YO/Prabhupada 1062 - Awa sin'iwa lati fe ni idari lori iseda aye yi

From Vanipedia
Jump to: navigation, search
Go-previous.png Previous Page - Video 1061
Next Page - Video 1063 Go-next.png

Awa sin'iwa lati fe ni idari lori iseda aye yi
- Prabhupāda 1062


660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

A n'ifẹ lati jẹ oluwa lori awọn ohun elo ti isẹda aye Sugbon asise wa niyen. Nigba ti a ba ri awọn ohun iyanu ti nṣẹlẹ ni agba isẹda, o yẹ ki a mọ pe oludari kan wa lẹhin agba isẹda yi. Ko si ohun ti o wa ni ode aye lai ni idari. Lati ro wipe kosi oludari jẹ ọrọ ọmọde. Fun apẹẹrẹ, ki ọkọ mọto ma sare ṣiṣẹ, pelu ina-akanṣe mọto ti o dara, ti o si nsaare loju titi. ọmọde le ro pe o jẹ ohun iyanu "bawo ni oko yi se nsare, laisi ẹṣin tabi ẹranko miiran to nfa? sugbọn eniyan ti o loye tabi agbalagba, O fi gbakan mọ wipé koda lẹhin gbogbo ina-akanse mọto, laisi awakọ, ẹrọ na o le rin. Ero towa ninu oko, tabi ninu ile-ina monamona.. Nisin ni asiko tawayi, asiko awon ẹrọ lawa, sugbon oye ko ye wa pe lehin gbogbo awọn erọ wọnyi, leyin isẹ nla t'erọ yi n'se, awakọ ni o wa n'bẹ. Bakan naa Ọlọrun Ọba ni awakọ, adhyaksa. Oun ni Eledumare ti ohun gbogbo nsisẹ labẹ itọsọna Rẹ. Ni bayi, Oluwa ti gba awọn jīvas tabi awọn ẹda alãye ninu Bhagavad-gītā, bi a o ṣe kiyesi ninu awọn ori iwe ti wọn nbọ lẹhin, bi awọn ẹya ara Rẹ, Mamaivāṁśo jīva-bhūtaḥ (BG 15.7). Apa ati nkankana nitumo Aṁśa. Nisin gege bi ẹrun wura, wura na lo jẹ, omi iwonba die lat'okun si ni iyo bi omi okun na, bakanna si ni awa ẹda alãye, bi a se jẹ ẹya ara ti oludari to ga julọ, īśvara, Bhagavān, tabi Oluwa Śrī Kṛṣṇa, Awa ti ni, mo lero lati wi, gbogbo awọn agbara ti Ọlọrun Ọba niwọn kinkini nitori ti a jẹ īśvaras kinkini, īśvaras ti wọn nse itẹriba Awa na si fe ni idari lori awon nkan. A ngbiyanju lati dari isẹda, gẹgẹ bi a se ngbiyanju ni iwoyi lati sakoso lori ofurufu tabi awọn aye ọrun. Eyin fe jeki awon isogbe te daa le fo lori ofurufu. bẹ si ni ifẹ lati sakoso si wa nibẹ nitori b se wa ninu Ọlọrun o wa ninu awa na niwonba. Sugbon o yẹ ki a mọ peko jamọ nkankan. Awa si ni iwa lati ni idari lori iseda aye yi, lati ni idari lori ile aye yi, awa ki ise oludari to ga julọ Be ni o ti ni alaaye ninu Bhagavad-gita.

Kini isẹda aye? Eleyi na ti ni alaye. Isẹda aye, na ti ni alaye ninu iwe mimọ Gita bi prakriti ti o rẹlẹ-ju, prakrti ti o rẹlẹ-ju, wọn ti salaye ẹda alààyè bi prakriti to ga ju Prakriti wa labẹ iṣakoso nigbagbogbo, ti o wa labẹ... Itumo gidi fun prakrti ni obirin tabi abo. Gege bi oko se ni idari lori ise iyawo re, beena, prakrti wa labe idari yi. Olorun, Eledumare, loni idari yi, prakrti yi, awon eda aye yi ati iseda na, awọn ẹda alãye ati isẹda ni wọn wa ni itẹriba labẹ, Ọlọrun Ọba Ni ibamu pẹlu iwe mimọ Gita, biotilẹjẹpe awọn ẹda alãye, jẹ ẹya ara Ọlọrun Ọba, wọn kà wọn kun si prakriti. Eleyi ti wa ni mẹnuba ni kedere ninu ori iwe Keje ti Bhagavad Gita. apareyam itas tu viddhi aparā (BG 7.5). apara iyam ni ile aye yi je. Itas tu, prakriti miran tun kọja eyi. kini prakrti? Jiva-bhuta, ..

Iwa mẹta ni Isẹda aye fara rẹ jọ: ipo rere, ipo ifẹ ati ipo aimọkan. Eyi ti o leri awọn wọnyi, lori gbogbo awọn ipo wọnyi, ipo rere, ifẹ ati aimọkan, ni akoko ayeraye. Akoko tayeraye. ati nipa apapọ awọn ipo isẹda wọnyi ati labẹ iṣakoso ati idari akoko ayeraye, awọn akitiyan si wa Awọn akitiyan wa, ti a npe ni karma. Awọn akitiyan wọnyi ti nlọ lati igba lailai, a si ti njiya tabi ngbádùn awọn eso ti akitiyan wa na.