atọwọdọwọ awọn ọmọ-lẹhin, lati agbọrọsọ kan si imiran, ona sîsê yoga yi ti nsọkalẹ wa. sugbọn asẹhinwa asẹhinbọ ọna sîsê yi ti wa sọnu. Fun idi eyi Mo tun nse atunwi ọna sîsê yoga na fun ọ lẹẹkansi, ọna sîsê yoga atijọ yini ti Bhagavad-gita tabi Gitopanisad. Nitoripe iwọ Arjuna jẹ olufọkansi ati ọrẹ Mi, nitorina ni yio see se fun iwọ lati ni oye rẹ."

Alaye eleyi ni wipe Bhagavad Gita jẹ majẹmu ti o wa paapa julọ fun awọn ẹlẹsin Oluwa. Ipo mẹta oniruru awọn eniyan imọlẹ ni wọn wa, ti wọn npe ni jñānī, yogi ati bhakta, Tabi awọn alaimọra, awọn ti wọn sasaro, ati awọn ẹlẹsin. Nibi Oluwa sọ kedere fún Arjuna wipe "Emi o fi iwọ ṣe alakọkọ nitẹwọgba parampara titun parampara. nitori imọran atọwọdọwọ awọn ọmọ lẹhin ti atijọ ti padanu. Nitorina, o jẹ ifẹ Oluwa, lati fi idi parampara miran mulẹ ni ọna ero kanna ti o ti nbọ wa silẹ lati ọdọ ọlọrun-oorun si ẹlomiran, Beena, gba bayi kosi pin kaa kiri. Tabi ọna sîsê na, ọna sîsê yoga le ni ikede ni titun nipa irẹ. Di alaṣẹ ni agbọye iwe mimọ Bhagavad Gita." A ri bayi wipe Arjuna gba imọran Bhagavad Gita lẹkọ paapa nitori olufọkansi Ọlọrun, akẹkọ taara lọdọ Ọlọrun. iyẹn nikan ko, o tun jẹ ọrẹ Rẹ timọtimọ. Nitori idi eyi Bhagavad Gita le jẹ mi mọ l’ọna to dara ju nipa eniyan ti o ni iru awọn iwa Arjuna. Iyẹn ni wipe o gbọdọ jẹ olufọkansi. ti o ni ibasepọ taara pẹlu Oluwa