YO/Prabhupada 1065 - Eyan gbodo ko ni alakoko pe ara eda yi ko loje



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Eniyan gbọdọ kọkọ ni imọ pé oun kọ ni ara ilẹ yi. Nigbati ohun aye ba ti fun wa ni abawọn, a o di mi mọ bi ẹni ide. Ninu ide. Ati igberaga, imoye itanje... Imoye itanjẹ ni ifarahan ninu ero pe emi jẹ isẹ ọwọ ti isẹda aye. Eleyi ni a npe ni itanra ẹni jẹ. Eleyi ni a npe ni itanra ẹni jẹ. Gbogbo akitiyan ile aye, yasyātma-buddhiḥ kuṇape tri-dhātuke (SB 10.84.13). Yasyātma-buddhiḥ kuṇape tri-dhātuke, ẹni tí ero ara rẹ ti gba lọkan. Nisin, Bhagavad Gita ti jẹ sisọ lọrọ nitoripe Arjuna ti f'ara re si ipo aye yi. Eniyan gbọdọ ni igbala ninu ero ara ti ile aye. Eyini jẹ aṣayan alakọkọ fun awọn oniṣẹ imọlẹ, ti o fẹ ni ominira, ti o fẹ ni igbala. o si gbọdọ kọkọ ni imọ pé oun kọ ni ara ilẹ yi. Imoye yi, tabi imoye ti ile aye... Ni igbati a ba ni igbala ninu imoye aye, iyen ni a npe ni mukti. Mukti, tabi igbala, tumọ si ominira kuro ninu imoye ti aye. Śrīmad-Bhāgavatam na tun funni ni itumọ igbala: muktir hitvānyathā rūpaṁ svarūpeṇa vyavasthitiḥ (SB 2.10.6). Svarūpeṇa vyavasthitiḥ. Mukti tumọ si ominira kuro ninu imoye eleeri ti ile aye yi, ati ka fi idi mulẹ ninu imoye mimọ. Gbogbo ẹkọ ti inu iwe mimọ Bhagavad-gita ni pinnu lati se isọji imoye mimọ yi, nitori naa a ri ni ipele kẹhin ilana Bhagavad-gītā ti Ọlọrun nbi Arjuna léèrè boya ọkan rẹ ti di mimọ bayi. Boya imoye re ti ni iyasi mimo. Imoye ti o ti ni ya si mimọ tumọ si sise ni ibamu pẹlu awọn ilana ti Oluwa. Eyini ni apapọ gbogbo alaye lori imoye ti o ti ni ya si mimọ. Imoye ti wa nibẹ tẹlẹ nitori a jẹ ẹya ara ti Oluwa, ṣugbọn a ni itẹsi lati jẹki ipa ti o rẹlẹ mu wa lọkan. Itẹsi lati jẹki awon ipo ti aye mu wa lọkan. Ṣugbọn Oluwa, gẹgẹ bi Atobiju, ko si ohun ti nwu lori. Eyi ni iyatọ ti o wa laarin Oluwa Ọlọrun ati awọn olukuluku ẹmi kekeke.

Kini imoye yi? Imoye yi ni "Èmi’’."Kini emi jẹ nígbà náà? Ninu imoye eleeri "Emi " tumọ si "Emi ni Oluwa gbogbo ohun ti o wa ni itọju mi. Imoye eleeri ni yi. Emi ni "Onigbadun." Aye nyi lọ nitori gbogbo ẹda alãye kọọkan ro wipe "Emi ni oluwa ati ẹlẹda ile aye." Imoye aye ni iriran ìpín si meji nipa ti ọkan ati iwa hihu. Ikan ni wipe "Emi ni Eleda, " Ikeji niwipe " Emi ni onigbadun." Sugbọn Ọlọrun Ọba nikan ni awọn mejeeji, Ẹlẹda ati Onigbadun, ati nipa eyi to kan awọn ẹda alãye, gẹgẹ bi ẹya ara Ọlọrun Ọba, wọn ki nse ẹlẹda tabi onigbadun, ṣugbọn alajumọse ni wọn. Fun apẹẹrẹ, ẹya ẹrọ kan se ibasepọ pẹlu gbogbo ẹrọ. Tabi t'i a ba se iwaadi nipa ofin ara wa. Ọwọ, ẹsẹ, oju ati bẹbẹ lọ gbogbo wọn ni awọn ẹya ara, gbogbo awon nkan wonyi ni won nsisẹ, sugbon ni ododo awọn ẹya ara yi kọ ni onigbadun, ikun ni onigbadun. Ese wa sin rin kaakiri Owo wa nse ounje, eyin njeun, ati gbogbo apa ara eda, gbogbo awọn ẹya ara nse isẹ fun itẹlọrun ikun nitori ikun ni opòmulero ti o nsakoso eto ara. Nitorina a fi gbogbo ohun fun ikun. Prāṇopahārāc ca yathendriyāṇām (SB 4.31.14). A nkẹ igi nipa fifi omi fun gbongbo rẹ. a si nkẹ ara nipa bibọ ikun, Awon apa ara eda - owo, ese, oju, eti, ika owo - gbogbo awọn ẹya ara gbọdọ sowọpọ nitori ki ara ba le wa ni ilera. Bakanna, Ọlọrun Ọba ni onigbadun ati ẹlẹda. ati ni ti wa, bi ẹda alãye to ni tẹriba, ise owo agbara Ọlọrun Ọba, ti wa ni lati sowọpọ fun itẹlọrun Rẹ. Ifọwọsowọpọ yi yio se wa l’anfani. Gẹgẹ bi ounjẹ ti o lọ si inu se jẹ anfani fun gbogbo awọn ẹya ara miiran. Ti awọn ọmọ ika ọwọ ba ro wipe o yẹ ki wọn je ounjẹ fun ara wọn dipo ki wọn fifun ikun Eje ka da nikan gbadun e." Asise niyen. Kosi bi ika owo sefe gbadun. Ti ika owo bafe gbadun ounje na, won gbodo fi ounje na sinu ikun.