YO/Prabhupada 0172 - Lati teriba fun Krishna ni esin to daju



Lecture on SB 1.5.30 -- Vrndavana, August 11, 1974

Itumo esin ni yena, ati teriba fun Krsna. bibeko, wanti salaye ninu Srimad-Bhagavatam, dharmah projjhita-kaitavo 'tra (SB 1.1.2). Gbogbo awon esin ton tan awon eyan je, wan gbudo tiwan jade latinu Bhagavad, Srimad-Bhagavatam. Tiwan jade, projjhita. Lati wanu Olorun, lati d'Olorun, lati di èdá to t'Olorun wa - Iru awon esin bayi gbudo jade kuru ninu Srimad-Bhagavatam. Nitoripe esin gidi kon lonje. Lati teriba fun Krsna ni esin to daju.

Nitorina wan ti salaaye, yat tat saksad bhagavata uditam. teba fe sunmo Olorun eda to gaju, egbudo tele awon ofin Olorun. Sugbon awon eyan wanyi o mo nkankan nipa eni t'Olorun je, tabi nkan ti ofin re je, tabi iru ibasepo wo lani pelu re... Awon nkan yi o le yewan. Awon elesin nikan lon mo. Kilode toje pe awon elesin nikan lomo? Idahun si siwa ninu Bhagavad-gita: bhaktya mam abhijanati yavan yas casmi tattvatah (BG 18.55). teba fe mo eni t'Olorun je, eni ti Krsna je, egbudo gb'ona bhakti-marga, tabi ise ifarasi Olorun... Ko s'ona imi. Kosibi kankan ti Krsna sowipe ele mo nipa re lati ori riro tabi imoye tio daju. Rara. Lehin na kobati sowipe " Afi teba ni jnana lema ni oye nipa mi." Rara. Ona karma ati yoga gan o le fun yi ni oye nipa re. Wanti salaaye ninu sastra. Bhakti nikan, Bhakti nikan. Ise oluko mimo, tabi mahatma wa ni lati pin oro egbe yi fun gbogbo eyan. Ise apifunni to daju leleyi.

Nitoripe awon eyan jiya fun iru imoye yi. Nitorina egbe imoye Krsna wa yi ni egbe kan soso - Mole kede wipe egbe wa nikan lole fun agbaye eda ni awon anfaani to da. Egbe wa nikan. Gbogbo awon egbe iyoku o daju, moti jerisi. Ejeki gbogbo wan wa ko nipa sastra kon ri fun ara wan. Wan tan awon eyan je. bhagavad-bhakti yi nikan lo daju. Nitoripe kosi besele ni oye nipa Bhagavan lai monipa ilana ise ifarasi Oluwa. Bhaktya mam abhijanati yavan yas casmi tattvatah (BG 18.55). Krsna si fe ka mo nipa ra dada ni otito, tattvatah. Konsepe ka dede wa ka bere sini gbo nipa eto re pelu awon gopi nitoripe " O feran awon gopi gan." Kilode tefe gbo nipa awon irohin idaraya ti Krsna pelu awon gopi? Kilode teyin o fe gbo nipa iroyin bose fiku pa awon esu? Awon eyan o si fe gbo nipa eto bose fiku pa awon esu. sugbon nitoripe iroyin idaraya laarin Krsna ati awon gopi ko iroyin idaraya laarin okurin at'Obirin, osi dun lati gbo. Sugbon orisirisi ise ti Krsna se wa n'be. Paritranaya sadhunam vinasaya ca duskrtam (BG 4.8). Iroyin idaraya Krsna niyen. Eto Krsna niyen. Gege bi Oluwa Ramacandra se fi ku pa Ravana. Iroyin Idarya ti Krsna na niyen. Iroyin idaraya ti Ramacandra ati ti Krsna

Agbudo gba ni mimo eyikeyi ninu awon iroyin nipa Krsna. Kon se awon iroyin ti Vrndavan nikan , tabi ti awon gopi nikan Awa o gbudo feti gbo awon iroyin igboya wanyi afi t'awa ba ni ominiran. Eto to le gan ati mo loje. Nitoripe awon eyan yi o mo nipa iroyin idaraya ti Krsna ati wipe wan fe farawe Krsna, nitorina lonse wo lule.. Orisirisi nkan lowa sugbon awa o fe soro nipa wan. Sugbon tawa bafe ni ilosiwaju ninu eto krsna-lila, agbudo mo nipa eni ti Krsna jem nkan to fe, ati basele huwa. lehin na lale wole sinu apa igboya awon iroyin idaraya ti Krsna. Bibeko koni yewa, nigbato baya, ama wo lule.