YO/Prabhupada 0046 - Ema di eranko



Morning Walk -- May 28, 1974, Rome

Yogeśvara: Ki Bhagavan to lo, o fi ifa iwe kan sile pelu awon ibeere. Se mo le beere nkan ninu won?

Prabhupāda: Bee ni.

Yogeśvara: Wahala kan ti o da bi o nsele ni gba gbogbo leralera ni ijade awon ti won ndayaja yan pelu awon nkan ogun, eyi to je wipe, awon oniyanju fun ero iselu, ni opo julo fun awon ero iselu.

Prabhupāda: Beni gbogbo ipinle ofin ni mo ti s'alaye siwaju. Nitoripe won je eranko, ati nigba miran awon eranko igbo lile. Bo se ri ni yen. Eranko, awon orisirisi eranko ni won wa. Ekun ati kiniun, awon eranko lile ni yen. Sugbon eyin ngbe ninu ilu awon eranko. Ni ijo awon eranko, awon kan, eranko miran wa ti won le biburu nyen ko je iyalenu. Leyin gbogbo oro, e ngbe ninu ijo eranko. Nitorina e di omo eniyan, iyen in apeere ti o daju lo. Iyanju kan soso ti o wa ni yi. A ti koko se itenumo wipe, ijo awon eranko niyi. Ti awon eranko biburu ba jade, ki lo wa je iyalenu nbe? Leyin na, ijo eranko ni. Boya ekun lo jade tabi erin lo jade, eranko ni gbogbo won. Sugbon eyin ko gbodo di eranko. E sodi si. Iyen se dandan. A npe omo eniyan ni eranko ti o loye ninu. Ti e ba di ologbon nnu, iyen nse ni wiwulo. Sugbon ti e ba nse eranko, orisi eranko miran, iyen ko ni ran yin lowo. E gbodo di eniyan gidi. Sugbon, durlabhaṁ mānuṣaṁ janma tad apy adhruvam arthadam.(SB 7.6.1)

Awon eniyan yi won ko ni afojusi laye. Kini ohun afojusi omo eda..., won o mo. Nitorina won se atunse iwa eranko won, ni bayi, ni bayi. Gege bi won se ma nlo wo ijo alaifaso bora. Iwa eranko, o nri iyawo re nihoho lojoojumo, o si tu nlo wo ijo onihoho, o si nsan wo fun eleyi. Nitoripe won ko ni ohun ti ongba won laaye afi iwuwasi eranko yi. A bi beko? Abi kini idi re lati lo wo ihoho obinrin miran? E nri iyawo yin laaro ati loru ni ihoho. Kilode ti e ma... Nitoripe won o ni nkan ti o ngba won lokan. Awon eranko. Punaḥ punaś carvita-carvaṇānām (SB 7.5.30). Ka wipe aja, ko mo nkan to nje didun. O kan nfi ehin-run nkan, egungun kan, ni bayi, ni bayi. Nitoripe o je eranko. Ko ni ohun kan ti o gba lokan. Nitorina gbogbo ijo yi nje t'eranko. Ni pataki awon oyinbo. Won ti se idagbasoke ilaju lori iwuwasi eranko, to tumo si wipe, "Emi ni ara yi, ati pe iwulo aye mi to dara julo ni igbadun ara mi" Eranko ni yi. "Emi ni ara yi" Ara tumo si awon apa ara. " Ati pe lati se itelorun awon apa ara ni nkan igbega to pe ju lo. Iyen ni ilaju won.

Nitorina eni lati fi ilaju ti omo eniyan tooto han. E ma je ko ya yin lenu, eranko , ni iru ki ru, ni agbara k'agbara, won ma a jade. Leyin na nko, eranko ni se. Ofin akoda ni iwuwasi eranko. Nitoripe oun ro wipe, "Emi ni ara yi..." Gege bi aja se nro wipe, "Aja ni mi, mo tobi gan mo si l'agbara," bee na ni eniyan miran na nro wipe, "Orile ede nla ni mi." Sugbon kini ipinle ofin ? Aja na nronu re lori ara to ni, orile ede nla yi na nrora re lori ara to ni. Nitorina ko si iyato ninu aja yi ati orile ede nla yi. Iyato kan soso to wa ni pe omo eniyan, nipa ti ebun eda, ti ni awon ipa ara ti o dara pupo. sugbon ko ni agbara, tabi oye bi yi o se lo awon ipa ara to dara na, bi a se nni idagbasoke ninu emi ati bawo ni a se le kuro ninu aye asan yi. Ko ni ogbon fun eleyi. Ko le se ju lati lo awon ipa ara to dara yi fun iwuwasi eranko. Itumo re ni yen. Ko ni eko bi yi o se lo oye to dara. Nitori idi eyi, o nlo fun iwuwasi eranko. Ati pe awon eniyan ni gbogbo aye, nigba ti won ba ri awon oyinbo, won nro wipe "Won ni idagbasoke." Kini iyen? Idagbasoke ninu iwuwasi eranko. Ipinle ofin duro lori iwuwasi eranko. O ya won lenu. Won nse ifarawe. Bee na ni won se itelo iwuwasi eranko, ilaju eranko. Nisinyi a gbodo lodi si fun anfani ilaju tabi ilosiwaju ti omo eniyan.