YO/Prabhupada 0585 - A Vaiṣṇava is Unhappy by seeing Others Unhappy



Lecture on BG 2.20 -- Hyderabad, November 25, 1972

Beena kosejo pe eyin rowipe koseni kankan lori isobe oorun. Awon eda tole gbe nibe si wa. Awa ti ko lati Brahma-saṁhitā pe koṭiṣu vasudhādi-vibhūti-bhinnam. Vasudhā. Isogbe nitumo Vasudhā. Aimoye isogbe towa ninu agbaye yi. Yasya prabhā prabhavato jagad-aṇḍa-koṭi-koṭiṣv aśeṣa-vasudhādi-vibhūti-bhinnam (Bs. 5.40). Isogbe kan lowa. Awon agbaye to wa po gan. Nigbati ikan ninu awon olufokan Caitanya Mahāprabhu bere lowo re, pe " Oluwa mi, eti wa nisin. E dakun E mu gbogbo awon eda yi pada. teyin basi rowipe ese won ti pojuu, pe kosi besele funwon nigbala, efi gbogbo ese won sori mi. Mofe jiya funwon. Emu won lo." Imiye Vaisnava leleyi. para-duḥkha-duḥkhī nitumo imoye Vaisnava leleyi. Looto, inu Vaisnava o le dun lati ri awon eyan ton jiya. Looto, koni ibanuje kankan. Nitoripe osi ni ipaarapo pelu Krsna, bawo lose leni ibanuje? fun ara re, koni ibanuje kankan. Sugbon ibanuje asi wa lokan re to ban ri awon eda ton jiya. Para-duḥkha-duḥkhī. Nitorina, Vāsudeva Ghoṣa, se bere lowo Oluwa Caitanya Mahāprabhu pe " E fun awon eda toni ibanuje wanyi nigbala. Teyin ba si rowipe elese niwon, pe kosi besele fun won nigbala, lehin na e mugbogbo ese won ke funmi. Mofe jiya fun won, kebale mu won lo." Beena inu Caitanya Mahaprabhu si dun gan si oro to so, osi rerin si. O sowipe " brahmanda yi, agbaye yi, dabi irugbin mustard ninu apo toni irugbn to po." Eto wa niwipe awon agbaye to wa po gan. E fi we ara won. E mu apo irugbin kan, kesi mu irugbin kan soso. Teba fi we rawon, kini iwulo irugbin an yi? Beena bi agbaye yi se ri niyen. Awon agabye to wa po gan. Awon oni sayensi aye isin, fe losi awon isogbe imi. Tonba tie losibe kini ijeere ton ni? koṭiṣu vasudhādi-vibhūti-bhinnam ni won. Kosi beyan sefe losi awon isogbe to po. Pelu isiro ton ni gan, tonba felosi isogbe to gaju Brahmaloka, Asi to bi odun oke-meji lati debe.

Beena ninu iseda Olorun gbogbo nkan ni lopin. Imoye ori wa o le ka. Beena aimoye isogbe, aimoye agbaye ati aimoye eda to wa. gbogbo won lon yika nitori karma won. iyika ninu ibimo ati iku nitumo ipaaro ara eda. Mo s'eto kan ninu aye yi... Nitoripe gbogbo eyan wa ninu ipo ara eda yi. Botilejepe awa wa ninu ipo aye yi... "brāhmaṇa nimi," "kṣatriya nimi," "vaiśya nimi," "śūdra nimi," "Olugbe India nimi," " Olugbe America nimi," " Nkan bayi bayi nimi." Awa ipo ara eda ni gbogbo eleyi je. Beena mosin rowipe ara eda yi nimi, " Mosi ni ise yi lati se. Bi brahmana, moni ise bayi bayi." "Bi olugbe America moni ise bayi bayi." " Beena fun igba ti imoye yi ma tesiwaju, agbodo gba ara eda imi. Ilana iseda leleyi.