YO/Prabhupada 1074 - Gbogbo iyan tan je ninu aye yi - nitori ara eda tani



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Gbogbo awọn inira ti a ni iriri ni ile aye ni wọn ti inu ara wa, Ibomiiran ninu Gita (8.21) o ti wa bayi pe :

avyakto 'kṣara ity uktas
tam āhuḥ paramāṁ gatim
yaṁ prāpya na nivartante
tad dhāma paramaṁ mama
(BG 8.21)

Avyakta tumọ si lainifarahan Ani ki ise gbogbo isẹda aye ni o wa ni ifihan niwaju wa. Awọn iye ori wa jẹ aláìpé to bẹ ani a ko ti le ri gbogbo awọn irawọ, gbogbo awọn aye ọrun ti wọn wa ninu agbaye yi. A le ri ọpọ alaye gba ninu awọn iwe Vediki nipa gbogbo awọn aye ọrun, a si le gba wọn gbọ tabi ki a ma fiyesi, gbogbo awọn aye ti wọn jẹ pataki, ni wọn ti wa ni apejuwe ninu awọn iwe Vediki, paapa ninu Śrīmad-Bhāgavatam. Sugbon aye ọrun ẹmí, eyi ti o kọja ode aye yi (BG 8.20), sugbon avyakta yi, eyini alainifarahan, oun ni paramam gatim, O yẹ ki eniyan nifẹ ki o si lepa ijọba ọrun yi, nitori ti a ba de ijọba ọrun na, yaṁ prāpya, ti oluwarẹ ba sunmọ tabi ti o ba de ijọba ọrun na, na nivartante, ko ni si ipada si ile aye yi mọ. eyini ibi ti o jẹ ibugbe ainipekun Oluwa lati be l'awa o ni lati pada wa.. (isinmi) Nibayi a le se ibeere bawo ni eniyan se le se lati sunmọ ibugbe Oluwa Atobijulọ. Alaye eyi na ti wa ninu Bhagavad-gita. Wọn sọ ni ori iwe kẹjọ, ẹsẹ-iwe 5,6,7,8, ilana lati le sunmọ Oluwa Atobijulọ tabi ibugbe Rẹ na tun ni apejuwe nibẹ. Wọn sọ nibẹ pe:

anta-kāle ca mām eva
smaran muktvā kalevaram
yaḥ prayāti sa mad-bhāvaṁ
yāti nāsty atra saṁśayaḥ
(BG 8.5)

Anta-kāle, ni opin aye rẹ, lasiko iku. Anta-kāle ca mām eva. Ẹnikẹni na, ti o se ìrántí Krsna, smaran, ti o ba le ranti. Eni ti o nku lọ, lasiko iku, ti o ba se ìrántí irisi Krsna ti o ba fi awọ ara rẹ silẹ ninu ero yi, o daju nigbana o ti sunmọ ijọba Ọlọrun., mad-bhavam. Bhavam tumọ si mimọ. Yaḥ prayāti sa mad-bhāvaṁ yāti. Mad-bhāvam ntọkasi titobi ayanmọ Eledumare. Bi a ti sapejuwe tẹlẹ, Ọba Atobijulọ ni sac-cid-ānanda-vigraha (BS 5.1) O ni irisi rẹ, irisi rẹ jẹ ainipẹkun, sat; o kún fun ìmọ, cit; ati alaafia, ananda. Nisin awa gan le yẹ wo ti awọ ara wa yi ba jẹ sac-cid-ānanda. Rara. asat ni ara eda yi. Dipo ko jẹ sat, asat lo jẹ. Antavanta ime dehā (BG 2.18), Bhagavad-gītā sọ wipe, antavat ni ara ẹda yi, fun igba diẹ lo wa fun. Ati.. Sac-cid-ananda. Dipo kodi sat, o jẹ asat, ilodi lojẹ. dipo ko jẹ cit, kún fun ìmọ, o kún fun aimọkan. A ko ni imọ ti ijọba ọrun, ani a ko ni imọ ni pipe ti aye yi paapaa. ọpọ awọn nkan wa ti wọn jẹ aimọ si wa, nitorina ara yi jẹ alaimọkan. Dipo ko kún fun ìmọ, o jẹ alaimọkan. Awọ ara wa nsègbé, o kún fun aimọkan, ati nirananda. Dipo ki o kún fun alaafia se ni o kún fun inira. Gbogbo awọn inira ti a ni iriri ni ile aye ni wọn ti inu ara wa.