YO/Prabhupada 0458 - Chanting Hare Krishna - Touching Krishna With Your Tongue



Lecture on SB 7.9.6 -- Mayapur, February 26, 1977

Prabhupāda: Beena bi Nṛsiṁha-deva se fowokan ori Prahlāda Mahārāja, lesekese eyin na le ni irun nkan bayi. " Kini nkan na? Bawo? Nrsimha-deva o sin bi, Krsna o sinbi." Rara. O wa nibi. " Kini yen je?" Nama rūpe kali kale kṛṣṇa avatāra (CC Adi 17.22). Krsna wa nibi ninu oruko re, Krsna. Ema rowipe Krsna leleyi, Hare Krsna, oruko yi, oyato si Krsna. Krsna to gaju, irisi Krsna, oruko Krsna, ati Krsna fun ara re - gbogbo e, otito kanna lonje. Kosi iyato kankan. beena ninu asiko tawayi pelu ori kiko : kīrtanād eva kṛṣṇasya mukta-saṅgaḥ paraṁ vrajet (SB 12.3.51). Pelu orin kiko oruko mimo Krsna... Nama-cintāmaṇi kṛṣṇaḥ caitanya-rasa-vigrahaḥ, pūrṇaḥ śuddho nitya-muktaḥ (CC Madhya 17.133). Ema rowipe oruko mimo Krsna yato si Krsna. pūrṇam loje. Pūrṇaḥ pūrṇam adaḥ pūrṇam idam (Īśopaniṣad, Invocation). purna ni gbogbo e je. pipe nitumo Purna. Ati gbiyanju lati salaaye nipa eto yi ninu Isopanisad wa. Eyin ti ka. Beena e mu oruko mimo Krsna yi nipataki. Eyin na ma ni ijeere kana pelu Prahlada Maharaja lati ifowokan toni pelu owo idodo ti Nrsimha-deva. Kosi yato kankan. E ronu bayi nigbogbo'gba pe lesekese teyin ban korin Hare Krsna, egbodo mo wipe eyin fi ahon fi kan Krsna. Lehin na ema ni ijeere kanna pelu Prahlada Maharaja. Ese pupo.

Ajo: Jaya!