YO/Prabhupada 0173 - Afe d'ore gbogbo awon eyan



Lecture on SB 1.7.6 -- Vrndavana, April 23, 1975

Agbudo gba imoye wa lati Bhagavad-gita tabi Srimad-Bhāgavatam nipa Kṛṣṇa. Kṛṣṇe parama-pūruṣe bhaktir utpadyate. teba gbo Śrīmad-Bhāgavatam... sugbon teyin o ba ni imoye nipa ofin Krsna tabi ofin nipa aye to pe.. Wansi ti salaaye ni ibere iwe Śrīmad-Bhāgavatam. Dharmaḥ projjhita-kaitavaḥ atra paramo nirmatsarāṇām (SB 1.1.2). Ninu iwe Śrīmad-Bhāgavatam wanti ti gbogbo awon oniranu wanyi si'ta. Fun awon paramahamsa nikan lowa. Nirmatsarāṇām. Eni ti o ni ilara kankan nitumo Nirmatsara. Ilara tani lati eto Krsna nloti bere. Awa o fe gba Krsna s'okan. Awon man saba sowipe, " Kilode toje pe Krsna nikan leyin pe ni eda to gaju? Opolopo ni awon to wa." Ilara niyen. Ilara yi de ti bere lati eto Krsna, nitorina oti dagba si ona to po. ninu aye wa gan, asi ni ilara to po. awa ni ilara si awon ore wa, si baba wa, si omo-okurin wa, kama wa so ti awon eyan imi - awon oniṣowo, Orile-ede, awujo, ilu, afi ilara nikan lo kun fun. Matsaratā. "Kilode to jepe eni yi ni ilosiwaju jumi lo?" Mo bere lati ni ilara si. Ile aye yi niyen.

Sugbon teyan ba ni oye nipa Krsna, a ni imoye Krsna, koni ni ilara l'okan. A d'ore siwa. Suhṛdaḥ sarva-bhūtānām. Itumo egbe imoye Krsna yi niwipe afe d'ore gbogbo eyan. Nitoripe wan jiya laini imoye Krsna, awa sin lo lati ile kan sikeji, ilu kan sikeji, abule kan sikeji, tan se waasu nipa imoye Krsna. Pelu ore-ofe Krsna awa ti famora awon okurin to l'ogbon gan. Gege na taba tesiwaju bayi, lai ni ilara seni kankan.. Iwa awon eranko niyen, iwa aja, iwa elede. para-duḥkha-duḥkhī n'iwa eda eyan. Agbudo ni ibanue taba ri awon eda ton jiya. Gbogbo eyan lon jiya nitoripe wan ni lati mo nipa imoye Krsna yi. Ise soso tawani ni lati jeki imoye Krsna l'okan re ji, lehin na inu gbogbo agbaye yi ma dunsi. Anartha upaśamaṁ sākṣād bhakti-yogam adhokṣaje, lokasya ajānataḥ. Awon eyan o ni imoye nipa eto yi. Gege na agbudo ti egbe yi siwa ju. Lokasyājān..., vidvāṁś cakre sātvata-saṁhitām (SB 1.7.6). Śrīmad-Bhāgavatam. Bhāgavata-dharma ni oruko imi fun egbe imoye Krsna yi Bhāgavata-dharma. Taba le gba s'okan, gbogbo awujo eda ma ni idunnu.

Ese pupo.