YO/Prabhupada 0090 - Bibeko bawo lase fe se ni ISKCON



Morning Walk -- December 5, 1973, Los Angeles

Prabhupāda: Gbogbo eniyan lo je ebi ti Olorun, sugbon a ni lati ri nkan ti oun' se fun Olorun. Gege bi gbogbo eniyan se je ara ipinle ilu. Kilode ti a fun enikan ni ipo giga ati oye nla?

Prabhupāda: Kilode? Nitori o j'eni mimo.

Sudaamaa: Bee lori.

Prabhupāda: Bee ni a gbodo fi ise se. Lati lero nikan , "Mo je ibakan Olorun," ti a ko si nse nkankan fun Olorun, iyen ki se...

Sudaamaa: Iyen o bo ju mu.

Prabhupāda: Iyen o dara. Iyen tumo si wipe o maa... Lai pe o ma tun gbagbe Olorun. O ma tun gbagbe.

Sudaamaa: Nitooto, ano kan yen l'agbara pupo. Awon eniyan ibi yi, nitori, bi o ti le je wipe won fi ara j'ebi Olorun, sugbon nitoripe won ti gbagbe, nigba na igbagbe won na si nipa lori wa.

Prabhupāda: Bee ni. Igbagbe tumo si maayaa.

Sudaamaa: Bee ni.

Prabhupāda: Maayaa ko nse nkan miran. Igbagbe ni. Ko ju yen lo. Ko ni igbesi aye. Igbagbe, ko ni iduro. Sugbon fun igba ti o ba wa nibe, o je oniyonu pupo.

Sudaamaa: Awon olujosin kan ti bi mi leere ibeere kan wipe inu won o dun. Bee na ti o ba tile je wipe inu won ko dun, se o ye ki won si tun ma se ojuto won ninu isokan Olorun. Mo wi fun won, paapa bi eeyan ko tile ni idunnu...

Prabhupāda: Sugbon o ye ki e se apeere. Ti e ba fi apeere to yato han won, bawo ni won se ma tele yin? Apeere san ju iwasu lo. Kilode ti o ngbe n'ita.

Sudaamaa: Bee ni, mo...

Prabhupāda: (idake) ... lojo kan oni mo ni ilera to le pupo, mo ni lati kuro nbi. Iyen o tumo si wipe mo ma fi egbe yi sile Mo lo si India lati se itoju ara mi. Tabi ti wa si London. Iyen je bo seri. Bee ni ilera le ri bayi nigba miran...Sugbon ki se wipe a ma fi Egbe na sile. Ti ilera mi o ba ba ibi mu, ma lo... mo ni ogorun ile ijosin. O si ni kuro ninu agbaye yi lati lo se atunse ilera re. O ni lati duro sinu agbaye yi. Kilode nigba na ti o fi kuro ninu Egbe? (idake) ... Śrī Narottama dāsa Ṭhākura. A gbodo gbe pelu awon olujosin. Kilode ti mo se fi ebi mi sile? Nitoripe won ki nse olufokansin. Nitorina mo wa... Bibeko, ni arugbo ara, mi o ba ti ni itura. Rara o. Ko ye ki a gbe pelu awon alainigbagbo, boya awon olori idile tabi enikeni. Gege bi Maharaja Vibhisana. Nitoripe egbon re ki se olufokansin, o ya sile, o si fi sile. O wa si odo Ramachandra. Vibhisana. Iyen se mimo fun o.

Sudaamaa: Bee ni.

Hṛdayānanda: Bee na Prabhupāda, won so wipe sanyaasi gbodo da gbe, iyen tumo si pelu awon olujosin nikan.

Prabhupāda: Tani...! Nibo ni won ti so wipe sanyaasi gbodo da gbe?

Hṛdayānanda: Mo fe so wipe, ni gba miran ninu awon iwe yin.

Prabhupāda: Eh?

Hṛdayānanda: Nigba miran ninu iwe yin. Sibe na iyen tumo si pe pelu awon olujosin?

Prabhupāda: Ni apapo, sanyaasi le da gbe. Sugbo oju ise sanyaasi ni lati se iwasu.

Sudāmā: Emi o tile fi igba kan fe da duro.

Prabhupāda: Eh?

Sudāmā: Mi o figbakan ro wipe nma da iwasu duro lai lai.

Prabhupāda: Iwaasu, iwo o le da iwasu ti re se O gbodo se iwasu gegebi awon ofin ati ilana ti oluko igbala ti fi sile. E o le da ona iwasu ti yin sile. Iyen di dandan. Asaju kan gbodo wa. Ni abee akoso asaju na. Yasya prasādād bhagavat... Kini yen wi? Ni ibi gbogbo, ninu ibugbe ise, nibe a ma ni oga lesekese.. Bee ni e gbodo se ife re. Iyen ni ise. Ka ni ninu offisi, ni sakaani kan alabojuto a wa. Ti o ba si se ni ona ara re, "Bee ni mo nse ise owo mi," ti alabojuto offisi na ko si ni itelorun, e ro wipe iru ise yen dara? Bakanna, ni a se ni, ni bi gbogbo ni a ti ni oga lesekese. Bee na ni a gbodo se se. Iyen je ohun eto leto. Ti olukaluku ba da ti e sile, da ona isewawu ti re sile, idaru lo ma da sile nigba na.

Sudāmā: Koda, ododo oro ni yen.

Prabhupāda: Bee ni. Nisinyi a ni eto to kari aye. O wa ni ipo ti emi beni o si ni ipo ti aye yi na. Iyen ki se ipo ti aye. Iyen na je ipo ti emi, o tumo si isakoso leto leto. Bibeko, bawo ni o se ma sese? Gege bi Gaurasundara to ta ile na, ti a o si ri ibi ti owo gba lo. Kile eleyi? Ko bi leere mo, enikeni. O ta ile na, owo na wa da, ko se ri mo.