YO/Prabhupada 1073 - Beena botilejepe awa o le ye ironu lati d'oga iseda aye yi kuro l'okan



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Ni iwọn igba ti bi a ko ba fi iwa yi silẹ lati jẹ oluwa lori awọn ohun elo isẹda Ninu Ori iwe Kẹdogun ti Bhagavad-Gita, a ti ni aworan gidi ti ile aye yi. O ti wi nibẹ:

ūrdhva-mūlam adhaḥ-śākham
aśvatthaṁ prāhur avyayam
chandāṁsi yasya parṇāni
yas taṁ veda sa veda-vit
(BG 15.1)

Nisin, ile aye yi ti ni apejuwe ninu ori iwe kedogun iwe mimo Bhagavad-gita bi igi ti gbongbo rẹ wá ni oke, urdhva-mulam. Se ẹ ni iriri igi ti gbongbo rẹ wa l’oke? A ni iriri igi ti gbongbo rẹ wa l’oke, nipa ojiji. Ti eniyan ba dúró l’eti odo tabi eyikeyi orisun omi, o le ri pe ojiji awọn igi ninu omi dorikodò, awọn ẹka lọ sisalẹ awọn gbongbo si wá sókè. Bákan náà, ni aye yi se jẹ ojiji ti ọrun ẹmi. Gege bi ojiji awọn igi ninu omi se dorikodò l'eti omi, Bákan náà, ni aye yi se jẹ ojiji ti ọrun ẹmi. Ninu ojiji ko si otitọ nibẹ tabi ohun ojulowo, sugbọn lati ojiji a le ni oye wipe awọn nkan gidi wa ti wọn jẹ otitọ. Fun apeere, aṣálẹ ko si omi nibẹ, ojiji omi to wa ninu ile gbigbe, ṣugbọn ilẹ to nse bi dingi lokere d’àba wipe iru nkan bi omi wa. Bee na, ninu ojiji ti ọrun ẹmi, tabi ile aye yi, kosi idunnu kankan, kos'omi kankan. ṣugbọn omi gidi ti ayọ gangan wa nibẹ ninu isalu ọrun. Oluwa da ni imọran wipe a le wọ ijọba ọrun ni awọn ọna wọnyi, nirmāna-mohā.

nirmāna-mohā jita-saṅga-doṣā
adhyātma-nityā vinivṛtta-kāmāḥ
dvandvair vimuktāḥ sukha-duḥkha-saṁjñair
gacchanty amūḍhāḥ padam avyayaṁ tat
(BG 15.5)

Padam avyayam na, tabi ijọba ọrun, ẹni ti o ba jẹ nirmāna-moha ni o le de bẹ. Nirmāna-mohā. Kíni eyi tumọ si? A nlepa lati l’àmi lori. Lorieke a fẹ àmi lori. Ẹnikan fẹ lati di "sa," ẹnikan fẹ lati di "oluwa," awon imi fe di Olori ijoba, tabi elomi fe d'olowo, elomi fe di nkan bayi bayi, Oba. Fun iwọn igba ti a ba ti ni ipọnle fun awọn àmi wọnyi... Nitoripe nigbẹhin gbogbo awọn àmi jẹ ti ara, awa ki ise awọ ara yi. Imọ yi ni ipele akọkọ ninu iriri ẹmí. Bee na ami ara ko gbodo fawa lokan. Ati jita-saṅga-doṣā, saṅga-doṣā. ti ni nkan ṣe pẹlu awọn ipa mẹta ti isẹda, sugbọn a gbọdọ s’ẹtọ nipa iṣẹ ẹsin fun Oluwa. Ti a ko ba ni ipọnle fun iṣẹ ẹsin ti Oluwa, nigbana a ko ni le se ikora nijanu lọwọ ipa ti awọn ohun elo isẹda. Nitorina Olyuwa sowipe, vinivṛtta-kāmāḥ, Ifẹkufẹ ati ifẹ aye ni wọn nfa isàmi ati ipọnra-ẹnile Ifẹ wa ni lati jẹ oluwa lori awọn ohun elo isẹda. Ni iwọn igba ti bi a ko ba fi iwa yi silẹ lati jẹ oluwa lori awọn ohun elo isẹda, ko si seese lati pada si ijọba ọrun, sanatana-dhāma. Ijọba ainipẹkun, Dvandvair vimuktāḥ sukha-duḥkha-saṁjñair gacchanty amūḍhāḥ, amūḍhāḥ padam avyayaṁ tat (BG 15.5). Odo metalokan tayeraye, tio le paare bi ile aye yi, le see sumọn fun, amūḍhāḥ. Itumo Amūḍhāḥ l'eni ti ko ni idamu kankan, Eni ti ifalọkan awọn igbadun eke aye ko si se ni dãmu. ẹni ti o wa ninu iṣẹ Oluwa Atobiju, Ẹni to ba ti wa bayi ni o le fi rọrun sunmọ ibugbe na ti o ga julọ. aye ainipẹkun yi ko nilo oorun, osupa tabi ina mọnamọna kankan. Eyini ni soki nipa isunmọ ijọba aye ainipẹkun.