YO/Prabhupada 0047 - Atobiju ni Olorun



Lecture on BG 7.1 -- Upsala University Stockholm, September 8, 1973

Awon orisirisi ona yoga lo wa, bhakti-yoga, jñāna-yoga, karma-yoga, haṭha-yoga, dhyāna-yoga. Opolopo awon ona yoga. Sugbon bhakti-yoga ni eyi to ga julo. Won so eyi ninu ori iwe keyin. Mo nka ori iwe Keje niwaju yin. Ni ipari eyin iwe Kefa, Olorun so wipe:

yoginām api sarveṣāṁ
mad-gatenāntar-ātmanā
śraddhāvān bhajate yo māṁ
sa me yuktatamo mataḥ
(BG 6.47)

Yoginām api sarveṣām. Eni ti o ba nse yoga ni a npe ni yogi. Olorun so wipe, yoginām api sarveṣām: "Laarin gbogbo awon yogi..." Mo ti so siwaju tele. Awon oniruru yogi ni won wa. Ninu awon yogi..." Yoginām api sarveṣām. Sarveṣām "tumo si "ninu gbogbo awon yogi" Mad-gatenāntar-ātmanā: "Eniti o ba nfi Mi sinu okan re." A le fi Olorun s'okan. A ni iworan Krishna. Ere Krishna, a nforibale fun. Nitorina ti a ba fi ara wa si nu si se esin Ere, aworan Krishna, ti ko si yato si Krishna, tabi, ni aisi aworan , a le se iyinlogo oruko mimo Olorun, Olorun na ni yen. Abhinnatvān nāma-nāminoḥ (CC Madhya 17.133). Atobiju ni Olorun. Nitorina , ko si iyato laarin Oun ati oruko Re.. Ko si iyato laarin Oun ati ere Re. Ko si iyato laarin Oun ati aworan Re Ko si iyato laarin Oun ati ori oro Re. Ohunkohun nipa Olorun ni nse Olorun. Iyen ni imo patapata. Nitorina boya e se oruko Olorun logo tabi e se esin aworan Olorun - gbogbo nkan ni Olorun.

Nitorina orisirisi apeere ise esin ni won wa.

śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ
smaraṇaṁ pāda-sevanam
arcanaṁ vandanaṁ dāsyaṁ
sakhyam ātma-nivedanam
(SB 7.5.23)

E kan feti gbo ni pa Olorun. Ifeti gbo yi na je Olorun. Gege bi a se ngbiyanju nisinyi lati gbo nipa Olorun. Ifetigbo yen na tun je Olorun. Awon odomokunrin ati obinrin won yi, won nkorin. ikorin yi na tun je Olorun bakanna. Śravaṇaṁ kīrtanam. Smaraṇam si tele. Ti e ba nkorin nipa Olorun, ti e ba nranti aworan Olorun, Olorun na ni yen. Tabi e ri aworan Olorun. Olorun na ni yen. E ri Ere Olorun. Iyen ni Olorun E ni eko nipa Olorun.

Olorun na ni yen. Nitorina ni onakona,

śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ
smaraṇaṁ pāda-sevanam
arcanaṁ vandanaṁ dāsyaṁ
sakhyam ātma-nivedanam
(SB 7.5.23)

Eyikeyi ninu awon ise mesan na, ti e ba fi se, ni owo kanna ni e o pade Olorun. Boya e ma gba lati se eto mesan-san, tabi mejo tabi meje, tabi mefa tabi marun, merin, meta, meji, bi o ti le je eyokan, ti e ba se ni lile ati... Gbimo wipe iyinlogo yi. Ko na wa ni nkankan. A nkorin kaa kiri gbogbo orile ede aye. Enikeni na sile ko lorin bi won ba se ngbo wa. Ko na yin ni nkan kan. Ti e ba si korin, ko si ipadanu lodo yin. Nitorina. Ti e ba fi eyi se iwa wu, ni kia kia ni e o pade Olorun Iyen ni anfani. lowo kan na. Nitoripe oruko Olorun ati Olorun ko ni yato...

