YO/Prabhupada 0037 - Enikeni toba mo Krishna (Oluwa),Oun ni Guru



Lecture on BG 7.1 -- Hong Kong, January 25, 1975

Nitorina bawo ni a se le ni iye agbara Olorun, bawo ni a se le mo agbara isedaye, ati kini o nse agbara Olorun, bawo ni O se nse nkan, gbogbo nkan - iyen na je sayensi nla. Iyen ni a npe ni sayensi Olorun. Kṛṣṇa-tattva-jñāna. Yei kṛṣṇa-tattva-vettā, sei guru haya (CC Madhya 8.128). Caitanya Mahāprabhu so nipa eniti o je guru Itumo Guru ni wipe yei kṛṣṇa-tattva-vettā sei guru haya: "Enikeni ti o ba mo Olorun, oun ni guru" A ko le fun ra wa da Guru. Enikeni ti o ba mo Olorun bi o ti le wu to... A o le mo. A ko le mo Olorun ni amotan. Iyen o le see se. Awon agbara Olorun wa ni aimoye. Parāsya śaktir vividhaiva śrūyate (CC Madhya 13.65, purport). Agbara kan nse ise ni ona kan, agbara miran nse ise ni ona miran . Sugbon gbogbo won ni agbara Olorun. Parāsya śaktir vividhaiva śrūyate. Mayādhyakṣeṇa prakṛtiḥ sūyate sa-carācaram (BG 9.10). Prakrti na... A ri wi pe ododo yi wa lati eleda, ko ti le nse ododo nikan, orisirisi nkan ni oun jade - ninu eso Eso ododo rose, igi ododo rose na ma wa. Eso bela, igi bela na ma wa nbe. Bawo ni eyi se nsele? Lati inu ile kan na, inu omi kan na, ati awon eso ti won fi oju jora, sugbon won jade ni yato. Bawo ni eyi se nse? Eyi ni a npe ni parāsya śaktir vividhaiva śrūyate svābhāvikī jñāna. Awon eniyan yepere tabi oni sayensi ka roun wi, so wipe, "Iseda ni oun se awon nkan won yi" Sugbon won o mo nkan ti iseda yi je, ti o nse akoso awon ise idanida, aseda aye yi, bawo ni o se nse se.

Won so fun wa ninu Bhagavad Gita wipe, mayādhyakṣeṇa (BG 9.10). Olorun so wipe, "Ni abe akoso mi ni aseda se nse ise re." Otito oro ni yen. Aseda, ile erupe... Ile erupe ko le parapo fun ara re laisi owo nbe. Awon ile giga ti won da ofurufu l'aya, pelu erupe iyanrin ni won fi ko won, sugbon erupe iyanrin ko dede di ile giga ni ofurufu fun ra re. Iyen ko le see se. Emi kekere kan wa, ti o nse akoso bi enjinia tabi olu-kole, akitekt, ti o mu erupe iyanrin ti o si paa po lati ko ile giga to gun loke loke Eyi ni iriri wa. Nitorina bawo ni a se le so wi pe erupe iyanrin nsise funra ra re Erupe iyanrin ko le da sè se. O n'ilo ogbon ori to fori pe, eto lilo ati iparapo to yanju, nitori idi eyi, eto akoso to ga. Gege bi ninu ile aye yi, a ni eto ti o ga julo, oorun, lilo bibo ti oorun, agbara oru, agbara imole ti oorun. Bawo ni won se nlo? E wo nkan ti iwe mimo so ni pa re: yasyājñayā bhramati sambhṛta-kāla-cakro govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi. Ile oorun na dabi ile aye yi. Gege bi ni ile aye yi, a le ni awon olori orile ede pupo, sugbon tele tele ko wa ju eyokan lo, bakanna, ni ile aye ko kan olori kan wa Ni ile oorun ni a ti gba imo ijinle ti Bhagavad Gita Olorun ni, imaṁ vivasvate yogaṁ proktavān aham avyayam: (BG 4.1) "Vivasvan, oludari oorun, ni Mo koko se alaye imo ijinle ti a npe ni Bhagavad Gita" Vivasvan ni olori ile oorun, omo re si ni Manu. Akoko ni yi. Akoko ti a wa yi. Se l'akoko ti igba Vaivasvata Manu. Itumo Vaivasvata ni pe o ti odo Vivasvan wa, pe o je omo Vivasvan. A npe ni Vaivasvata Manu.