YO/Prabhupada 0038 - Oye won wa lati inu awon iwe mimo Veda



Lecture on BG 7.1 -- Hong Kong, January 25, 1975

Nisinyi, Olorun wa nbi. A ni aworan Krishna, aworan Krishna, tempili Krishna, orisirisi Krishna. Won ki nse nkan eruu. Won ki nse nkan ti a fo ju inu wo, gege bi awon amoye Māyāvādī se ro pe "O le fo ju inu re wo lokan" Rara. A ko le finu ro Olorun. Alailogbon miran ni yen. Bawo ni eyin se le finu ro Olorun? Iyen wa je pe Olorun ti di nkan ero fun oye yin. Oun ki ise nkan. Iyen ki ise Olorun. Nkan ti a ba pa le ro, iyen ki ise Olorun. Olorun wa ni waju yin nisinyi, Krishna. O wa sinu aye yi. Tadātmānaṁ sṛjāmy aham, sambhavāmi yuge yuge. Nitorina awonti won ti ri Olorun, e gba imoran yin lodo won..

tad viddhi praṇipātena
paripraśnena sevayā
upadekṣyanti te jñānaṁ
jñāninas tattva-darśinaḥ
(BG 4.34)

tattva-darśinaḥ. Aya fi ti e ba ri, bawo ni e se le fi ihinrere fun awon miran? Nitorina riri ni Olorun, ki ise ni pa ti itan nikan. Ninu itan abale, nigba ti Krishna wa lori aye yi, itan Ogun ti Kurukshetra nibi ti won ti fi oro inu iwe Bhagavad Gita si le, eyi je nkan itan gidi. Nitorina a le ti ara itan mo awon ogo Olorun ati lati ara iwe mimo. Śāstra-cakṣusā. Gege bi ni akoko yi, Olorun ko si ni oju iri wa, sugbon a fi ye wa lati inu iwe mimo eni ti Krishna nse

Nitori eyi śāstra-cakṣusā. Śāstra... Bo ya ki e gba a lati ohun ti oju nri tabi lati inu iwe mimo... Iwoye lati inu iwe mimo dara ju eyi ti a fi oju ri. Nitori idi eyi oye wa, gege bi omo leyin ofin Vediki, oye won wa lati inu awon iwe mimo Vedas. Won ki nse idasile imo funra ra won. Ti nkan kan ba ye wa lati ipa eri ti awon Vedas, iyen ti daju. Nitorina a ni oye Olorun lati inu awon Vedas. Vedaiś ca sarvair aham eva vedyaḥ (BG 15.15). Bhagavad Gita so bayi. E ko le fo ju inu wo Olorun. Ti alaimokan kan ba so wipe "Mo nfo ju inu okan mi ro" aimokan re ni yen. E gbodo ri Olorun ni pa ti awon iwe mimo ti Vedas Vedaiś ca sarvair aham eva vedyaḥ (BG 15.15). Idi re ni yi ti a fi nse eko awon Vedas. Nitori eyi ni a se npe won ni Vedanta. Imoran Krishna ni Vedanta.