abhinnatvān nāma-nāminoḥ (CC Madhya 17.133). Eyi je awon alaye ti iwe Vediki. Abhinnatvān nāma-nāminoḥ. Nāma cintāmaṇiḥ kṛṣṇaḥ. Oruko Olorun ni cintamani. Itumo Cintamani ni nkan èmi. Cintāmaṇi-prakara-sadmasu kalpa-vṛkṣa-lakṣāvṛteṣu (Bs. 5.29). Eyi ni awon alaye ti Vediki. Ibi ti Olorun ngbe, won se ni apejuwe. cintāmaṇi-prakara-sadmasu kalpa-vṛkṣa-lakṣāvṛteṣu surabhīr abhipālayantam (Bs. 5.29). Nitorina nama, oruko mimo Olorun, iyen na je cintamani, ti èmi. Nāma cintāmaṇiḥ kṛṣṇaḥ. O je enikan na, Olorun. Nāma cintāmaṇiḥ kṛṣṇaś caitanya (CC Madhya 17.133). Chaitanya tumo si nkan ti ko ku, nkan alaye. E le ni anfani kan na ni pa sise iyinlogo oruko Re gege bi igba ti e ba nba Olorun soro. Iyen na se se. Sugbon o je nkan ti o ma ye yin ni diedie. Nāma cintāmaṇiḥ kṛṣṇaś caitanya-rasa-vigrahaḥ. Rasa-vigraha tumo si inu didun, orisun gbogbo idunu.. Bi e ba se nyin oruko Olorun logo, Hare Krishna, ni diedie ni e ma bere si gbadun ife aladun ti o ju gbogbo nkan lo. Gege bi awon omo odokunrin ati obinrin yi, bi won se nkorin, won si njo pelu inu didun. Ko si eni ti o le farawe won. Won ki se were, ti won se nkorin. Niidaju, won nni ayo, inu didun ti ki se ti ile aye yi. Nitori idi eyi ni won se njo. Ko nse bi ijo-aja. Rara. O je ijo elemi, ijo ti emi. Nitorina... Nitori idi eyi a npe ni rasa-vigraha, orisun ayo.

Nāma cintāmaṇiḥ kṛṣṇaś caitanya-rasa-vigrahaḥ pūrṇaḥ (CC Madhya 17.133). Purna, pipe. Ki ise pe o fi eyo kan din ninu Olorun. Rara. Olorun patapata. Ti o pe. Purna. Purna tumo si pipe. Purnah suddhah. Suddha tumo si pe a so di mimo. Ibaje wa ninu ile alaye yi. Nkan ti ile, [iyepe] oruko koruko ti e le pe, nitoripe o ti ni ibaje ti asan, e ko lo se fun igba pipe. Eyi ni iriri miran. Sugbon kikorin ti mantra Hare Krishna yi, ti e ba nse lo fun wakati merin le logun, ko ni se yin laare lai lai. Iyen ni iyewo. E ma korin lo. Awon omo kunrin yi le korin fun wakati merin le logun, lai jeun, tabi mu mi. O dara bee gee. Nitoripe o wa ni pipe, o je ti emi, suddha. Suddhe tumo si mimo. Ko ni ibawon ti aye. Inu didun ti ile aye, ife ki ife... Ife ti o ga julo ni ile aye ni ife isepo. Sugbon e ko le gbadun eyi fun wakati merin le logun. Iyen ko se se. E le gbadun re fun awon iseju kan. O tan. Ti won ba ti le mu yin ni dandan lati je igbadun, eyin ma ko sile: Rara, o ti to." Iyen ni nkan ti ile aye yi. Sugbon nkan ti emi je ailopin. E le gbadun titi lai lai, wakati merin le logun. Iyen ni igbadun ti èmi. Brahma-saukhyam anantam (SB 5.5.1). Anantam. Anantam tumo si lai lopin.