YO/Prabhupada 1068 - Ise meta lowa fun awon ipo orisirisi iseda aye yi



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Iru akitiyan mẹta ni o wa ni ibamu pẹlu awọn orisi ipa isẹda: Pūrṇam ni Oluwa jẹ, to pe ni ohun gbogbo, ati pe ko si ọna ti o fi le di ẹru awọn ofin ti isẹda aye.

Nitorina o yẹ ki a ni ọgbọn to boju mu lati mọ wipe ayafi Oluwa, nikan ni alakoso ohun gbogbo ni agbaye. O ti ni alaye ninu Bhagavad-gita:

ahaṁ sarvasya prabhavo
mattaḥ sarvaṁ pravartate
iti matvā bhajante māṁ
budhā bhāva-samanvitāḥ
(BG 10.8)

Oluwa ni ipilẹsẹ Asẹda. Oun na lo sẹda Brahmā. O tun wa ni alaaye. Oun lo sẹda Brahmā. Ninu ori iwe ikanla Oluwa ti wa ni apejuwe bi prapitāmaha (BG 11.39) nitori Brahmā ni apejuwe bi pitāmaha, baba nla, Oun si ni asẹda ti baba nla. Nitorina ki ẹnikan ma se pe ara rẹ ni alakoso ohunkohun, ki o si gba ohun ti Oluwa ṣeto fun nikan nipa akosilẹ fun u itọju rẹ. Ọpọlọpọ awọn apẹẹrẹ ni o wa nibẹ fun ni bi a se le lo awọn ohun ti Oluwa ti ṣeto ni akọsilẹ fun wa. Eyini tun ni alaye ninu Bhagavad-gita. Ni ibẹrẹ, Arjuna ti pinnu wipe oun ko ni ja ogun. Eyi jẹ ipinnu ararẹ. Arjuna sọ fun Oluwa wipe ko ṣee ṣe fun oun lati gbadun ijọba lẹhin ti o ba ti pa awọn ìyekan rẹ. Ipinnu yi ti ni ipinlẹ lori ero ara. Nitoripe o ti lero pe ara oun ni oun jẹ, ati pe awọn ẹbi rẹ ni awọn arakunrin rẹ, ọmọ-lẹbi, awọn ana, baba agba, ni awọn iran rẹ, nitorina o fẹ tẹ ara rẹ lọrun. Oluwa si sọ gbogbo ọrọ yi lati le yi ni ero pada. ati nigbẹhin Arjuna pinnu lati ja labẹ itọsọna ti Oluwa. nigba ti o sọpe, kariṣye vacanaṁ tava (BG 18.73).

Nitorina eniyan o wa fun lati ma ja bi awọn ologbo ati aja ninu aye yi Wọn gbọdọ ni oye lati mọ pataki ile aye ẹda eniyan ki wọn si kọ lati ma huwa bi awọn eranko lasan. Ẹda ọmọ eniyan yẹ ki o mọ ero aye rẹ. Eyi si wa ni itọsọna ninu gbogbo awọn iwe Vediki, koko rẹ si wa ninu Bhagavad-gita. Awọn iwe Vediki wa fun awọn eniyan, ki ise fun awọn eranko. Awọn eranko le pa ara wọn fun ounjẹ, bẹni ko si ọran nibẹ fun wọn. ṣugbọn ti eniyan ba pa ẹran fun itelọrun adun rẹ ti ko le ko ni ijanu, o ni lati dahun fun lilodi si awọn ofin isẹda. O si ti wa ni alaye kedere ninu Bhagavad Gita pe iru akitiyan mẹta ni o wa ni ibamu pẹlu awọn orisi ipo isẹda: awọn akitiyan ti rere, ti ifẹ ati ti aimọkan. Bakanna, iru ounjẹ mẹta ni o wa nibẹ pẹlu: ounjẹ ni rere, ifẹ ati aimọkan. Gbogbo awọn wọnyi ni wọn ti ni apejuwe kedere, ti a ba si lo awọn ilana ti Bhagavad Gita daradara, gbogbo aye wa yoo si wa di iwẹmimọ, ati nigbẹhin a o ni anfani lati de idélé Yad gatvā na nivartante tad dhāma paramaṁ mama (BG 15.6).

Iroyin na wa ninu Bhagavad-gita, pe ti o kọja ode aye yi, ode ọrun miran wa, ti a npe ni ọrun sanatana. Ninu ode aye yi, ni abẹ awọ sanmọ yi, a ri pe gbogbo ohun ni o wa fun igba diẹ. A wa saye, duro fun igba diẹ, fi eso silẹ, d’arugbo, lẹhinna di alaisi. Iyẹn ni ofin ti ile aye. boya ẹ fi ara yi se apẹẹrẹ, tabi a lo eso kan tabi ohunkohun ti a da sile, o ni ọjọ iparun rẹ nigbẹhin. Ṣugbọn leri ibùgbé aye yi, aye miran tun wa nibẹ ti a ni imọ nipa rẹ, pe paras tasmāt tu bhāvaḥ anyaḥ (BG 8.20). Isẹda miran, eyi ti o jẹ sanatana, ayeraye. Jiva na tun ni apejuwe bi sanatana, ayeraye. Mamaivāṁśo jīva-bhūtaḥ jīva-loke sanātanaḥ (BG 15.7). ayeraye nitumo Sanātana, sanātana. Oluwa na si ni apejuwe bi sanatana ninu ori iwe kanla. Nitori pe a ni ibasepọ timọtimọ pẹlu Oluwa, gbogbo wa ni a si jẹ ọkan ninu iwa... Sanatana Ẹni O tobijulọ ati awọn ẹda alaye sanatana, gbogbo wọn ni wọn wa lori ipo didara kanna. nitorina gbogbo eredi ti Bhagavad Gita ni lati se isọji ojúṣe sanatana wa, tabi sanātana, eyini ti a npe ni sanātana-dharma, tabi eyi ti o jẹ ojúṣe ayeraye ti ẹda alãye. A nkopa ninu orisirisi awọn akitiyan fun igba diẹ, ṣugbọn gbogbo awọn akitiyan wọnyi le se ya si mimọ. Nigba ti a ba fi gbogbo awọn akitiyan ti ki pẹ lọwọ wọnyi silẹ, sarva-dharmān parityajya (BG 18.66), ti a si gba awọn akitiyan ti Oluwa Ọlọrun ti pa l’asẹ. Eyini ni a npe ni aye mimọ wa.